“Àwa Kò Lè Dẹ́kun Sísọ̀rọ̀”
1 Jésù Kristi ń bójú tó iṣẹ́ ìwàásù náà ní kínníkínní. (Mát. 28:20; Máàkù 13:10) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó mílíọ̀nù mẹ́fà àwọn olùpòkìkí aláápọn tí wọ́n ń jẹ́rìí ní ilẹ̀ igba ó lé mẹ́rìnlélọ́gbọ̀n, a ò gbọ́dọ̀ ronú pé iṣẹ́ ìjẹ́rìí wa ti parí. Títí di ìgbà tí Ọlọ́run yóò fi kéde pé iṣẹ́ náà ti parí, “àwa kò lè dẹ́kun sísọ̀rọ̀” nípa àwọn ohun tí a ti kọ́.—Ìṣe 4:20.
2 Gbára Lé Ẹ̀mí Ọlọ́run: Sátánì máa ń sapá gidigidi láti mú ká rẹ̀wẹ̀sì. (Ìṣí. 12:17) Ẹran ara aláìpé wa tún ń kó ọ̀pọ̀ ìṣòro bá wa. Irú àwọn nǹkan báyẹn lè yí àfiyèsí wa kúrò nínú iṣẹ́ ìwàásù tó ṣe pàtàkì jù lọ yìí. Ṣùgbọ́n, bí a bá gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà, ẹ̀mí rẹ̀ yóò ràn wá lọ́wọ́ láti kojú ohun ìdènà èyíkéyìí.
3 Nígbà tí wọ́n ṣenúnibíni lílekoko sí ìjọ Kristẹni ọ̀rúndún kìíní, àwọn ará gbàdúrà sí Ọlọ́run pé kí ó ran àwọn lọ́wọ́ láti lè máa fi àìṣojo gbogbo sọ ọ̀rọ̀ rẹ̀. Jèhófà dáhùn àdúrà wọn, ó fún wọn ní ẹ̀mí rẹ̀, ó sì fún wọn ní ìtara àti ìmúratán tí wọ́n nílò láti máa wàásù nìṣó. Nítorí èyí, wọ́n ń bá a nìṣó láìdábọ̀ ní fífi àìṣojo polongo ìhìn rere náà.—Ìṣe 4:29, 31; 5:42.
4 Má Ṣe Bẹ̀rù Ọ̀rọ̀ Amúnirẹ̀wẹ̀sì: Ohun tí ọ̀pọ̀ èèyàn ń rò nípa wa tàbí ọ̀rọ̀ èké tí wọ́n fi ń bà wá jẹ́ lè fẹ́ mú wa ṣojo. Ṣùgbọ́n, rántí gbólóhùn aláìṣojo tí Pétérù àti àwọn àpọ́sítélì yòókù sọ níwájú Sànhẹ́dírìn, bó ṣe wà lákọọ́lẹ̀ ní Ìṣe 5:29-31. Gẹ́gẹ́ bí Gàmálíẹ́lì tó jẹ́ olùkọ́ Òfin ṣe sọ, iṣẹ́ Ọlọ́run ò ṣeé bì wó. Kì í ṣe agbára wa la fi ń ṣe é. Ọlọ́run ló ń ti iṣẹ́ bàǹtàbanta yìí lẹ́yìn, òun nìkan ló sì lè ṣe é láṣeparí!—Sek. 4:6.
5 Ẹ jẹ́ kí á máa bẹ Jèhófà lójoojúmọ́ pé kí ẹ̀mí rẹ̀ máa ràn wá lọ́wọ́ kí a lè máa fi ìtara polongo ìhìn rere náà. Ǹjẹ́ kí a lè sọ bí Jeremáyà ti sọ pé ṣe ni ìhìn Ìjọba náà dà bí iná tí ń jó nínú egungun wa. (Jer. 20:9) A ò gbọ́dọ̀ dákẹ́!