Ìgbàgbọ́ Wa Ń Sún Wa Ṣe Àwọn Iṣẹ́ Rere
1 Ìgbàgbọ́ ló sún Nóà, Mósè àti Ráhábù ṣe àwọn ohun tí wọ́n ṣe. Nóà kan ọkọ̀ áàkì. Mósè kọ àwọn àǹfààní onígbà kúkúrú tí ì bá máa gbádùn nínú àgbàlá Fáráò sílẹ̀. Ráhábù fi àwọn amí pa mọ́, lẹ́yìn náà ó ṣègbọràn sí ìtọ́ni tí wọ́n fún un, ó sì tipa bẹ́ẹ̀ gba ìdílé rẹ̀ là. (Heb. 11:7, 24-26, 31) Àwọn iṣẹ́ rere wo ni ìgbàgbọ́ wa ń sún wa ṣe lónìí?
2 Jíjẹ́rìí: Ìgbàgbọ́ ń sún wa láti sọ fún àwọn ẹlòmíràn nípa Ọlọ́run ìyanu wa àtàwọn ìpèsè tó ti ṣe ká lè ní ayọ̀ títí láé. (2 Kọ́r. 4:13) Nígbà míì, ẹ̀rù àtijẹ́rìí lè máa bà wá. Àmọ́ tá a bá ń ‘gbé Jèhófà sí iwájú wa nígbà gbogbo,’ àá rí okun gbà, ìbẹ̀rù á sì fò lọ. (Sm. 16:8) Nígbà náà, ìgbàgbọ́ wa yóò sún wa láti máa sọ ìhìn rere náà fún àwọn mọ̀lẹ́bí, àwọn aládùúgbò, àwọn tá a jọ ń ṣiṣẹ́, àwọn ọmọléèwé wa àtàwọn ẹlòmíràn ní gbogbo àkókò yíyẹ.—Róòmù 1:14-16.
3 Pípàdé Pọ̀: Lílọ sípàdé déédéé jẹ́ iṣẹ́ rere mìíràn tí ìgbàgbọ́ ń sún wa ṣe. Báwo ló ṣe jẹ́ bẹ́ẹ̀? Lílọ tí à ń lọ sáwọn ìpàdé Kristẹni déédéé ń fi ìdánilójú tá a ní hàn pé Jésù wà níbẹ̀ pẹ̀lú wa nípasẹ̀ ẹ̀mí mímọ́ Ọlọ́run. (Mát. 18:20) Ó ń fi ìfẹ́ àtọkànwá wa hàn láti “gbọ́ ohun tí ẹ̀mí ń sọ fún àwọn ìjọ.” (Ìṣí. 3:6) À ń kọbi ara sí àwọn ìtọ́ni tí à ń rí gbà nítorí pé ìgbàgbọ́ wa ń jẹ́ ká mọ̀ pé Jèhófà, Olùkọ́ wa Atóbilọ́lá, lẹni tó ń kọ́ wa.—Aísá. 30:20.
4 Àwọn Ohun Tí A Yàn Láti Ṣe: Ìdánilójú tó múná tá a ní nípa àwọn ohun gidi tí a kò tíì rí ń sún wa láti fi àwọn nǹkan tẹ̀mí sí ipò tó ṣe pàtàkì jù lọ nígbèésí ayé wa. (Heb. 11:1) Lọ́pọ̀ ìgbà, èyí máa ń béèrè pé ká fi àwọn nǹkan tara rúbọ. Fún àpẹẹrẹ, alàgbà kan kọ̀ láti tẹ́wọ́ gba iṣẹ́ oúnjẹ òòjọ́ kan tó máa mówó rẹpẹtẹ wọlé, nítorí pé kò ní í fún un láyè láti máa wá sí àwọn ìpàdé kan, á máa fi ìdílé rẹ̀ sílẹ̀, kò sì ní í lè máa bá iṣẹ́ òjíṣẹ́ aṣáájú ọ̀nà rẹ̀ lọ mọ́. Ẹ jẹ́ kí àwa náà ní ìgbẹ́kẹ̀lé kíkún nínú ìdánilójú tí Bíbélì fún wa pé Jèhófà yóò pèsè fún àwọn tó bá ń “bá a nìṣó . . . ní wíwá ìjọba náà àti òdodo Rẹ̀ lákọ̀ọ́kọ́.”—Mát. 6:33.
5 Àwọn mìíràn ń kíyè sí agbára tí ìgbàgbọ́ ń sà nínú ìgbésí ayé wa. Ká sòótọ́, káàkiri ayé làwọn èèyàn mọ̀ nípa ìgbàgbọ́ wa. (Rom. 1:8) Nígbà náà, ẹ jẹ́ kí gbogbo wa fi hàn nípa àwọn iṣẹ́ rere wa pé ìgbàgbọ́ wa kì í ṣe òkú ìgbàgbọ́.—Ják. 2:26.