Àwọn Ìfilọ̀
◼ Àwọn ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ tí a óò fi lọni ní June: Ìmọ̀ Tí Ń Sinni Lọ sí Ìyè Àìnípẹ̀kun fún ₦55. Pọkàn pọ̀ sórí bíbẹ̀rẹ̀ àwọn ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì inú ilé. July àti August: A lè lo èyíkéyìí nínú àwọn ìwé pẹlẹbẹ olójú ewé 32 tí ó tẹ̀ lé e yìí: Akoso Naa Ti Yoo Mu Paradise Wá, Gbádùn Iwalaaye lori Ilẹ Ayé Titilae!, Iwọ Ha Nilati Gbàgbọ́ Ninu Mẹtalọkan Bí?, Ki Ni Ète Igbesi-Aye? Bawo Ni Iwọ Ṣe Le Rí I?, Nígbà Tí Ẹnìkan Tí Ìwọ Fẹ́ràn Bá Kú, àti Ọlọrun Ha Bikita Nipa Wa Niti Gidi Bi? September: Àṣírí Ayọ̀ Ìdílé. ÀKÍYÈSÍ: Kí àwọn ìjọ tí yóò bá nílò àwọn ìwé ìgbétásì tí a mẹ́nu kàn lókè yí béèrè fún wọn lórí Literature Order Form (S-14) olóṣooṣù wọn ti oṣù tí ń bọ̀.
◼ Kí alábòójútó olùṣalága tàbí ẹnì kan tí òun yàn ṣàyẹ̀wò àkáǹtì ìjọ ní June 1 tàbí bí ó bá ti lè ṣeé ṣe kí ó yá tó lẹ́yìn náà. Ẹ ṣe ìfilọ̀ fún ìjọ lẹ́yìn tí ẹ bá ti ṣe èyí.
◼ Àwọn Ìtẹ̀jáde Tuntun Tí Ó Wà Lọ́wọ́:
Ayọ̀—Bi A Ṣe Lè Rí I—Ìgbò
Ihinrere Lati Mu Ọ Layọ—Ẹ́fíìkì
Isopọṣọkan ninu Ijọsin Ọlọrun Tootọ Kanṣoṣo Naa—Ísókó
Lilaaja Sinu Ilẹ-ayé Titun—Ẹ́fíìkì
Ọlọrun Ha Bikita Nipa Wa Niti Gidi Bi?—Èdè Àwọn Adití
Watch Tower Publications Index 1986-1995—Gẹ̀ẹ́sì
◼ Àwọn Kásẹ́ẹ̀tì Àtẹ́tísí Tuntun Tí Ó Wà Lọ́wọ́:
Singing Kingdom Songs (kásẹ́ẹ̀tì àtẹ́tísí ẹlẹ́yọ kan)—Gẹ̀ẹ́sì
◼ Àwọn Kásẹ́ẹ̀tì Fídíò Tuntun Tí Ó Wà Lọ́wọ́:
Ìmọ̀ Tí Ń Sinni Lọ sí Ìyè Àìnípẹ̀kun (Apá 1)—Èdè Àwọn Adití