ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • km 10/00 ojú ìwé 1
  • Jàǹfààní Nínú Ìtòlẹ́sẹẹsẹ Ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́ Jèhófà

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Jàǹfààní Nínú Ìtòlẹ́sẹẹsẹ Ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́ Jèhófà
  • Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2000
Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2000
km 10/00 ojú ìwé 1

Jàǹfààní Nínú Ìtòlẹ́sẹẹsẹ Ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́ Jèhófà

1 Ọ̀dọ́kùnrin kan ní Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà ní iṣẹ́ àtàtà tó ń buyì kúnni lọ́wọ́—ó ń ṣiṣẹ́ ní ilé iṣẹ́ tí wọ́n ti ń ṣe ohun ìjà àti àwọn ọkọ̀ tí ń lọ sí gbalasa òfuurufú. Ṣùgbọ́n, nígbà tó wá kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, ó rí i pé iṣẹ́ tí òun ń ṣe tako àwọn ìlànà inú Bíbélì. (Aísá. 2:4) Ẹ̀rí ọkàn rẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí dà á láàmú. Ó wá rí i kedere pé òun ò ní lè máa bá iṣẹ́ yìí lọ kí òun sì ní ẹ̀rí ọkàn tó mọ́. (1 Pét. 3:21) Ọ̀pọ̀ èèyàn lónìí ló ti fi ọ̀pọ̀ ọdún lépa àwọn iṣẹ́ kan tí wọ́n wá rí i lẹ́yìn ọ̀ rẹyìn pé ó tako àwọn ìlànà Bíbélì. Báwo la ṣe lè mọ ipa ọ̀nà tí yóò mú àǹfààní pípẹ́ títí wá?

2 Ìtòlẹ́sẹẹsẹ Ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́ Jèhófà Tó Dára Jù Lọ: Jèhófà ń kọ́ wa ní ohun tí ète ìgbésí ayé jẹ́ ní ti gidi gan an àti bí a ṣe lè lo ìgbésí ayé wa lọ́nà tí yóò mú àǹfààní tó wà títí láé wá fún wa. Ó ń kọ́ wa pé ká ṣe iṣẹ́ rere. (Éfé. 4:28) Ó ń kọ́ wa bí a ṣe lè mú ìgbésí ayé wa sunwọ̀n sí i, ì báà jẹ́ ní ti èrò orí, ní ti ìwà híhù, àti nípa tẹ̀mí. Ó ń kọ́ wa bí a ṣe lè gbé pọ̀ lálàáfíà pẹ̀lú àwọn ará, pẹ̀lú ìdílé wa àti ọmọnìkejì wa. Ìwé rẹ̀, Bíbélì, àti ètò àjọ rẹ̀ ló fi ń ṣe àwọn iṣẹ́ ribiribi yìí.

3 Àwọn ìpàdé ìjọ wa ṣe pàtàkì nínú èyí. Bí a ṣe ń lọ sí gbogbo ìpàdé márààrún déédéé táa sì ń kópa nínú wọn, a ń gba ìdálẹ́kọ̀ọ́ kíkúnrẹ́rẹ́ gẹ́gẹ́ bí òjíṣẹ́ ìhìn rere, a sì ń gba ìmọ̀ ẹ̀kọ́ tó kúnjú ìwọ̀n nípa ìgbésí ayé Kristẹni. (2 Tím. 3:16, 17) Olùkọ́ni Atóbilọ́lá wa tún ń pèsè ẹ̀kọ́ ìṣàkóso Ọlọ́run síwájú sí i nípasẹ̀ àwọn àpéjọ àti àpéjọpọ̀. Ohun tí ó yẹ kí ó jẹ́ góńgó wa ni pé a kì yóò pàdánù ìpàdé kan tàbí ìtòlẹ́sẹẹsẹ kan bí ìlera àti bí ipò tó yí wa ká bá gbà wá láyè láti lọ.

4 Ọ̀nà Àṣeyọrí Ni: A kà á nínú Sáàmù 1:1-3 pé: “Aláyọ̀ ni ènìyàn tí kò rìn nínú ìmọ̀ràn àwọn ẹni burúkú. . . . Inú dídùn rẹ̀ wà nínú òfin Jèhófà . . . Gbogbo nǹkan tí ó bá ń ṣe ni yóò sì máa kẹ́sẹ járí.” Ojúlówó àṣeyọrí ń wá láti inú mímú inú Ọlọ́run dùn, ìyẹn sì wé mọ́ títẹ̀ lé òfin Jèhófà tó wà nínú Bíbélì tí a sì tún ń ṣàlàyé ní àwọn ìpàdé Kristẹni.

5 Ọ̀dọ́kùnrin tí a mẹ́nu kan ní ìpínrọ̀ àkọ́kọ́ yẹn bẹ̀rẹ̀ sí lọ sí ìpàdé pẹ̀lú àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí fi ẹ̀kọ́ Jèhófà sílò nínú ìgbésí ayé rẹ̀. Ó fi iṣẹ́ tó ń mówó gọbọi wá tó ń ṣe sílẹ̀, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí ṣe òmíràn tó mú kó ní “ẹ̀rí ọkàn rere” níwájú Jèhófà. Ó ya ìgbésí ayé ara rẹ̀ sí mímọ́ fún Jèhófà, ó sì ń sìn bí aṣáájú ọ̀nà. Ní báyìí, ó lè sọ pé: “Nígbà kan rí, ohun tí mo fi gbogbo ìgbésí ayé mi ṣe ni àwọn ohun ìjà olóró fún pípa àwọn èèyàn ẹlẹgbẹ́ mi. Àmọ́, Jèhófà, nínú inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí rẹ̀ ṣí ọ̀nà sílẹ̀ kí èmi àti ìdílé mi lè di ìránṣẹ́ tó ń fọkàn sìn ín, kí á sì ya ìgbésí ayé wa sọ́tọ̀ pátápátá fún mímú ìhìn rere náà nípa ilẹ̀ ayé tó jẹ́ Párádísè tọ àwọn èèyàn lọ.”

6 Ǹjẹ́ ká ṣakitiyan láti jẹ́ kí Jèhófà kọ́ wa lẹ́kọ̀ọ́, sí ìyìn Rẹ̀ àti àǹfààní wa àìnípẹ̀kun!— Aísá. 48:17.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́