Àtúnyẹ̀wò Ilé Ẹ̀kọ́ Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìṣàkóso Ọlọ́run
Àtúnyẹ̀wò láìṣí ìwé wò fún àkópọ̀ ẹ̀kọ́ tí a kárí nínú àwọn iṣẹ́ Ilé Ẹ̀kọ́ Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìṣàkóso Ọlọ́run fún àwọn ọ̀sẹ̀ January 1 sí April 23, 2001. Lo bébà ọ̀tọ̀ láti fi kọ ìdáhùn sí púpọ̀ nínú àwọn ìbéèrè náà, bí ó bá ti lè ṣeé ṣe fún ọ tó, ní ìwọ̀n àkókò tí a yàn.
[Àkíyèsí: Lákòókò àtúnyẹ̀wò alákọsílẹ̀, Bíbélì nìkan ni a lè lò láti dáhùn ìbéèrè èyíkéyìí. Àwọn ìtọ́kasí tí ó tẹ̀ lé àwọn ìbéèrè wà fún ìwádìí fúnra rẹ. Nọ́ńbà ojú ìwé àti ìpínrọ̀ lè má fara hàn nínú gbogbo àwọn ìtọ́kasí tí a ṣe sí Ilé Ìṣọ́.]
Dáhùn Òtítọ́ tàbí Èké sí ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn gbólóhùn tó tẹ̀ lé e yìí:
1. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé a ò gbọ́dọ̀ jẹ́ kí bí ọ̀ràn ṣe rí lára wa mú wa gbójú fo ìwà àìtọ́ bíburú jáì, a lè tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Jósẹ́fù nípa fífi àánú dárí ji ẹni tó ṣẹ̀ wá, tó sì ronú pìwà dà. (Jẹ́n. 42:21; 45:4, 5) [w99-YR 1/1 ojú ìwé 31 ìpínrọ̀ 2 àti 3]
2. Bí a bá mú ọ̀ràn pé ìwé Kíróníkà Kìíní ṣe ìtòlẹ́sẹẹsẹ àwọn ìtàn ìlà ìdílé kúrò, ńṣe ló wulẹ̀ ṣe àsọtúnsọ ohun tó wà nínú ìwé Sámúẹ́lì Kejì àti ìwé Àwọn Ọba. [w85-YR 11/1 ojú ìwé 27 ìpínrọ̀ 1 àti 2]
3. Sólómọ́nì Ọba ‘tún Tádímórì kọ́’ nítorí ó jẹ́ ibi pàtàkì fún ire ìjọba rẹ̀ bí ó ti jẹ́ ibùdó àwọn ológun fún dídáàbò bo ìhà àríwá, ó sì tún jẹ́ ìkòríta ọ̀nà àwọn arìnrìn-àjò. (2 Kíró. 8:4) [Bíbélì kíkà ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀; wo w99-YR 1/15 ojú ìwé 28 ìpínrọ̀ 3.]
4. Jésù fi ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ rẹ̀ hàn nípa títẹ́wọ́ gba iṣẹ́ àrà ọ̀tọ̀ ti wíwá sáyé láti àjùlé ọ̀run, kí ó sì di ènìyàn rírẹlẹ̀, tó kéré sí àwọn áńgẹ́lì. (Fílí. 2:5-8; Héb. 2:7) [w99-YR 2/1 ojú ìwé 6 ìpínrọ̀ 3]
5. Ìwalẹ̀pìtàn fìdí gbígbógun tí Ṣíṣákì gbógun ti Júdà tó sì kó “àwọn ìṣúra ilé Jèhófà àti àwọn ìṣúra ilé ọba” múlẹ̀. (2 Kíró. 12:9) [Bíbélì kíkà ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀; wo w88-YR 2/1 ojú ìwé 26 ìpínrọ̀ 4.]
6. Ète ìmọ̀ràn ni láti ‘tọ́ ẹni tó ṣàṣìṣe sọ́nà,’ kì í ṣe láti fipá mú un ṣe ìyípadà tí kò fẹ́ ṣe. [w99-YR 1/15 ojú ìwé 22 ìpínrọ̀ 2]
7. Ńṣe ló yẹ kéèyàn máa sin Ọlọ́run láìní èrò pé òun yóò rí ẹ̀san gbà. [w99-YR 4/15 ojú ìwé 16 ìpínrọ̀ 1]
8. Nígbà tí Dáfídì ń sọ̀rọ̀ nípa “ìgbòkègbodò iṣẹ́” Jèhófà, bó ti wà lákọọ́lẹ̀ ní Sáàmù 103:2, àwọn ohun tí Jèhófà ṣẹ̀dá tí a lè fojú rí ló ní lọ́kàn. [w99-YR 5/15 ojú ìwé 21 ìpínrọ̀ 5 àti 6]
9. Àwọn alátakò kò lè ṣèdènà kíkọ́ tẹ́ńpìlì nígbà ayé Ẹ́sírà nítorí Jèhófà ṣolùṣọ́ àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ olóòótọ́. (Ẹ́sírà 5:5) [w86-YR 2/15 ojú ìwé 29 ìpínrọ̀ 2 àti 3]
10. Àwọn ìtàn ìlà ìdílé inú Kíróníkà Kìíní kò ṣe pàtàkì fún ẹni tó bá ń ka Bíbélì lóde òní. [w85-YR 11/1 ojú ìwé 28 ìpínrọ̀ 1 sí 3]
Dáhùn àwọn ìbéèrè tó tẹ̀ lé e yìí:
11. Bí ìwé Àwọn Ọba Kìíní ṣe sọ fún wa, ta ni Áhábù Ọba fẹ́, ipa wo sì ni ìgbéyàwó yẹn ní lórí Áhábù àti orílẹ̀-èdè náà? (1 Ọba 16:30-33; 18:13) [w85-YR 5/15 ojú ìwé 30 ìpínrọ̀ 3]
12. Báwo la ṣe lè gbé àwọn àníyàn wa sọ́dọ̀ Jèhófà? [w99-YR 3/15 ojú ìwé 23 ìpínrọ̀ 1 àti 2]
13. Ẹ̀kọ́ tí ń múni ronú jinlẹ̀ wo nípa ànímọ́ rere la lè rí kọ́ látinú ọ̀ràn Ùsáyà, ọba Júdà? (2 Kíró. 26:15-21) [Bíbélì kíkà ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀; wo w99-YR 12/1 ojú ìwé 26 ìpínrọ̀ 1 àti 2.]
14. Dípò kó jẹ́ pé ńṣe ni Jésù ń gbé ààtò kan kalẹ̀, ẹ̀kọ́ wo tó lágbára ni Jésù kọ́ wa nípa fífọ ẹsẹ̀ àwọn àpọ́sítélì rẹ̀? (Jòh. 13:4, 5) [w99-YR 3/1 ojú ìwé 31 ìpínrọ̀ 1]
15. Kí nìdí tí àkọsílẹ̀ inú 1 Kíróníkà 14:8-17 fi gbàfiyèsí nígbà ayé Aísáyà, kí sì nìdí tó fi yẹ kí Kirisẹ́ńdọ̀mù fiyè sí i lónìí? (Aísá. 28:21) [Bíbélì kíkà ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀; wo w91-YR 6/1 ojú ìwé 21 ìpínrọ̀ 2 àti 3.]
16. Kí làwọn nǹkan tí wọ́n ń ṣe nínú ìjọsìn Báálì tó mú kó fa ọ̀pọ̀ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì mọ́ra? [w99-YR 4/1 ojú ìwé 29 ìpínrọ̀ 3 sí 6]
17. Ẹ̀kọ́ gidi wo la lè rí kọ́ látinú iṣẹ́ tí Hesekáyà ṣe láti dáàbò bo orísun omi Jerúsálẹ́mù, àti láti mú kí ó pọ̀ sí i? (2 Kíró. 32:3, 4) [Bíbélì kíkà ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀; wo w96-YR 8/15 ojú ìwé 6 ìpínrọ̀ 1 àti 2.]
18. Báwo ni àpẹẹrẹ Jòsáyà ṣe lè jẹ́ ìṣírí fún àwọn ọ̀dọ́ lónìí pé kí wọ́n sin Ọlọ́run, kí wọ́n sì yẹra pátápátá fún ìjọsìn èké? (2 Kíró. 34:3, 8, 33) [Bíbélì kíkà ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀; wo w90-YR 8/1 ojú ìwé 5 ìpínrọ̀ 2.]
19. Ǹjẹ́ gbogbo àwọn Júù tó ṣẹ́ kù sí Bábílónì ló jẹ́ aláìṣòótọ́, ẹ̀kọ́ gidi wo la sì lè rí kọ́ látinú èyí? (Ẹ́sírà 1:3-6) [Bíbélì kíkà ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀; wo w86-YR 2/15 ojú ìwé 29 ìpínrọ̀ 4 àti 7.]
20. Kí ni ohùn orin àti kíkọrin nígbà ìfilọ́lẹ̀ tẹ́ńpìlì nígbà tí Jèhófà fi àwọsánmà tó ṣàrà ọ̀tọ̀ kún ilé rẹ̀ fi hàn? (2 Kíró. 5:13, 14) [Bíbélì kíkà ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀; wo w94-YR 5/1 ojú ìwé 10 ìpínrọ̀ 7.]
Pèsè ọ̀rọ̀ tàbí gbólóhùn tó yẹ kó wà ní àlàfo inú ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn gbólóhùn tó tẹ̀ lé e yìí:
21. Ẹni tó bá ń gba Kristẹni ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ nímọ̀ràn gbọ́dọ̀ rí i dájú pé òun gbé ohun tóun sọ ka __________________________ Ọlọ́run, kí ó má ṣe gbé e ka __________________________ àti __________________________ ènìyàn. (Kól. 2:8) [w99-YR 1/15 ojú ìwé 22 ìpínrọ̀ 1]
22. __________________________, tó jẹ́ __________________________ tó lọ́lá jù lọ àti __________________________ lọ́nà tó ga jù lọ, yóò ṣe ohun tó pọ̀ gan-an ju èyí tí Sólómọ́nì ṣe fún àwọn tó ṣe ìrúbọ fún Un. (2 Kíró. 9:12, 22) [Bíbélì kíkà ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀; wo w99-YR 11/1 ojú ìwé 23 ìpínrọ̀ 4.]
23. Gẹ́gẹ́ bí ẹ̀gún ti lè ṣèdíwọ́ fún irúgbìn kí ó má dàgbà, bẹ́ẹ̀ náà ni __________________________ tó pàpọ̀jù àti agbára ìtannijẹ __________________________ lè ṣèdíwọ́ fún ẹnì kan kó má lè dàgbà dénú nípa tẹ̀mí. (Mát. 13:19, 22) [w99-YR 3/15 ojú ìwé 22 ìpínrọ̀ 5]
24. Ipa yòówù kí á máa kó láàárín àwọn èèyàn Jèhófà tí a ṣètò, bí a bá ń làkàkà láti __________________________ —kódà nígbà tí ìdààmú bá dé—a óò jẹ́ orísun __________________________ fún àwọn onígbàgbọ́ ẹlẹgbẹ́ wa. [w99-YR 2/15 ojú ìwé 29 ìpínrọ̀ 1]
25. Kí Kristẹni tòótọ́ kan tó lè ṣàṣeyọrí níbi tí Sólómọ́nì ti kùnà, ó gbọ́dọ̀ fi gbogbo __________________________ tàbí __________________________ nínú ìjọsìn rẹ̀ sílẹ̀, kí ó sì ṣègbọràn sí àwọn ọ̀rọ̀ __________________________ láti ‘nífẹ̀ẹ́ Jèhófà Ọlọ́run rẹ̀ pẹ̀lú gbogbo ọkàn-àyà rẹ̀.’ (Mát. 22:37; 1 Kíró. 28:9) [Bíbélì kíkà ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀; wo w87-YR 3/1 ojú ìwé 31 ìpínrọ̀ 17 àti 18.]
Mú ìdáhùn tó tọ̀nà nínú ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn gbólóhùn tó tẹ̀ lé e yìí:
26. Àkọsílẹ̀ tó wà ní 2 Àwọn Ọba 17:5, 6 ròyìn bí (Tigilati-pílésà; Ṣálímánésà Karùn-ún; Esari-hádónì) ṣe gbógun ti ẹ̀yà mẹ́wàá ìjọba Ísírẹ́lì ti ìhà gúúsù, tó sì sàga ti Samáríà fún ọdún mẹ́ta, tí Samáríà sì ṣubú sọ́wọ́ àwọn ará Ásíríà níkẹyìn lọ́dún (740; 607; 537) ṣáájú Sànmánì Tiwa. [Bíbélì kíkà ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀; wo w88-YR 2/15 ojú ìwé 27 ìpínrọ̀ 1.]
27. A nílò (Ìwé Mímọ́ Lédè Hébérù; ẹ̀mí mímọ́) láti lè lóye (Ìwé Mímọ́ Kristẹni Lédè Gíríìkì; Ìwé Mímọ́). [w85-YR 5/15 ojú ìwé 30 ìpínrọ̀ 5]
28. Bí Ẹ́kísódù 4:11 ṣe fi hàn, Jèhófà Ọlọ́run ‘ló ń yan ẹni tí kò lè sọ̀rọ̀, adití, ẹni tí ó ríran kedere, àti afọ́jú’ nítorí pé òun (ló jẹ̀bi àwọn àléébù ara ti èèyàn ní; ló ń yan olúkúlùkù sẹ́nu àǹfààní iṣẹ́ ìsìn; lò fàyè gba kí àwọn àléébù ara hàn láàárín àwọn èèyàn). [w99-YR 5/1 ojú ìwé 28 ìpínrọ̀ 2]
29. Dáfídì Ọba ṣètò àwọn àlùfáà sí “ọ̀nà” tàbí ẹgbẹ́ (12; 24; 36), ó sì yan ẹgbẹ́ kọ̀ọ̀kan láti sìn fún (ọ̀sẹ̀ kan; ọ̀sẹ̀ méjì; oṣù kan) nínú tẹ́ńpìlì. [w85-YR 11/1 ojú ìwé 28 (àpótí)]
30. Ìbéèrè tí Sátánì béèrè pé: “Ṣé bẹ́ẹ̀ ni ní tòótọ́, pé Ọlọ́run sọ pé ẹ̀yin kò gbọ́dọ̀ jẹ nínú gbogbo igi ọgbà?” fi hàn pé (Sátánì kò mọrírì ohun tí Jèhófà pèsè; ó ń sọ pé Ọlọ́run ń fawọ́ ire ńláǹlà kan sẹ́yìn fún Éfà, ohun kan tó lè jẹ́ kí ojú rẹ̀ là, kí ó sì mú kí ó dà bí Ọlọ́run alára; Éfà kò fi ìmọrírì hàn fún ọ̀pọ̀ ìbùkún tí Jèhófà ti fún un). (Jẹ́n. 3:1, 5, 6) [w99-YR 4/15 ojú ìwé 17 ìpínrọ̀ 1]
So àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tó tẹ̀ lé e yìí mọ́ èyí tó bá a mu lára àwọn gbólóhùn tí a tò sí ìsàlẹ̀ yìí:
Lúùkù 14:28-30; Òwe 25:11; Róòmù 12:2; Òwe 22:4; Oníw. 7:14
31. Láti yí ìrònú wa padà kí á sì fi òtítọ́ Ọlọ́run kún èrò inú wa, ó ń béèrè ìsapá tí a fi ìmúratán ṣe. [w99-YR 4/1 ojú ìwé 22 ìpínrọ̀ 2]
32. Nígbà táa bá ń fúnni nímọ̀ràn, ó ṣe pàtàkì láti lo ọ̀rọ̀ yíyẹ. [w99-YR 1/15 ojú ìwé 23 ìpínrọ̀ 1]
33. Ó yẹ ká wéwèé, ká sì múra sílẹ̀ fún ojúṣe wa, ẹrù iṣẹ́ wa, ìpinnu wa, àti àwọn ìṣòro wa—yálà wọ́n jẹ́ kánjúkánjú tàbí wọn kò jẹ́ kánjúkánjú. [w99-YR 3/15 ojú ìwé 21 ìpínrọ̀ 3]
34. Yíyọ̀ǹda tí Ọlọ́run yọ̀ǹda kí á dojú kọ ayọ̀ àti wàhálà ń rán wa létí pé a kò lè mọ ohun tí yóò ṣẹlẹ̀ lọ́la. [w99-YR 5/1 ojú ìwé 29 ìpínrọ̀ 4 àti 5]
35. Ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ máa ń mú èrè púpọ̀ wá. [w99-YR 2/1 ojú ìwé 7 ìpínrọ̀ 6]