Àwọn Ìfilọ̀
◼ Àwọn ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ tí a óò fi lọni ní September: Àṣírí Ayọ̀ Ìdílé fún ₦55. Ìfilọni àfidípò: Life—How Did It Get Here? By Evolution or by Creation? (ńlá, ₦170; kékeré, ₦85) tàbí Mankind’s Search for God fún ₦85. October: Àsansílẹ̀ owó fún yálà Jí! tàbí Ilé Ìṣọ́ tàbí fún ìwé ìròyìn méjèèjì. Bẹ̀rẹ̀ láti apá ìparí oṣù náà, a óò pín ìwé àṣàrò kúkúrú náà, Ìròyìn Ìjọba No. 35, káàkiri. November: Pípín ìwé àṣàrò kúkúrú náà, Ìròyìn Ìjọba No. 35, káàkiri yóò máa bá a nìṣó. Àwọn ìjọ tí ó bá ti kárí ìpínlẹ̀ wọn nípa mímú ìwé àṣàrò kúkúrú náà, Ìròyìn Ìjọba No. 35, dé ọ̀dọ̀ àwọn onílé ní ilé tàbí ibùgbé kọ̀ọ̀kan lè fi ìwé Ìmọ̀ lọni. December: Gẹ̀ẹ́sì—New World Translation pẹ̀lú ìwé náà, The Bible—God’s Word or Man’s? Ìfilọni àfidípò: Ọkunrin Titobilọla Julọ Ti O Tii Gbé Ayé Rí tàbí Iwe Itan Bibeli Mi. Yorùbá—Ìwé Mímọ́ Kristian Lédè Griki ní Ìtumọ̀ Ayé Titun. Ìfilọni àfidípò: Ọkunrin Titobilọla Julọ Ti O Tii Gbé Ayé Rí tàbí ìwé olójú ewé 192 èyíkéyìí. Àwọn èdè yòó kù—Ọkunrin Titobilọla Julọ Ti O Tii Gbé Ayé Rí tàbí Iwe Itan Bibeli Mi. Ìfilọni àfidípò: Ìwé olójú ewé 192 èyíkéyìí. ÀKÍYÈSÍ: Kí àwọn ìjọ tí yóò bá nílò àwọn ìwé ìgbétásì tí a mẹ́nu kàn lókè yí, yàtọ̀ sí ìwé àṣàrò kúkúrú náà, Ìròyìn Ìjọba No. 35, tí a óò kó ránṣẹ́ sí gbogbo ìjọ, béèrè fún wọn lórí Literature Order Form (S-14) olóṣooṣù wọn ti oṣù tí ń bọ̀.
◼ Kí alábòójútó olùṣalága tàbí ẹnì kan tí òun yàn ṣàyẹ̀wò àkáǹtì ìjọ ní September 1 tàbí bí ó bá ti lè ṣeé ṣe kí ó yá tó lẹ́yìn náà. Ẹ ṣe ìfilọ̀ fún ìjọ lẹ́yìn tí ẹ bá ti ṣe èyí.
◼ A ń rán àwọn alàgbà létí láti ṣiṣẹ́ lórí àwọn ìtọ́ni tí a pèsè nínú Ilé-Ìṣọ́nà ti April 15, 1991, ní ojú ìwé 21 sí 23, tí ó ní í ṣe pẹ̀lú àwọn tí a yọ lẹ́gbẹ́ tàbí tí wọ́n yọ ara wọn lẹ́gbẹ́, tí wọ́n bá nítẹ̀sí sí dídi ẹni tí a gbà pa dà.
◼ Kí àwọn tí ń dara pọ̀ mọ́ ìjọ fi gbogbo àsansílẹ̀ owó tuntun àti ìsọdituntun fún Ilé Ìṣọ́ àti Jí!, títí kan àsansílẹ̀ owó tiwọn fúnra wọn, ránṣẹ́ nípasẹ̀ ìjọ.
◼ Kì í ṣe Society ni ó ń kọ ìwé ìbéèrè fún ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ ti akéde kọ̀ọ̀kan. Kí alábòójútó olùṣalága ṣètò fún ìfilọ̀ lóṣooṣù kí a tó fi ìbéèrè fún ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ ti ìjọ lóṣooṣù ránṣẹ́ sí Society kí gbogbo ẹni tí ó bá fẹ́ láti gba ìwé ti ara rẹ̀ lè sọ fún arákùnrin tí ń bójú tó ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́. Ẹ jọ̀wọ́, ẹ fi àwọn ìtẹ̀jáde tí ó jẹ́ ìbéèrè àkànṣe sọ́kàn.
◼ Nígbà tí ẹ bá ń béèrè fún ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́, kí ìjọ fi sọ́kàn pé àkójọ ìsọfúnni náà, CD-ROM, ni a kò gbọ́dọ̀ máa pín yàlàyàlà. Ó wà fún lílò àwọn akéde ní pàtàkì.
◼ “Àpótí Ìbéèrè” Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa ti May 1997, dámọ̀ràn pé kí a ṣọ́ra nípa bíbá akéde tí ó jẹ́ ẹ̀yà òdì kejì ṣiṣẹ́ nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́. Àwọn ìdí rere wà fún gbogbo wa láti lo òye nínú ọ̀ràn yí. Èyí kò túmọ̀ sí pé àwọn alábòójútó arìnrìn-àjò tàbí àwọn arákùnrin mìíràn pàápàá kò lè bá àwọn arábìnrin ṣiṣẹ́ nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ pápá. Kàkà bẹ́ẹ̀, a sọ èrò náà pé kò bọ́gbọ́n mu fún arákùnrin kan láti máa dá lo àkókò pa pọ̀ déédéé pẹ̀lú ẹnì kan náà tí ó jẹ́ ẹ̀yà òdì kejì tí òun kò bá tan.
◼ Ní gbogbo àwùjọ, ní onírúurú àkókò nínú ọdún, àwọn họlidé ayé maá ń wà tí ó máa ń fún àwọn ọmọ ní àyè kúrò ní ilé ẹ̀kọ́, tí ó sì máa ń fúnni láyè kúrò lẹ́nu iṣẹ́ oúnjẹ òòjọ́. Ìwọ́nyí jẹ́ àǹfààní títayọ lọ́lá fún ìjọ láti ní ìpín tí ó pọ̀ sí i nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ pápá. Kí àwọn alàgbà fojú sọ́nà fún ìgbà tí àkókò wọ̀nyí yóò wáyé, kí wọ́n sì tètè fi àwọn ìṣètò tí wọ́n ti ṣe fún ìjẹ́rìí àjẹ́pọ̀ ní àwọn àkókò họlidé tó ìjọ létí ṣáájú.
◼ Àwọn Ìtẹ̀jáde Tuntun Tí Ó Wà Lọ́wọ́:
Ìdìpọ̀ Jí! ti 1996—Gẹ̀ẹ́sì
Ìdìpọ̀ Ilé Ìṣọ́ ti 1996—Gẹ̀ẹ́sì
Ayọ̀—Bi A Ṣe Lè Rí I—Ẹ́fíìkì
◼ Àwọn Compact Disk Tuntun Tí Ó Wà Lọ́wọ́:
Kingdom Melodies, Àkójọ 2 àti 3 (cdm-2; cdm-3)
Singing Kingdom Songs—Gẹ̀ẹ́sì