Àwọn Ìfilọ̀
◼ Ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ tí a ó fi lọni ní oṣù April àti May: Àwọn ẹ̀dà Ilé Ìṣọ́ àti Jí! Ní ìwé pẹlẹbẹ Béèrè lọ́wọ́ nítorí àwọn èèyàn tó bá fìfẹ́ hàn, kí o sì sapá láti bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì pẹ̀lú àwọn èèyàn nínú ilé wọn. June: Kí Ni Ọlọ́run Ń Béèrè Lọ́wọ́ Wa? Pọkàn pọ̀ sórí bíbẹ̀rẹ̀ àwọn ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì pẹ̀lú àwọn èèyàn nínú ilé wọn. July àti August: A lè lo èyíkéyìí nínú àwọn ìwé pẹlẹbẹ olójú ewé méjìlélọ́gbọ̀n tó tẹ̀ lé e yìí: Akoso Naa Ti Yoo Mu Paradise Wá, Gbádùn Iwalaaye lori Ilẹ Ayé Titilae!, Iwọ Ha Nilati Gbàgbọ́ Ninu Mẹtalọkan Bí?, Ki Ni Ète Igbesi-Aye—Báwo Ni Iwọ Ṣe Le Rí I?, Kí Ní Ń Ṣẹlẹ̀ sí Wa Nígbà tí A Bá Kú?, Nígbà Tí Ẹnìkan Tí Ìwọ Fẹ́ràn Bá Kú, Orukọ Atọrunwa naa Tí Yoo Wà Titilae, àti Ọlọrun Ha Bikita Nipa Wa Niti Gidi Bi? Àwọn ìwé pẹlẹbẹ Ẹmi Awọn Oku—Wọn Ha Le Ran Ọ Lọwọ Tabi Pa Ọ Lara Bi? Wọn Ha Wa Niti Gidi Bi? àti Ìwé Kan Tí Ó Wà fún Gbogbo Ènìyàn ni a lè fi lọni nígbà tó bá yẹ.
◼ Àwọn Ìtẹ̀jáde Tuntun Tó Wà:
Gbádùn Iwalaaye lori Ilẹ Ayé Titilae! —lédè Ẹdó, Gokana, Ishan, Khana, Ùróbò
Kíyè sí Àsọtẹ́lẹ̀ Dáníẹ́lì! —lédè Ẹ́fíìkì, Gẹ̀ẹ́sì, Ìgbò, Ísókó, Yorùbá
Awọn Ìbéèrè Tí Awọn Ọ̀dọ́ Ń Béèrè—Awọn Ìdáhùn Tí Ó Gbéṣẹ́ —lédè Ìgbò
Ọkunrin Titobilọla Julọ Ti O Tii Gbé Ayé Rí —lédè Ísókó