Àpótí Ìbéèrè
◼ Àwọn ìṣọ́ra wo ni a nílò nígbà tí a bá wà pẹ̀lú ẹnì kan tí ó jẹ́ ẹ̀yà òdì kejì nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa?
A ní ìdí láti fojú sọ́nà pé àwọn arákùnrin àti arábìnrin wa ní in lọ́kàn láti rọ̀ mọ́ ọ̀pá ìdiwọ̀n ìwà híhù gíga jù lọ nínú ìwà wọn. Síbẹ̀síbẹ̀, a ń gbé nínú ayé aláìmọ́ àti onígbọ̀jẹ̀gẹ́, tí kò fi bẹ́ẹ̀ ní àwọn ààlà ìwà híhù. Nígbà tí ó jẹ́ pé a lè ní àwọn ohun tí ó dára jù lọ lọ́kàn, a gbọ́dọ̀ wà lójúfò nígbà gbogbo láti yẹra fún fífa ẹ̀gàn tàbí lílọ́wọ́ nínú ohun tí kò bójú mu. Èyí kan ṣíṣọ́ra nígbà tí a bá ń lọ́wọ́ nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́.
Nínú iṣẹ́ ìsìn pápá, a sábà máa ń bá àwọn ènìyàn tí wọ́n jẹ́ ẹ̀yà òdì kejì pàdé, tí wọ́n ń fi ohun tí ó dà bí ọkàn ìfẹ́ olótìítọ́ inú hàn nínú òtítọ́. Bí ó bá jẹ́ pé àwa nìkan ni a dá lọ ṣe ìkésíni, tí kò sì sí ẹnikẹ́ni mìíràn nílé, yóò dára jù nígbà gbogbo pé kí a jẹ́rìí fún un ní ẹnu ọ̀nà dípò wíwọ inú ilé. Bí ó bá fi ọkàn ìfẹ́ hàn, a lè ṣètò láti pa dà lọ nígbà tí akéde mìíràn yóò wà pẹ̀lú wa, tàbí nígbà tí àwọn ẹlòmíràn nínú agbo ilé náà yóò wà nílé pẹ̀lú. Bí èyí kò bá ṣeé ṣe, yóò bọ́gbọ́n mu pé kí a fa ṣíṣe ìkésíni náà le akéde kan tí ó jẹ́ ẹ̀yà kan náà bíi ti onílé lọ́wọ́. Èyí kan dídarí ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì pẹ̀lú ẹnì kan tí ó jẹ́ ẹ̀yà òdì kejì pẹ̀lú.—Mát. 10:16.
A ní láti ṣọ́ra nígbà tí a bá ń yan ẹni tí a óò bá ṣiṣẹ́ nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn akéde tí wọ́n jẹ́ ẹ̀yà òdì kejì lè ṣiṣẹ́ pa pọ̀ lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan, ó dára jù láti ṣe èyí nígbà tí wọ́n bá wà pẹ̀lú àwùjọ kan. Gẹ́gẹ́ bí ó ti máa ń rí, àní nígbà tí a bá wà nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ pàápàá, kò bọ́gbọ́n mu fún wa láti máa dá lo àkókò pa pọ̀ pẹ̀lú ẹnì kan tí ó jẹ́ ẹ̀yà òdì kejì, tí kì í ṣe alábàáṣègbéyàwó wa. Nítorí náà, arákùnrin tí ń bójú tó àwùjọ iṣẹ́ ìsìn gbọ́dọ̀ lo òye nígbà tí ó bá ń yan àwọn akéde, títí kan àwọn ọ̀dọ́langba, láti ṣiṣẹ́ pa pọ̀.
Nípa lílo òye nígbà gbogbo, a óò yẹra fún ‘jíjẹ́ okùnfà èyíkéyìí fún ìkọ̀sẹ̀’ yálà fún àwa fúnra wa tàbí fún àwọn ẹlòmíràn.—2 Kọ́r. 6:3.