ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • km 9/00 ojú ìwé 7
  • Àwọn Ìfilọ̀

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Àwọn Ìfilọ̀
  • Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2000
Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2000
km 9/00 ojú ìwé 7

Àwọn Ìfilọ̀

◼ Ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ tí a ó fi lọni ní oṣù September: Ìmọ̀ Tí Ń Sinni Lọ sí Ìyè Àìnípẹ̀kun. October: Àwọn ẹ̀dà Ilé Ìṣọ́ àti Jí! Bí wọ́n bá fi ìfẹ́ hàn nígbà ìpadàbẹ̀wò, a lè fi ìforúkọsílẹ̀ fún ìwé ìròyìn lọ̀ wọ́n. Bẹ̀rẹ̀ láti apá ìparí oṣù yìí, a óò pín Ìròyìn Ìjọba, nọnba 36 kiri. November: Pípín Ìròyìn Ìjọba, nọnba 36 kiri yóò máa bá a nìṣó. Àwọn ìjọ tó bá kárí ìpínlẹ̀ wọn tán nípa mímú Ìròyìn Ìjọba, nọnba 36 dé ọ̀dọ̀ gbogbo onílé àti ibi tí àwọn ènìyàn wà, lè fi ìwé pẹlẹbẹ Béèrè tàbí ìwé Ìmọ̀ lọni. Bí àwọn èèyàn bá ti ní ìwọ̀nyí tẹ́lẹ̀, a lè lo ìwé Walaaye Titilae. December: Ìmọ̀ Tí Ń Sinni Lọ sí Ìyè Àìnípẹ̀kun pẹ̀lú Ìwé Mímọ́ ní Ìtumọ̀ Ayé Tuntun.

◼ Gbogbo ìgbà ló ń pọndandan pé ká pèsè ìrànwọ́ nígbà tí jàǹbá bá ṣẹlẹ̀. Bí o bá fẹ́ fowó ṣètìlẹyìn ìpèsè ìrànwọ́, o lè fi ọrẹ rẹ ránṣẹ́ sí Society, níbi tí wọ́n ti ya owó ìrànwọ́ sọ́tọ̀ fún ète yìí. Àdírẹ́sì ni: Watch Tower, P.M.B. 1090, Benin City, Edo State. (Wo Jí!, October 8, 1986, ojú ìwé 23 sí 25.) Jọ̀wọ́, má ṣe fi aṣọ, oúnjẹ, tàbí àwọn nǹkan èlò ránṣẹ́ sí Society tàbí sí ibi tí jàǹbá ti ṣẹlẹ̀ àyàfi tí Society tàbí ìgbìmọ̀ tí ń pèsè ìrànwọ́ bá sọ ní pàtó pé kí o ṣe bẹ́ẹ̀. Èyí yóò mú kí ó ṣeé ṣe láti pèsè ìrànwọ́ lọ́nà tó wà létòlétò, a óò sì lè pín àwọn nǹkan lọ́nà yíyẹ.

◼ A ń rán àwọn alàgbà létí láti ṣiṣẹ́ lórí ìtọ́ni táa là kalẹ̀ nínú Ilé-ìṣọ́nà ti April 15, 1991, ní ojú ìwé 21 sí 23, tó ní í ṣe pẹ̀lú àwọn táa yọ lẹ́gbẹ́ tàbí tí wọ́n yọ ara wọn lẹ́gbẹ́, tí wọ́n lè fẹ́ kí a gbà wọ́n padà.

◼ Kí àwọn tí ń dara pọ̀ mọ́ ìjọ fi gbogbo ìforúkọsílẹ̀ fún Ilé Ìṣọ́ àti Jí! ránṣẹ́ nípasẹ̀ ìjọ, yálà ìforúkọsílẹ̀ tuntun tàbí èyí tó fẹ́ parí ṣùgbọ́n tí wọ́n fẹ́ kó máa bá a nìṣó.

◼ Kì í ṣe Society ló ń kọ ọ̀rọ̀ sínú fọ́ọ̀mù ìbéèrè fún ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ ti akéde kọ̀ọ̀kan. Kí alábòójútó olùṣalága ṣètò fún ìfilọ̀ lóṣooṣù kí a tó fi ìbéèrè fún ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ ti ìjọ lóṣooṣù ránṣẹ́ sí Society, kí olúkúlùkù ẹni tó bá fẹ́ láti gba ìwé tirẹ̀ lè sọ fún arákùnrin tí ń bójú tó ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́. Ẹ jọ̀wọ́, ẹ rántí pé àwọn ìtẹ̀jáde kan wà tó jẹ́ ìbéèrè àkànṣe.

◼ Àwọn Ìtẹ̀jáde Tuntun Tí Ó Wà:

Ìdìpọ̀ Ilé Ìṣọ́ ọdún 1999—Gẹ̀ẹ́sì

Ìdìpọ̀ Jí! ọdún 1999—Gẹ̀ẹ́sì

◼ Kásẹ́ẹ̀tì Àfetígbọ́ Tuntun Tí Ó Wà:

Appreciating Our Spiritual Heritage (Àwòkẹ́kọ̀ọ́, kásẹ́ẹ̀tì kan)—Gẹ̀ẹ́sì

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́