Àwọn Àpéjọpọ̀ Àgbáyé ní 1998
Ẹgbẹ́ Olùṣàkóso ń wéwèé láti ṣe àwọn àpéjọpọ̀ àgbáyé ní 1998. Pa pọ̀ pẹ̀lú àwọn àpéjọpọ̀ àgbègbè tí a ti máa ń ṣe tẹ́lẹ̀, a óò ṣe àwọn àpéjọpọ̀ àgbáyé mélòó kan ní Àríwá America títí kan Áfíríkà, Éṣíà, Europe, Latin America, àwọn àgbègbè Caribbean, àti Gúúsù Pàsífíìkì.
A óò ṣe ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ lára àwọn àpéjọpọ̀ àkànṣe wọ̀nyí ní Àríwá America, a óò sì ké sí àwọn àyànṣaṣojú káàkiri ayé. Pẹ̀lúpẹ̀lù, a lè fojú sọ́nà fún níní àwọn míṣọ́nnárì ní àwọn àpéjọpọ̀ àgbáyé wọ̀nyí. A óò ké sí àwọn míṣọ́nnárì àti àwọn mìíràn tí wọ́n wà nínú iṣẹ́ ìsìn àkànṣe, láti lọ sí ọ̀kan nínú àwọn àpéjọpọ̀ wọ̀nyí ní orílẹ̀-èdè wọn tàbí nítòsí rẹ̀.
Àwọn àfikún ìsọfúnni nípa déètì, ibi tí a óò ti ṣe wọ́n, ẹ̀rí ìtóótun àwọn àyànṣaṣojú, ìṣètò fún àwọn àyànṣaṣojú láti ilẹ̀ òkèèrè, àti àwọn kúlẹ̀kúlẹ̀ míràn ń bọ̀ lọ́nà. Ẹ̀ka ọ́fíìsì yóò sọ fún àwọn ìjọ nípa ìlú àpéjọpọ̀ àgbáyé tí a óò ké sí àwọn akéde láti lọ. A óò pèsè ìsọfúnni nípa àwọn déètì àti ètò tí a ń ṣe fún àwọn àyànṣaṣojú tí a yàn.