ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • km 11/98 ojú ìwé 7
  • Àwọn Ìfilọ̀

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Àwọn Ìfilọ̀
  • Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—1998
Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—1998
km 11/98 ojú ìwé 7

Àwọn Ìfilọ̀

◼ Àwọn ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ tí a óò fi lọni ní November: Ìmọ̀ Tí Ń Sinni Lọ sí Ìyè Àìnípẹ̀kun. December: Ìmọ̀ Tí Ń Sinni Lọ sí Ìyè Àìnípẹ̀kun àti Ìwé Mímọ́ ní Ìtumọ̀ Ayé Tuntun. January: Ìwé olójú ewé 192 èyíkéyìí tí a tẹ̀ jáde ṣáájú 1985 tí ìjọ ní lọ́wọ́. Àwọn ìjọ tí kò bá ní irú àwọn ìwé bẹ́ẹ̀ lè fi ìwé Ayọ̀—Bi A Ṣe Lè Rí I, Igba Ewe rẹ—Bi o ṣe le Gbadun rẹ Julọ, Igbesi Aye Yii Ha Ni Gbogbo Ohun Ti O Wà Bi?, Iwọ Le Walaaye Titilae ninu Paradise lori Ilẹ Aye lọni. February: Àṣírí Ayọ̀ Ìdílé. Ìfilọni àfidípò: Ìwé olójú ewé 192 èyíkéyìí tí ọjọ́ rẹ̀ ti pẹ́ tí a lè ní lọ́wọ́. ÀKÍYÈSÍ: Kí àwọn ìjọ tí yóò bá nílò àwọn ìwé ìgbétáásì tí a mẹ́nu kàn lókè yìí béèrè fún wọn lórí Literature Order Form (S-14) olóṣooṣù wọn ti oṣù tí ń bọ̀.

◼ Àǹfààní láti rìnrìn àjò lọ sí òkè òkun ti ṣí sílẹ̀ fún àwọn kan. Nítorí èyí, ọ̀pọ̀ àwọn ará ti ṣètò láti ṣèbẹ̀wò sí àwọn orílẹ̀-èdè mìíràn. Lóòrèkóòrè, wọ́n máa ń kàn sí ọ́fíìsì ẹ̀ka Society, tí wọ́n sì máa ń béèrè ìsọfúnni. Inú àwọn ọ́fíìsì ẹ̀ka máa ń dùn láti pèsè àwọn àdírẹ́sì Gbọ̀ngàn Ìjọba àti àwọn àkókò ìpàdé láti ṣèrànwọ́ ní kíkàn sí àwọn ìjọ àdúgbò. Pẹ̀lúpẹ̀lù, wọ́n lè pèsè ìtọ́sọ́nà ní ti ṣíṣèbẹ̀wò sí ọ́fíìsì ẹ̀ka. Ṣùgbọ́n, ìròyìn fi hàn pé ọ̀pọ̀ àfikún ìbéèrè ni àwọn ará máa ń béèrè nípa ètò ìrìnnà, ilé ibùwọ̀, àwọn ibi tí a lè ṣèbẹ̀wò sí, àti àwọn ọ̀ràn mìíràn tí ó jọ èyí. Àwọn ẹ̀ka ọ́fíìsì kò lágbára láti pèsè irú ìsọfúnni yìí, bẹ́ẹ̀ ni wọn kò ní àkókò fún un. A fún àwọn olùṣèbẹ̀wò níṣìírí láti kàn sí irú àwọn àjọ onísọfúnni bí àwọn ilé iṣẹ́ aṣojú arìnrìn-àjò, tàbí ilé iṣẹ́ tí ń bójú tó ìrìn àjò afẹ́ tí wọ́n máa ń pèsè ìsọfúnni fún àwọn arìnrìn-àjò afẹ́.

◼ Àwọn Ìtẹ̀jáde Tuntun Tí Ó Wà:

Àwọn Àkòrí Ọ̀rọ̀ Bíbélì fún Ìjíròrò —Haúsá, Ísókó, Tiv

◼ Àwọn Ìtẹ̀jáde Tí Ó Wà Nísinsìnyí:

Àwọn Àkòrí Ọ̀rọ̀ Bíbélì fún Ìjíròrò (Ìtẹ̀jáde ti 1998) —Ẹ́fíìkì, Ìgbò

ÀKÍYÈSÍ: Kí àwọn ìjọ tí yóò bá nílò àwọn ìwé tí a dárúkọ lókè yìí béèrè fún wọn lórí fọ́ọ̀mù Literature Order (S-14) olóṣooṣù wọn ti oṣù tí ń bọ̀. Ìtẹ̀jáde tuntun ìwé kékeré yìí ni Ẹ́fíìkì, Ìgbò, àti Ísókó yóò lò ní Ilé Ẹ̀kọ́ Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìṣàkóso Ọlọ́run ní ọdún 1999.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́