Ran Àwọn Ẹlòmíràn Lọ́wọ́ Kí Wọ́n Lè Jàǹfààní Láti Inú Ìwé Pẹlẹbẹ Kí Ní Ń Ṣẹlẹ̀ sí Wa Nígbà Tí A Bá Kú?
Lẹ́nu àìpẹ́ yìí, a ka ìwé pẹlẹbẹ Kí Ní Ń Ṣẹlẹ̀ sí Wa Nígbà Tí A Bá Kú? ní Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ìwé Ìjọ. A gbà gbọ́ pé gbogbo wa ti jàǹfààní láti inú rẹ̀.
Ìwé pẹlẹbẹ yìí ní ìsọfúnni tó lè ṣe àwọn tí a ń bá pàdé nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ láǹfààní. Ó ṣàwárí gbòǹgbò ẹ̀kọ́ àìleèkú ọkàn, ó sì ṣàyẹ̀wò bí èrò náà ṣe di nǹkan pàtàkì nínú gbogbo ẹ̀sìn ayé. Lọ́nà tí ń fani lọ́kàn mọ́ra, ó ṣàlàyé ohun tí Bíbélì sọ nípa ọkàn, ìdí tí a fi ń kú, ipò tí àwọn òkú wà, ìrètí tó wà fún ìwàláàyè lẹ́yìn ikú, àti ìdí tó fi yẹ ká mọ ohun tó jẹ́ òtítọ́ nípa àwọn ọ̀ràn wọ̀nyí.
Ó ní nǹkan bí ogójì àwòrán àti àwọn àyọlò ní ìbẹ̀rẹ̀ apá kọ̀ọ̀kan, tí a lè lò láti ru ìfẹ́ àwọn èèyàn sókè. Nígbà tí a bá ń fi ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì inú ilé lọni, a lè lo apá tó kẹ́yìn. Ọ̀pọ̀ ti ṣàṣeyọrí nínú lílo ìwé pẹlẹbẹ yìí nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́. A rọ gbogbo yín láti lò ó ní gbogbo ìgbà tí àǹfààní bá ṣí sílẹ̀.