Àwọn Ìfilọ̀
◼ Àwọn ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ tí a óò fi lọni ní February: Àṣírí Ayọ̀ Ìdílé. March: Ìmọ̀ Tí Ń Sinni Lọ sí Ìyè Àìnípẹ̀kun. Pọkàn pọ̀ sórí bíbẹ̀rẹ̀ àwọn ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì inú ilé. April àti May: Gbogbo èdè—Àsansílẹ̀-owó fún Ilé Ìṣọ́ àti Jí!. ÀKÍYÈSÍ: Kí àwọn ìjọ tí yóò bá nílò àwọn ìwé ìgbétáásì tí a mẹ́nu kàn lókè yìí béèrè fún wọn lórí Literature Order Form (S-14) olóṣooṣù wọn ti oṣù tí ń bọ̀.
◼ Kí akọ̀wé àti alábòójútó iṣẹ́ ìsìn ṣàyẹ̀wò ìgbòkègbodò gbogbo aṣáájú ọ̀nà déédéé. Bí èyíkéyìí lára wọn bá ní ìṣòro dídójú ìlà wákàtí tí a béèrè fún, àwọn alàgbà ní láti ṣètò, kí a lè ṣe ìrànlọ́wọ́ fún un. Fún ìdámọ̀ràn, ṣàtúnyẹ̀wò àwọn lẹ́tà Society (S-201) ti October 1, 1993, àti October 1, 1992. Tún wo ìpínrọ̀ 12 sí 20 nínú àkìbọnú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa ti September 1986.
◼ Bẹ̀rẹ̀ ní ọ̀sẹ̀ May 4, 1998, títí dé June 15, 1998, ìwé pẹlẹbẹ Ki Ni Ète Igbesi-Aye? Bawo Ni Iwọ Ṣe Le Rí I? ni a óò máa kà ní Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ìwé Ìjọ. A fún un yín níṣìírí pé kí ẹ kọ̀wé béèrè fún ìtẹ̀jáde yìí nísinsìnyí kí ẹ lè lò ó ní Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ìwé Ìjọ.
◼ Kí àwùjọ àwọn akéde tí wọ́n ti ṣètò láti nípìn-ín nínú ṣíṣiṣẹ́ nínú ìpínlẹ̀ tí a kò pín fúnni ní àwọn oṣù tí ń bọ̀ wéwèé láti fi ìwé pẹlẹbẹ Béèrè tàbí ìwé Ìmọ̀ lọni nínú iṣẹ́ ìsìn pápá wọn.