Kí Nìdí Tí Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Déédéé Nínú Ìdílé Fi Ṣe Pàtàkì Gan-an?
1 “Mo mà dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà o pé àwọn òbí mi kọ́ mi dáadáa! Mo mọ̀ pé ìyẹn wà lára ohun tó ràn mí lọ́wọ́ láti dúró ti ètò àjọ Jèhófà nígbà gbogbo.” Ọ̀rọ̀ yìí tí ọ̀kan lára Ẹgbẹ́ Olùṣàkóso sọ tẹnu mọ́ ipa ńláǹlà tí ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì déédéé nínú ìdílé máa ń ní. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ojoojúmọ́ la máa ń sá sókè sá sódò láti gbọ́ bùkátà, kí nìdí tí a fi ní láti máa ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì déédéé nínú ìdílé?
2 Ó Ń Fi Hàn Pé A Fẹ́ràn Ọlọ́run: Ìfẹ́ jíjinlẹ̀ táa ní sí Ọlọ́run yóò mú kí á máa tẹ̀ lé gbogbo ìtọ́ni rẹ̀. (1 Jòh. 5:3) Èyí kan kíkọ́ àwọn ọmọ wa látìgbà ọmọdé jòjòló. (Diu. 6:5-7) Ìwà àdánidá àwọn ọmọdé ni pé kí wọ́n fẹ́ láti kẹ́kọ̀ọ́. Wọ́n máa ń kíyè sí ohun tí a bá ṣe gidigidi, wọ́n sì máa ń gbọ́ ohun táa bá sọ, kíá ni wọ́n á sì bẹ̀rẹ̀ sí fara wé wa. (Òwe 20:7) Nítorí náà, àwọn ànímọ́ Ọlọ́run gbọ́dọ̀ kọ́kọ́ wà lọ́kàn àwọn òbí. Fífi irú àwọn ànímọ́ Ọlọ́run yìí hàn jẹ́ ẹ̀rí pé a fẹ́ràn Ọlọ́run.—Òwe 27:11.
3 Ààbò Ló Jẹ́: Nítorí pé àwọn ọmọ wa kò tíì ní ìrírí ìgbésí ayé, àwọn ni Sátánì àti ayé búburú rẹ̀ máa ń fojú sùn. Wọ́n máa ń fagbára mú wọn láti máa lépa ọrọ̀ àti àṣeyọrí lẹ́nu iṣẹ́ ayé. Àwọn ọmọ Kristẹni nílò ìrànwọ́ láti gbájú mọ́ àwọn ohun tẹ̀mí tí wọ́n lè lé bá, àìṣe bẹ́ẹ̀, wẹ́rẹ́ lọwọ́ á tẹ̀ wọ́n.—Róòmù 12:2.
4 Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì déédéé nínú ìdílé tá ò jẹ́ kó yẹ̀ lè ran àwọn ọmọ lọ́wọ́ láti gbé àwọn ohun tí wọ́n lè lé bá, tó bá Ìwé Mímọ́ mu kalẹ̀. Èyí kan fífúnra wọn ka Bíbélì déédéé lójoojúmọ́; dídi akéde tí kò tíì ṣèrìbọmi, àti bíbá a lọ dórí ìyàsímímọ́ àti ìrìbọmi. Àwọn ohun mìíràn tí wọ́n tún lè lé bá ni, ṣíṣe aṣáájú ọ̀nà olùrànlọ́wọ́, nínàgà fún iṣẹ́ ìsìn alákòókò kíkún ti dídi aṣáájú ọ̀nà, sísìn ní Bẹ́tẹ́lì; tàbí lílọ sí Ilé Ẹ̀kọ́ Ìdánilẹ́kọ̀ọ́ Iṣẹ́ Òjíṣẹ́. (Sm. 110:3) Ó dájú pé irú àwọn ohun tí wọ́n lè lé ba, tó bá Ìwé Mímọ́ mu yìí máa ń ran àwọn ọmọ lọ́wọ́ láti kojú ayé tí ìṣòro kún inú rẹ̀ dẹ́múdẹ́mú yìí.—Sm. 119:93.
5 Má Ṣe Dẹwọ́ Nínú Fífi Ọ̀nà Ọlọ́run Kọ́ Wọn: Níní ìdílé kan tó lágbára nípa tẹ̀mí gba òye àti àkókò. Má ṣe jẹ́ kí ohunkóhun dí ọ lọ́wọ́ láti lo àkókò tó yẹ láti fún ìdílé rẹ lókun kí o sì kọ́ wọn. Rí i dájú pé gbogbo àwọn tó wà nínú ìdílé rẹ mọ àkókò ìkẹ́kọ̀ọ́ ìdílé àti ibi tí ẹ óò kẹ́kọ̀ọ́. Ràn wọ́n lọ́wọ́ láti sọ ọ̀nà Ọlọ́run di tiwọn. (Sm. 119:33, 34, 66) Má ṣe dẹwọ́ nínú ìsapá rẹ láti máa bá ìdílé rẹ ṣèkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì déédéé. Ó níye lórí ju “èrè” ti ara èyíkéyìí lọ.—Sm. 119:36.