Àtúnyẹ̀wò Ilé Ẹ̀kọ́ Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Ọlọ́run
Àtúnyẹ̀wò pípa ìwé dé lórí àkópọ̀ ẹ̀kọ́ tí a kárí nínú àwọn iṣẹ́ àyànfúnni Ilé Ẹ̀kọ́ Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Ọlọ́run fún àwọn ọ̀sẹ̀ September 3 sí December 24, 2001. Lo abala tákàdá ọ̀tọ̀ láti fi kọ ìdáhùn sí púpọ̀ nínú àwọn ìbéèrè náà, bí ó bá ti lè ṣeé ṣe fún ọ tó, ní ìwọ̀n àkókò tí a yàn.
[Àkíyèsí: Lákòókò àtúnyẹ̀wò alákọsílẹ̀, Bíbélì nìkan ni a lè lò láti dáhùn ìbéèrè èyíkéyìí. Àwọn ìtọ́kasí tí ó tẹ̀ lé àwọn ìbéèrè wà fún ìwádìí tí o máa dá ṣe fúnra rẹ. Nọ́ńbà ojú ìwé àti ìpínrọ̀ lè má fara hàn nínú gbogbo àwọn ìtọ́kasí tí a ṣe sí Ilé Ìṣọ́.]
Dáhùn Bẹ́ẹ̀ Ni tàbí Bẹ́ẹ̀ Kọ́ sí ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn gbólóhùn tó tẹ̀ lé e yìí:
1. Ní Sáàmù 51:5, ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé ohun tí Dáfídì ní lọ́kàn ni pé ìbálòpọ̀ nínú ìgbéyàwó, ìlóyún àti ìbímọ jẹ́ ẹ̀ṣẹ̀, tàbí kó jẹ́ pé ńṣe ló ń tọ́ka sí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ pàtó kan tí ìyá rẹ̀ dá. [Bíbélì kíkà ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀; wo w86-YR 10/15 ojú ìwé 28 ìpínrọ̀ 8.]
2. Òótọ́ ni Sáàmù 58:4 sọ nígbà tó sọ pé “etí” ṣèbé kì í gbọ́ràn nítorí pé Ọlọ́run dá a ní adití. [Bíbélì kíkà ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀; wo Rbi8-E ojú ìwé 1583.]
3. Àwọn obìnrin tí Sáàmù 68:11 pè ní “ẹgbẹ́ ọmọ ogun ńlá” ni àwọn ẹrúbìnrin tí àwọn ọkùnrin Ísírẹ́lì máa ń dá sílẹ̀ lómìnira nígbà tí wọ́n bá ṣẹ́gun orílẹ̀-èdè àwọn ọ̀tá. [Bíbélì kíkà ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀; wo w86-YR 10/15 ojú ewé 30 ìpínrọ̀ 6.]
4. Bí a ṣe mẹ́nu kan “àwọn alágbára” ní Sáàmù 78:25 fi hàn pé Jèhófà ti ní láti lo àwọn áńgẹ́lì láti pèsè mánà náà. [Bíbélì kíkà ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀; wo w99-YR 8/15 ojú ìwé 25 ìpínrọ̀ 4.]
5. Ọ̀rọ̀ tí Pọ́ọ̀lù sọ pé “má ṣe jẹ́ kí ènìyàn kankan fojú tẹ́ńbẹ́lú èwe rẹ láé” fi hàn pé Tímótì kò tíì tó ọmọ ogún ọdún tàbí kó ṣẹ̀ṣẹ̀ lé díẹ̀ lógún ọdún nígbà yẹn. (1 Tím. 4:12) [w99-YR 9/15 ojú ìwé 29, ìpínrọ̀ 1 sí 3; ojú ìwé 31, ìpínrọ̀ 3]
6. Níbàámu pẹ̀lú àkọsílẹ̀ tó wà ní Sáàmù 110:1, “Olúwa mi” tọ́ka sí Jésù. [Bíbélì kíkà ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀; wo w94-YR 6/1 ojú ìwé 28 ìpínrọ̀ 5.]
7. A pe àwọn onídàájọ́ Ísírẹ́lì ní ọlọ́run nítorí pé agbára ńlá wà níkàáwọ́ wọn nínú ọ̀ràn ìdájọ́. [Bíbélì kíkà ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀; wo w86-YR 12/15 ojú ìwé 30 ìpínrọ̀ 7.]
8. Sáàmù 120 sí 134 ni a pè ní orin “ìgòkè” bóyá nítorí pé àwọn ọmọ Ísírẹ́lì máa ń kọ wọ́n nígbà tí wọ́n bá ń gòkè lọ sí Jerúsálẹ́mù, ìlú gíga náà, fún àjọyọ̀ wọn ẹlẹ́ẹ̀mẹ́ta lọ́dún. (Sm. 122:1) [Bíbélì kíkà ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀; wo w87-YR 3/15 ojú ìwé 21 ìpínrọ̀ 9.]
9. Ńṣe ni Òwe 8:22-31 wulẹ̀ ń ṣàpèjúwe ohun tí ọgbọ́n jẹ́. [w87-YR 5/15 ojú ìwé 28 ìpínrọ̀ 11]
10. Ìmọ̀ràn Bíbélì tá a rí nínú Òwe 21:17 pé ká yẹra fún ‘nínífẹ̀ẹ́ àríyá’ fi hàn pé ó burú láti gbádùn ara wa nítorí kì í jẹ́ kéèyàn ní àkókò fún àwọn ohun tó túbọ̀ ṣe pàtàkì. [Bíbélì kíkà ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀; wo w97-YR 10/1 ojú ìwé 27 ìpínrọ̀ 6.]
Dáhùn àwọn ìbéèrè tó tẹ̀ lé e yìí:
11. Kí ni ìbáwí onípẹ̀lẹ́tù tí Jésù fi tọ́ Màtá sọ́nà fi hàn? (Lúùkù 10:40, 41) [w99-YR 9/1 ojú ìwé 30 ìpínrọ̀ 7]
12. Inú “ògo” wo ni Jèhófà mú onísáàmù náà wọ̀? (Sm. 73:24) [Bíbélì kíkà ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀; wo w86-YR 12/15 ojú ìwé 30 ìpínrọ̀ 3.]
13. Irú èrò wo ni Onísáàmù náà ní nípa àwọn àǹfààní iṣẹ́ ìsìn bí a ti ṣàkọsílẹ̀ rẹ̀ ní Sáàmù 84:1-3? [Bíbélì kíkà ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀; wo w97-YR 3/15 ojú ìwé 8 ìpínrọ̀ 5 sí 7.]
14. Ọ̀nà wo ni Jèhófà gbà jẹ́ ‘Ọba lórí gbogbo àwọn ọlọ́run yòókù’? (Sm 95:3) [Bíbélì kíkà ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀; wo w86-YR 12/15 ojú ìwé 31 ìpínrọ̀ 5.]
15. Níwọ̀n bí àwọn Kristẹni àkọ́kọ́bẹ̀rẹ̀ ti gbà gbọ́ nínú Ẹgbẹ̀rún Ọdún Ìjọba Kristi gẹ́gẹ́ bí ìwé Ìṣípayá ti mẹ́nu kàn án, àwọn nǹkan wo ló mú kí àwọn Kristẹni apẹ̀yìndà kọ ẹ̀kọ́ àtọ̀runwá yìí sílẹ̀ lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn? [w99-YR 12/1 ojú ìwé 6 ìpínrọ̀ 3 sí ojú ìwé 7 ìpínrọ̀ 5]
16. Ààlà wo ló yẹ kí àwọn Kristẹni kíyè sí nígbà tí wọ́n bá ń mójú tó “ire ara ẹni” ti àwọn ẹlòmíràn? (Fílí. 2:4) [w99-YR 12/1 ojú ìwé 29 ìpínrọ̀ 1]
17. Kí ló túmọ̀ sí nígbà tí Sáàmù 128:3 sọ pé àwọn ọmọ yóò “dà bí àwọn àgélọ́ igi ólífì” yí tábìlì ẹnì kan ká? [Bíbélì kíkà ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀; wo w00-YR 8/15 ojú ìwé 30 ìpínrọ̀ 4.]
18. Bí a bá ṣàwárí pé iṣẹ́ Ọlọ́run jẹ́ amúnikún-fún-ẹ̀rù, báwo ló ṣe máa nípa lórí wa? (Sm. 139:14) [Bíbélì kíkà ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀; wo w93-YR 10/1 ojú ìwé 15 ìpínrọ̀ 18.]
19. Kí ni ìdí tí Òwe 5:3, 4 fi sọ pé ohun tí ìṣekúṣe máa ń yọrí sí nígbẹ̀yìn máa ń “korò bí iwọ” ó sì “mú bí idà olójú méjì”? [Bíbélì kíkà ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀; wo w00-YR 7/15 ojú ìwé 29 ìpínrọ̀ 2.]
20. Níbàámu pẹ̀lú Òwe 14:29, báwo ni ìfòyemọ̀ ṣe lè ràn wá lọ́wọ́ láti yẹra fún àwọn àbájáde tó ń wá látinú àìnísùúrù àti ìbínú tí a kò kápá rẹ̀? [Bíbélì kíkà ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀; wo w97-YR 3/15 ojú ìwé 13 ìpínrọ̀ 7 àti 8.]
Pèsè ọ̀rọ̀ tàbí gbólóhùn tó yẹ kó wà ní àlàfo inú ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn gbólóhùn tó tẹ̀ lé e yìí:
21. Sáàmù 72:16 ń tọ́ka sí ìkórè lọ́pọ̀ yanturu lọ́nà tí kò tíì sírú rẹ̀ rí nígbà ìṣàkóso __________________________ náà; ó tún fi hàn pé àwọn ọmọ abẹ́ Ìjọba Jésù lórí __________________________ yóò pọ̀ gidigidi. [Bíbélì kíkà ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀; wo w86-YR 10/15 ojú ìwé 29 ìpínrọ̀ 8.]
22. Ìdí méjì lá fi kọ ìwé Òwe—láti gbin __________________________ síni lọ́kàn àti láti __________________________. (Òwe 1:1-4) [w99-YR 9/15 ojú ìwé 13 ìpínrọ̀ 2]
23. “Ibi ìkọ̀kọ̀ Ẹni Gíga Jù Lọ” jẹ́ ibi __________________________ fún àwọn tó wà ní ìhà ti Ọlọ́run nínú ọ̀rọ̀ àríyànjiyàn __________________________ ; ó jẹ́ “ibi ìkọ̀kọ̀” tàbí ibi àìmọ̀ sí àwọn ènìyàn tí wọn __________________________. (Sáàmù 91:1) [Bíbélì kíkà ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀; wo w86-YR 12/15 ojú ìwé 31 ìpínrọ̀ 6.]
24. Dájúdájú, ‘ṣíṣàìgbàgbé gbogbo ìgbòkègbodò iṣẹ́ Jèhófà’ so mọ́ __________________________ lórí àwọn “iṣẹ́ rẹ̀,” ìyẹn àwọn ìṣe inú rere onífẹ̀ẹ́ rẹ̀ tí a ṣàpèjúwe nínú Sáàmù kẹtàlélọ́gọ́rùn-ún. (Sáàmù 103:2) [Bíbélì kíkà ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀; wo w99-YR 5/15 ojú ìwé 21 ìpínrọ̀ 5 àti 6.]
25. Àwọn òwe Sólómọ́nì nígbà púpọ̀ máà ń bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú __________________________. (Òwe 10:27; 14:26, 27; 15:16, 33) [w87-YR 5/15 ojú ìwé 29 ìpínrọ̀ 1]
Mú ìdáhùn tó tọ̀nà nínú ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn gbólóhùn tó tẹ̀ lé e yìí:
26. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Dáfídì ní ìdí láti bínú nítorí ohun tí Sọ́ọ̀lù fojú rẹ̀ rí, ó kó ara rẹ̀ níjàánu nítorí (ó mọ̀ pé aláìpé ni Sọ́ọ̀lù àti pé àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run gbọ́dọ̀ máa dárí jini; kò fi ìbátan rẹ̀ pẹ̀lú Jèhófà ṣeré rárá; ó mọ̀ pé ó burú láti máa dáni lẹ́jọ́). (1 Sám. 24:6, 15) [w99-YR 8/15 ojú ìwé 8 ìpínrọ̀ 7]
27. Onírúurú ànímọ́ ló para pọ̀ jẹ́ (ọgbọ́n; ìbáwí; òdodo), lára rẹ̀ ni òye, àròjinlẹ̀, lílo làákàyè, àti agbára láti ronú; (ìwà rere; òye; ìdájọ́ rere) ni agbára àtiyẹ kúlẹ̀kúlẹ̀ ọ̀ràn wò, kí a sì mọ bó ṣe rí nípa wíwo gbogbo ohun tó jẹ mọ́ ọn, kí a sì tipa bẹ́ẹ̀ mọ ohun tó túmọ̀ sí. (Òwe 1:1-4) [w99-YR 9/15 ojú ìwé 13 ìpínrọ̀ 3]
28. Agbára tí Jósẹ́fù ní láti dènà ìwà pálapàla tí aya Pọ́tífárì ń fi lọ̀ ọ́ wá látinú (ìmọ̀ tó ní nípa Òfin Mósè, èyí tó dá ìwà àgbèrè lẹ́bi; ọ̀wọ̀ jíjinlẹ̀ tó ní fún ipò orí ọkọ̀ obìnrin náà; kíkà tó ka àjọṣe rẹ̀ pẹ̀lú Jèhófà sí ohun iyebíye). (Jẹ́n. 39:7-9) [w99-YR 10/1 ojú ìwé 29 ìpínrọ̀ 3]
29. Ó dájú pé ẹni tó kọ Sáàmù kọkàndínlọ́gọ́fà ní ìmọrírì tó jinlẹ̀ fún (ọ̀rọ̀ tàbí òfin Ọlọ́run; ẹ̀bùn ìwàláàyè; ìrètí ìgbàlà), èyí tó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ pé gbogbo ẹsẹ Sáàmù náà ló ti mẹ́nu kàn án. [Bíbélì kíkà ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀; wo w99-YR 11/1 ojú ìwé 10 ìpínrọ̀ 5; w87-YR 3/15 ojú ìwé 21 ìpínrọ̀ 2.]
30. Ní ọjọ́ (wíwà níhìn-ín; ìṣàkóso; ẹgbẹ́ ológun) Mèsáyà Ọba, àwọn ọmọ-abẹ́ rẹ̀ ń yọ̀ọ̀da ara wọn kíákíá àti tayọ̀tayọ̀ tí iye wọn sì pọ̀ tó bẹ́ẹ̀ tí a fi lè fi wọ́n wé (ìsẹ̀-ìrì, ẹgbẹ́ ológun ńlá; ogunlọ́gọ̀ ńlá kan). (Sm. 110:3) [w87-YR 3/15 ojú ìwé 21 ìpínrọ̀ 4]
So àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tó tẹ̀ lé e yìí mọ́ èyí tó bá a mu lára àwọn gbólóhùn tí a tò sí ìsàlẹ̀ yìí:
Sm. 41:3; Òwe 2:19; 11:2; 14:15; Héb. 13:18
31. Bí ọ̀kan nínú àwọn olùjọsìn Jèhófà bá ń ṣàìsàn, yóò fún un lókun nípa tẹ̀mí. [w99-YR 9/1 ojú ìwé 6 ìpínrọ̀ 7]
32. Àwọn Kristẹni kò lè lọ́wọ́ nínú òwò tó kún fún màgòmágó tàbí tí kò gba ire àwọn ẹlòmíràn rò. [w99-YR 9/15 ojú ìwé 10 ìpínrọ̀ 2]
33. Àwọn tó ń lọ́wọ́ nínú ìṣekúṣe lè kàndin nínú iyọ̀ nípa rírìn débi tí iwájú ò ti ní ṣeé lọ, tí ẹ̀yìn ò sì ní ṣeé padà sí, kí wọ́n sì tipa bẹ́ẹ̀ ríkú he. [w99-YR 11/15 ojú ìwé 27 ìpínrọ̀ 3 àti 4]
34. Ẹni kan tó mòye tó sì ní ìfòyemọ̀ máa ń ro ohun tó máa jẹ́ àbájáde àwọn ìwà rẹ̀ kò sì ní fi pẹ̀lú àìronújinlẹ̀ tẹ̀ lé àwọn àṣà tuntun kan kìkì nítorí pé wọ́n lókìkí. [Bíbélì kíkà ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀; wo g94-YR 12/8 ojú ìwé 16 ìpínrọ̀ 1.]
35. Èèyàn kan tó jẹ́ agbéraga ló ṣeé ṣe kó jẹ́ ọ̀yájú, èyí sì lè yọrí sí àbùkù, ìkọ̀sẹ̀, àti ìṣubú. [w87-YR 5/15 ojú ìwé 30 ìpínrọ̀ 6]