ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • km 9/02 ojú ìwé 7
  • Àwọn Ìfilọ̀

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Àwọn Ìfilọ̀
  • Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2002
Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2002
km 9/02 ojú ìwé 7

Àwọn Ìfilọ̀

◼ Ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ tí a ó fi lọni ní oṣù September: A lè fi èyíkéyìí nínú àwọn ìwé pẹlẹbẹ olójú ewé 32 tó tẹ̀ lé e yìí lọni: Akoso Naa Ti Yoo Mu Paradise Wá, Gbádùn Iwalaaye Lori Ilẹ Ayé Titilae!, Iwọ Ha Nilati Gbàgbọ́ Ninu Mẹtalọkan Bí?, Ki Ni Ète Igbesi-Aye? Bawo Ni Iwọ Ṣe Le Rí I?, Kí Ní Ń Ṣẹlẹ̀ sí Wa Nígbà Tí A Bá Kú?, Nígbà Tí Ẹnìkan Tí Ìwọ Fẹ́ràn Bá Kú?, Orukọ Atọrunwa naa Tí Yoo Wà Titilae, Ọlọrun Ha Bikita Nipa Wa Niti Gidi Bi? àti “Sawo O! Emi Nsọ Ohun Gbogbo Di Ọtun.” A tún lè fi àwọn ìwé pẹlẹbẹ wọ̀nyí, Ẹmi Awọn Oku—Wọn Ha Le Ran Ọ Lọwọ Tabi Pa Ọ Lara Bi? Wọn Ha Wa Niti Gidi Bi?, Ìwé Kan Tí Ó Wà fún Gbogbo Ènìyàn àti Ìwọ́ Lè Di Ọ̀rẹ́ Ọlọ́run, lọni níbi tó bá ti bá àkókò mu. October: Ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́ àti Jí! Níbi tí ẹnì kan bá ti fi ìfẹ́ hàn, fi ìwé pẹlẹbẹ Béèrè lọ̀ ọ́, kí o sì sapá láti bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. November: Kí Ni Ọlọrun Ń Béèrè Lọ́wọ́ Wa? tàbí Ìmọ̀ Tí Ń Sinni Lọ sí Ìyè Àìnípẹ̀kun. Bí onílé bá ti ní àwọn ìwé wọ̀nyí, o lè fi ìwé kan tí ọjọ́ rẹ̀ ti pẹ́ lọ̀ ọ́. December: Ọkunrin Titobilọla Julọ Ti O Tii Gbé Ayé Rí. Bí kò bá sí, a lè fi Iwe Itan Bibeli Mi, tàbí ìwé Iwọ Le Walaaye Titilae ninu Paradise lori Ilẹ Aye lọni.

◼ A ti ṣe àwọn ìyípadà tó wà nísàlẹ̀ yìí nínú “Àwọn Ibi Tí A Ó Ti Ṣe Àpéjọ Àgbègbè ti Ọdún 2002” èyí tó wà nínú àkìbọnú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa ti May 2002. Kí alábòójútó olùṣalága ìjọ èyíkéyìí tí a bá ti yí déètì tàbí ibi tí wọn yóò ti ṣe àpéjọ padà jọ̀wọ́ ṣètò kí a ṣèfilọ̀ rẹ̀ ní Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn tí wọn yóò ṣe lẹ́yìn tí wọ́n bá ti rí ìtẹ̀jáde Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa yìí gbà.

November 8-10, 2002

ẸNÚGU 1 (Gẹ̀ẹ́sì) EE-12: Ayangba, Ogugu, Otukpa, Ubiadu, àti Oguma Iso.; EE-17: Amanato, City Layout, Federal Housing, Hilltop, Ihe, Lakecity, Lakeside, Liberty, Odenigbo, àti Trans Ekulu; EE-19: Mainland, Ndiagu, Onuasata, Real Estate, Station (Agbani), Uhueze, Umunevo, Urban, àti Uwani

November 15-17, 2002

ÌLỌRIN 1 (Yorùbá) Y-13A; Y-14: Akata, Ìdí Òro, Ìrẹsà Dúdú, Jaṣẹnu, Odò Ọbà, Ọjàgbó, Onípélé, àti Òṣupà; Y-18: Ayetẹ́jú Àmùrò, Ẹ̀gbẹ̀, Ìsánlú, Mọ̀pà, àti Odòbùkún

November 22-24, 2002

MGBOKO UMUORIA 7 (Ìgbò) IB-14: A sí N; IB-16: A sí O; IB-18: A sí O ÀYÀFI Aleto, Odagwa, àti Opobo Town; IB-35 ÀYÀFI Amaogudu, Ihuibe, Mpu, Amaeze (Ishiagu), Akpoha, àti Amangwu Edda; IB-38: B sí N

November 29–December 1, 2002

AGBOR 5 (Gẹ̀ẹ́sì) ME-10: Farm Settlement, Igwete, Ishimili, Ndemili, Ogbe Onishe, Olieogo, Umuekum, àti Utagba Uno; ME-14: Gbogbo ìjọ tí a kò yàn sí Agbor 3; ME-15: A sí N

ẸNÚGU 4 (Ìgbò) IB-2: O sí Z; IB-3; IB-34: B sí Z; IB-35: Amangwu Edda

ÙBOGÒ 7 (Gẹ̀ẹ́sì) ME-6: A sí B; ME-7: A sí D; ME-9: A sí Az; ME-10 ÀYÀFI Enede, Farm Settlement, Igwete, Ishimili, Ndemili, Ogbe Onishe, Olieogo, Oloa, Umuekum, àti Utagba Uno

December 6-8, 2002

DÁLÙWỌ́N 7 (Yorùbá) Y-8: Gbogbo ìjọ tí a kò yàn sí Dálùwọ́n 1; Y-9: A sí L

January 3-5, 2003

IGWURUTA ALI 10 (Gẹ̀ẹ́sì, Èdè Àwọn Adití Lọ́nà ti Amẹ́ríkà) EE-4: Unyengala; EE-22: M sí Z; EE-23: J sí Z; EE-28: C sí K

◼ À ń rán àwọn alàgbà létí láti ṣiṣẹ́ lórí àwọn ìtọ́ni tá a pèsè nínú Ilé-ìṣọ́nà ti April 15, 1991, ní ojú ìwé 21 sí 23, èyí tó ní í ṣe pẹ̀lú ọ̀ràn àwọn tí a yọ lẹ́gbẹ́ tàbí tí wọ́n yọ ara wọn lẹ́gbẹ́, tí wọ́n lè fẹ́ kí a gba àwọn padà.

◼ Kì í ṣe ẹ̀ka ọ́fíìsì wa níbí ló ń kọ ọ̀rọ̀ sínú fọ́ọ̀mù ìbéèrè fún ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ ti akéde kọ̀ọ̀kan. Kí alábòójútó olùṣalága ṣètò kí a máa ṣèfilọ̀ lóṣooṣù kí a tó fi fọ́ọ̀mù ìbéèrè fún ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ tí ìjọ nílò fún oṣù kọ̀ọ̀kan ránṣẹ́ sí ẹ̀ka ọ́fíìsì, kí olúkúlùkù ẹni tó bá fẹ́ láti gba ìwé tirẹ̀ lè sọ fún arákùnrin tí ń bójú tó ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́. Ẹ jọ̀wọ́, ẹ rántí pé àwọn ìtẹ̀jáde kan wà tí kíkọ̀wé béèrè fún wọn jẹ́ àkànṣe.

◼ Nígbà míì, àwọn ìjọ àtàwọn akéde kọ̀ọ̀kan máa ń dojú kọ àwọn ọ̀ràn òfin tó jẹ mọ́ ìjọsìn wa sí Jèhófà. A tẹ ìwé kékeré náà, Defending and Legally Establishing the Good News jáde lọ́dún 1950 láti ṣèrànwọ́ lórí àwọn ọ̀ràn wọ̀nyí. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ìwé yìí la ti máa ń lò látẹ̀yìnwá, àwọn ìsọfúnni tó ní í ṣe pẹ̀lú òfin tó wà nínú rẹ̀ kò bóde mu mọ́. Nítorí náà, àwọn akéde kankan àtàwọn ẹgbẹ́ alàgbà kò gbọ́dọ̀ gbìyànjú láti fi ohun tó wà nínú ìwé kékeré yẹn bójú tó ọ̀ràn òfin.

◼ Àkànṣe àsọyé fún gbogbo èèyàn fún sáà Ìṣe Ìrántí ti ọdún 2003 ni a óò sọ ní ọjọ́ Sunday, April 27. A óò ṣèfilọ̀ àkọlé àsọyé náà bí àkókò bá tó, a óò sì pèsè ìlapa èrò fún àsọyé. Kí àwọn ìjọ tí wọ́n bá ní ìbẹ̀wò alábòójútó àyíká, àpéjọ àyíká, tàbí àpéjọ àkànṣe ní òpin ọ̀sẹ̀ yẹn sọ àkànṣe àsọyé yìí ní ọ̀sẹ̀ tó tẹ̀ lé e. Kí ìjọ kankan má ṣe sọ àkànṣe àsọyé yìí ṣáájú April 27, 2003.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́