Pípadà Bẹ Àwọn Tó Fìfẹ́ Hàn Wò Ṣe Pàtàkì Nínú Iṣẹ́ Sísọni Di Ọmọ Ẹ̀yìn
1 Nígbà tí Jésù ń fún àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ olùṣòtítọ́ ní ìtọ́ni tó kẹ́yìn, ó wí pé: “Ẹ lọ, kí ẹ sì máa sọ àwọn ènìyàn . . . di ọmọ ẹ̀yìn, . . . ẹ máa kọ́ wọn.” (Mát. 28:19, 20) Jésù fi ọ̀rọ̀ wọ̀nyí tẹ̀ ẹ́ mọ́ àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ lọ́kàn pé wọ́n gbọ́dọ̀ ṣe iṣẹ́ ìkọ́ni. Èyí mú kó di dandan pé wọ́n gbọ́dọ̀ padà bẹ àwọn èèyàn wò láti mú kí ìfẹ́ tí wọ́n ní sí òtítọ́ pọ̀ sí i.
2 Báwo La Ṣe Ń Ṣe É?: Ó ṣòro fún àwọn ará kan láti lọ́wọ́ nínú apá iṣẹ́ ìwàásù yìí. Nígbà mìíràn, ó máa ń jẹ́ nítorí pé wọn ò mọ ohun tó yẹ kí wọ́n sọ nígbà tí wọ́n bá ṣe ìpadàbẹ̀wò. Ṣùgbọ́n o, kò fi bẹ́ẹ̀ ṣòro. Lọ́pọ̀ ìgbà, ó dára jù láti bẹ̀rẹ̀ sí wéwèé nǹkan tí wàá sọ nígbà ìpadàbẹ̀wò ní gbàrà tóo bá ti parí ìbẹ̀wò rẹ àkọ́kọ́. Kọ àwọn kókó tó fa onílé mọ́ra sílẹ̀. Èyí á jẹ́ kí o lè gbé ọ̀rọ̀ rẹ gba ibi tédè yín ti yéra. Pẹ̀lúpẹ̀lù, o lè béèrè ìbéèrè kan lọ́wọ́ onílé, ìyẹn lẹ máa dáhùn nígbà ìpadàbẹ̀wò. Padà lọ lọ́jọ́ kan náà tàbí níwọ̀n ọjọ́ mélòó kan bó bá ṣeé ṣe. Bí ọ̀pọ̀ ọ̀sẹ̀ bá kọjá, ìfẹ́ tónílé fi hàn lè dín kù, yóò sì ṣòro láti tún mú un sọ jí. Jẹ́ kí ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ rẹ rọrùn, kó ṣe kedere, kó sì ṣe tààràtà. Fi Bíbélì ti ohun tóo bá sọ lẹ́yìn. Yẹra fún àwọn kókó ọ̀rọ̀ tó máa ń fa ìjiyàn. Sọ̀rọ̀ dáadáa nípa àwọn ohun tó máa ń fani mọ́ra nínú ìhìn Ìjọba náà.
3 Ìwọ nìkan kọ́ ló yẹ kí ó máa sọ̀rọ̀ nígbà tóo bá ń gbọ́rọ̀ kalẹ̀. A sábà máa ń ṣàṣeyọrí nígbà táa bá jẹ́ kí onílé dá sí ọ̀rọ̀ náà. Lo àwọn ìbéèrè táa fi ń mọ èrò èèyàn kí o lè mọ ohun tó wà nínú rẹ̀. Èyí á jẹ́ kí o lè kọ́ ọ lẹ́kọ̀ọ́ lọ́nà tó nítumọ̀.
4 Ìrànwọ́ Tó Wà Lárọ̀ọ́wọ́tó: A pèsè àwọn àbá tó gbéṣẹ́ tí a lè ṣàyẹ̀wò nínú ìwé Iṣetojọ Lati Ṣaṣepari Iṣẹ-Ojiṣẹ Wa. Bí àpẹẹrẹ, kíyè sí àwọn ìtọ́sọ́nà àtàtà tó wà lójú ìwé 88 àti 89. Kíka ìpínrọ̀ mẹ́rin tó wà lábẹ́ àkòrí tó sọ pé “Ṣiṣe Awọn Ipadabẹwo” yẹ kó fún wa níṣìírí. O tún lè lo Àwọn Àkòrí Ọ̀rọ̀ Bíbélì fún Ìjíròrò tó wà nínú Ìwé Mímọ́ ní Ìtumọ̀ Ayé Tuntun.
5 Bí kókó kan bá jẹyọ nígbà ìbẹ̀wò àkọ́kọ́ ńkọ́ tí o sì fẹ́ túbọ̀ ṣèwádìí nípa rẹ̀? Ìwé mí-ìn tó tún lè ṣèrànwọ́ ni ìwé Reasoning From the Scriptures. Ọ̀pọ̀ kókó ẹ̀kọ́ pàtàkì wà nínú ẹ̀ téèyàn lè sọ̀rọ̀ nípa ẹ̀. A sọ nípa àwọn ọ̀nà tí a lè gbà lo ìwé yìí ní ojú ìwé 7 àti 8. A dá àwọn àbá nípa bí a ṣe lè lò ó. Ìpínrọ̀ 4 lójú ìwé 7 sọ pé: “Báwo lo ṣe lè rí àkójọ ọ̀rọ̀ tí o ń wá gan-an nínú ìwé yìí? Lọ́pọ̀ ìgbà, wàá tètè rí i nípa ṣíṣí i ní tààràtà sí àkòrí tó sọ nípa kókó ẹ̀kọ́ tí o ń jíròrò. Lábẹ́ gbogbo àkòrí, ó rọrùn láti rí àwọn ìbéèrè pàtàkì; lẹ́tà tó túbọ̀ hàn ketekete la fi kọ wọ́n, wọ́n sì pọwọ́ lé ìlà etí ìwé lápá òsì. Bí oò bá tètè rí èyí tí o ń wá, lọ wo Atọ́ka tó wà lẹ́yìn ìwé náà.”
6 Nítorí náà, ó dáa pé kí a máa lẹ́mìí pé nǹkan yóò ṣẹnuure nígbà tí a bá ń padà bẹ àwọn tó fìfẹ́ hàn nínú iṣẹ́ ìwàásù wa wò, kódà bí ìrírí wa ò bá tó nǹkan. Ohun tó ṣe pàtàkì ni pé a bìkítà nípa àwọn ẹlòmíràn. Lónìí, ètò Jèhófà ti pèsè ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ àti àwọn akéde tó nírìírí láti dá wa lẹ́kọ̀ọ́. Bí a bá rí àwọn èèyàn tí wọ́n jẹ́ olóòótọ́-ọkàn tí wọ́n “ń mí ìmí ẹ̀dùn, tí wọ́n sì ń kérora” nítorí àwọn ohun ìṣe-họ́ọ̀-sí tí wọ́n ń rí, ó yẹ kí ìfẹ́ táa ní sún wa láti padà lọ ká sì ràn wọ́n lọ́wọ́.—Ìsík. 9:4-6.