Àwọn Ìfilọ̀
◼ Àwọn ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ tí a óò fi lọni ní June sí September: Ìfilọni àkànṣe ti àdìpọ̀ oríṣi ìwé méjì fún ₦40 àti àdìpọ̀ ìwé mẹ́rin fún ₦80, tí ẹ lè béèrè fún láti ẹ̀ka ilé iṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí a ti ṣàlàyé nínú lẹ́ta wa ti March 23, 1998. Bákan náà, a lè fi èyíkéyìí nínú àwọn ìwé olójú ewé 192 tí ìjọ lè ní lọ́wọ́, yàtọ̀ sí Àṣírí Ayọ̀ Ìdílé, Ìmọ̀ Tí Ń Sinni Lọ Sí Ìyè Àìnípẹ̀kun, Iṣetojọ Lati Ṣaṣepari Iṣẹ-ojiṣẹ Wa àti Iwe-Amọna Ile Ẹkọ Iṣẹ Ojiṣẹ Ijọba Ọlọrun lọni ní àkànṣe ọrẹ ₦20. Ẹ lè béèrè fún ẹ̀dínwó lórí àwọn ìwé wọ̀nyí gẹ́gẹ́ bí a ti ṣàlàyé nínú lẹ́tà wa.
◼ Kí alábòójútó olùṣalága tàbí ẹnì kan tí òun yàn ṣàyẹ̀wò àkáǹtì ìjọ ní June 1 tàbí bí ó bá ti lè ṣeé ṣe kí ó yá tó lẹ́yìn náà. Ẹ ṣe ìfilọ̀ fún ìjọ lẹ́yìn tí ẹ bá ti ṣe èyí.
◼ Nínú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa ti August 1991 nípa “Awọn Ayẹyẹ Igbeyawo Kristẹni, Apa 6b—Awiye Igbeyawo,” a sọ àwọn ọ̀rọ̀ tí ó tẹ̀ lé e yìí ní ìpínrọ̀ 2 pé: “Bi o ti wu ki o ri, kiki awọn tọkọtaya naa ni wọn gbọdọ duro niwaju ojiṣẹ naa ni akoko ti wọn ba nka ẹ̀jẹ́. (Ilé-ìṣọ́nà, October 15, 1984, oju-iwe 10)” Àpilẹ̀kọ tí ó wà nínú Ilé Ìṣọ́ yìí gbé àwòrán tọkọtaya kan tí ó jẹ́ pé àwọn nìkan ni ó dúró níwájú òjíṣẹ́ tí ń darí ayẹyẹ náà, ṣùgbọ́n a kò sọ ohunkóhun nínú àpilẹ̀kọ yẹn nípa bóyá àwọn nìkan ni ó gbọ́dọ̀ dìde dúró nígbà tí wọ́n bá ń jẹ́jẹ̀ẹ́. Àmọ́ ṣá o, ní ojú ìwé 2 nínú ìlapa èrò náà, “Igbeyawo Ti O Ní Ọlá Ní Oju Ọlọrun,” lábẹ́ “Yan Ipin Yii Bi O Ba Fẹ: Ilana-Iṣe Ayẹyẹ Igbeyawo Ṣaaju Awọn Ẹ̀jẹ́,” a sọ pé kí “iyawo, ọkọ iyawo, ati awọn ẹlẹ́rìí labẹ ofin dúró niwaju ojiṣẹ.” Bí o ti sábà máa ń rí, àwọn ẹlẹ́rìí lábẹ́ òfin máa ń jẹ́ amúgbálẹ́gbẹ̀ẹ́ ìyàwó àti amúgbálẹ́gbẹ̀ẹ́ ọkọ. Nítorí náà, ohun tí ó tọ́ ni pé kí àwọn méjèèjì wọ̀nyí pẹ̀lú dìde dúró níwájú òjíṣẹ́ náà nígbà tí wọ́n bá ń ka ẹ̀jẹ́. Kí àwọn tí ń sọ àsọyé ìgbéyàwó rántí láti mú ìsọfúnni yìí wá sí àfiyèsí tọkọtaya.