Àwọn Ìfilọ̀
◼ Àwọn ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ tí a ó fi lọni ní oṣù July: Fífi àdìpọ̀ ìwé tí a béèrè fún lọ́dọ̀ Society lọni lọ́nà àkànṣe, gẹ́gẹ́ bí a ti ṣàlàyé nínú lẹ́tà wa ti March 1, 1999. Àdìpọ̀ ìwé mẹ́rin fún ₦60. August: A lè lo èyíkéyìí nínú àwọn ìwé pẹlẹbẹ olójú ìwé 32 tó tẹ̀ lé e yìí: Akoso Naa Ti Yoo Mu Paradise Wá, Gbádùn Iwalaaye lori Ilẹ Ayé Titilae!, Iwọ Ha Nilati Gbàgbọ́ Ninu Mẹtalọkan Bí?, Ki Ni Ète Igbesi-Aye? Bawo Ni Iwọ Ṣe Le Rí I?, Kí Ní Ń Ṣẹlẹ̀ sí Wa Nígbà Tí A Bá Kú?, Nígbà Tí Ẹnìkan Tí Ìwọ Fẹ́ràn Bá Kú, àti Ọlọrun Ha Bikita Nipa Wa Niti Gidi Bi? Àwọn ìwé pẹlẹbẹ Ẹmi Awọn Oku—Wọn Ha Le Ran Ọ Lọwọ Tabi Pa Ọ Lara Bi? Wọn Ha Wa Niti Gidi Bi?, Ìwé Kan Tí Ó Wà fún Gbogbo Ènìyàn, Our Problems—Who Will Help Us Solve Them?, àti Will There Ever Be a World Without War? ni a lè fi lọni nígbà tó bá yẹ. September: Ìmọ̀ Tí Ń Sinni Lọ sí Ìyè Àìnípẹ̀kun. October: Gbogbo èdè—Àsansílẹ̀ owó fún Ilé Ìṣọ́ àti Jí!
◼ Bẹ̀rẹ̀ láti September, àkòrí àsọyé fún gbogbo ènìyàn, èyí táwọn alábòójútó àyíká yóò máa sọ ni “Jèhófà ni ‘Ibi Gíga Ààbò’ Fáwọn Èèyàn Rẹ̀.”
◼ A fi ẹ̀dà méjì fọ́ọ̀mù náà, Report on Literacy ránṣẹ́ sí gbogbo ìjọ. Kí ẹ kọ ọ̀rọ̀ kún fọ́ọ̀mù yìí ní August 1, kí ẹ sì fi ránṣẹ́ sí wa ní August 6. Ẹ fi ẹ̀dà kan sínú fáìlì yín. Kí ẹ kọ ọ̀rọ̀ kún gbogbo àlàfo tó wà nínú fọ́ọ̀mù yìí, yálà ẹ ní ilé ẹ̀kọ́ mọ̀ọ́kọ-mọ̀ọ́kà tàbí ẹ kò ní.