Àwọn Ìfilọ̀
◼ Àwọn ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ tí a óò fi lọni ní February: Àṣírí Ayọ̀ Ìdílé fún ₦55; (ẹlẹ́yìn rírọ̀, ₦50). Ìfilọni àfidípò: Ìwé olójú ewé 192 èyíkéyìí tí ọjọ́ rẹ̀ ti pẹ́ tí a bá ní lọ́wọ́. March: Ìmọ̀ Tí Ń Sinni Lọ sí Ìyè Àìnípẹ̀kun. Ìfilọni àfidípò: Ìwé olójú ewé 192 èyíkéyìí mìíràn, kí a fi lọni ní iye tí a máa ń fi sóde. A óò sapá lákànṣe láti bẹ̀rẹ̀ àwọn ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì inú ilé. April àti May: Gbogbo èdè—Àsansílẹ̀ owó fún Ilé Ìṣọ́ àti Jí! Mú kí ìwé pẹlẹbẹ Béèrè wà lárọ̀ọ́wọ́tó fún àwọn tí ó fi ọkàn-ìfẹ́ hàn, kí o sì sakun láti bẹ̀rẹ̀ àwọn ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì inú ilé.
◼ Bẹ̀rẹ̀ láti ọ̀sẹ̀ March 22, 1999, ìwé náà, Ọkunrin Titobilọla Julọ Ti O Tii Gbé Ayé Rí ni a óò máa kà ní Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ìwé Ìjọ. Ìtẹ̀jáde Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa yìí ní odindi ìtòlẹ́sẹẹsẹ fún ìkẹ́kọ̀ọ́ náà nínú. O lè ṣe ẹ̀dà rẹ̀ kí o sì fi sínú ẹ̀dà ìwé tìrẹ kí ó lè rọrùn láti tọ́ka sí i. Ìtọ́sọ́nà nípa bí a óò ṣe ṣàyẹ̀wò ìnasẹ̀ ìwé náà ni a ṣàlàyé ní ìpínrọ̀ 5 nínú àpilẹ̀kọ náà, “Kikẹkọọ Iwe Ọkunrin Titobilọla Julọ Ti O Tii Gbé Ayé Rí,” ní ojú ìwé 1 nínú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa ti December 1992.
◼ Kí akọ̀wé àti alábòójútó iṣẹ́ ìsìn ṣàyẹ̀wò ìgbòkègbodò gbogbo aṣáájú ọ̀nà déédéé. Bí èyíkéyìí lára wọn bá ní ìṣòro dídojú ìlà wákàtí tí a béèrè fún, kí àwọn alàgbà ṣètò kí a lè ran ẹni náà lọ́wọ́. Fún ìdámọ̀ràn, ṣàtúnyẹ̀wò àwọn lẹ́tà S-201 ọdọọdún láti ọ̀dọ̀ Society tí déètì rẹ̀ jẹ́ October 1. Tún wo ìpínrọ̀ 12 sí 20 nínú àkìbọnú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa ti September 1986.
◼ Nísinsìnyí, a ti ní ìtẹ̀jáde CD-ROM, Watchtower Library ti 1997 ní èdè Gẹ̀ẹ́sì. Iye owó rẹ̀ jẹ́ ₦860. Kí àwọn tí ó bá fẹ́ ní in béèrè fún un nípasẹ̀ ìjọ. Ẹ jọ̀wọ́, ẹ fi sọ́kàn pé àwọn akéde ni ó wà fún ní pàtàkì kì í ṣe fún àwọn ará ìta.
◼ Kí àwọn ìjọ ṣètò láti ṣayẹyẹ Ìṣe Ìrántí lọ́dún yìí ní Thursday, April 1, lẹ́yìn tí oòrùn bá wọ̀. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àsọyé náà lè bẹ̀rẹ̀ ṣáájú àkókò yìí, gbígbé àwọn ohun ìṣàpẹẹrẹ Ìṣe Ìrántí kiri kò gbọ́dọ̀ bẹ̀rẹ̀ àyàfi ìgbà tí oòrùn bá wọ̀. Ẹ wádìí ládùúgbò láti mọ ìgbà tí oòrùn máa ń wọ̀ lágbègbè yín. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ó dára gan-an pé kí ìjọ kọ̀ọ̀kan ṣayẹyẹ Ìṣe Ìrántí tirẹ̀, èyí lè má ṣeé ṣe ní gbogbo ìgbà. Níbi tí ó bá jẹ́ pé àwọn ìjọ mélòó kan jọ ń lo Gbọ̀ngàn Ìjọba kan náà, ó ṣeé ṣe kí ìjọ kan tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ gba ilé mìíràn láti lò ní àṣálẹ́ yẹn. Níbi tí ó bá ti ṣeé ṣe, a dábàá pé ó kéré tán, kí àlàfo ogójì ìṣẹ́jú wà láàárín àwọn ìtòlẹ́sẹẹsẹ náà kí àyè lè wà láti kí àwọn àlejò, kí a lè fún àwọn olùfìfẹ́hàn tuntun ní ìṣírí, kí a sì jàǹfààní lẹ́kùn-únrẹ́rẹ́ láti inú ayẹyẹ náà. Ó yẹ kí a tún ronú nípa ìṣòro ọkọ̀ àti ibi ìgbọ́kọ̀sí pẹ̀lú, tí ó kan pé kí èrò bọ́ sílẹ̀ nínú ọkọ̀ tàbí kí wọ́n wọkọ̀. Kí ẹgbẹ́ àwọn alàgbà pinnu ìṣètò tí yóò dára jù lọ ní àdúgbò wọn.