Ṣọ́ra fún Àwọn Ewu Fífarasin Tó Wà Nínú Ṣíṣílọ Sí Orílẹ̀-Èdè Mìíràn Láìbófinmu
1 Nítorí ipò ọrọ̀ ajé tó ń jó rẹ̀yìn lójoojúmọ́ káàkiri àgbáyé, àwọn kan ti ṣí lọ sáwọn orílẹ̀-èdè ọlọ́rọ̀ lọ́nà tí kò bófin mu láti lọ wáṣẹ́ tó ń mówó wọlé gan-an. Nínú àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ kan, gbogbo ìdílé lódindi ti pa gbogbo tọ́rọ́-kọ́bọ̀ tí wọ́n ní pọ̀ tàbí kí wọ́n lọ yá owó rẹpẹtẹ láti bàa lè rán ẹnì kan nínú ìdílé wọn lọ sókè òkun. Ìrètí wọn ni pé, onítọ̀hún á rí towó ṣe lọ́hùn-ún, èyí ló sì máa sọ ìdílé akúṣẹ̀ẹ́ náà di olówó. Àwọn kókó wo ló yẹ kí ẹnì kan tó jẹ́ ìránṣẹ́ Jèhófà ronú lé lórí dáadáa kó tó pinnu láti ṣí lọ sí orílẹ̀-èdè mìíràn?
2 Ta Ni Àjèjì Tó Wọ̀lú Láìbófinmu? Ẹni tó ti orílẹ̀-èdè kan ṣí lọ sí òmíràn láìkọ́kọ́ gba ìwé àṣẹ tó yọ̀ǹda fún un láti máa gbé orílẹ̀-èdè tó ṣí lọ ni wọ́n ń pè bẹ́ẹ̀. Ṣíṣe bẹ́ẹ̀ jẹ́ rírú òfin. Bíbélì pàṣẹ fún àwọn Kristẹni láti ṣègbọràn sí gbogbo òfin Késárì tí kò bá ti tako òfin Ọlọ́run. (Ìṣe 5:29; Róòmù 13:1) Nípa bẹ́ẹ̀, wọ́n á lè ní ẹ̀rí ọkàn mímọ́, wọ́n á sì lè yẹra fún ìjìyà. Bí Kristẹni kan bá rú èyíkéyìí nínú àwọn òfin Késárì, ó ní láti dáhùn fún ohun tó ṣe kó sì fara mọ́ ìjìyà tó bá tọ́ sí i.—Róòmù 13:3-5.
3 Ó ṣeni láàánú pé, àwọn kan tó jẹ́ akéde ìhìn rere ti kọtí ikún sí ìmọ̀ràn Ìwé Mímọ́ tó wà lókè yìí. Wọ́n ti ṣí lọ sáwọn orílẹ̀-èdè òkèèrè láìbófinmu, wọ́n sì ń ṣiṣẹ́ níbẹ̀ láìgbàṣẹ. Lọ́pọ̀ ìgbà, irú ìgbésẹ̀ bẹ́ẹ̀ máa ń mú kí wọ́n tún gbé àwọn ìgbésẹ̀ ẹ̀tàn mìíràn tó ń múni dẹ́ṣẹ̀, irú bíi sísan owó àbẹ̀tẹ́lẹ̀ àti ṣíṣe ayédèrú ìwé àṣẹ ìrìnnà.—2 Kọ́r. 4:2.
4 Àwọn Ewu Tó Wà Lọ́nà: Nítorí pé ayédèrú ìwé àṣẹ ni wọ́n ní lọ́wọ́, ọ̀pọ̀ máa ń gba àwọn ọ̀nà ẹ̀bùrú tó lè yọrí sí ewu ńláǹlà. Àwọn kan ti kú nítorí pé ọkọ̀ ojú omi tí wọ́n wọ̀ dojú dé, ọ̀nì sì ti pa àwọn mìíràn jẹ bí wọ́n ṣe fẹ́ sọdá àwọn odò tó léwu. Àwọn mìíràn ti kú nínú aṣálẹ̀ nítorí ebi tàbí kí wọ́n bá ara wọn ní àgọ́ ìṣẹ́niníṣẹ̀ẹ́ tàbí kí wọ́n di aṣẹ́wó gbẹ̀yìn. A sábà máa ń gbọ́ pé àwọn ẹbí kì í gbúròó ará ilé wọn tó rìnrìn àjò lọ sókè òkun tàbí kí wọ́n má tiẹ̀ gbọ́ ohunkóhun nípa rẹ̀ mọ́ láéláé. Ṣé kì í ṣe pé àwọn kan lára irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ ti kú lọ́nà kan ṣáá nígbà tí wọ́n ń rìnrìn àjò lọ sí orílẹ̀-èdè ọlọ́rọ̀ tí wọ́n pinnu láti lọ, tàbí kẹ̀ kó jẹ́ pé wọ́n ti sọ wọ́n sẹ́wọ̀n?
5 Àwọn Ewu Tẹ̀mí: Àwọn ẹgbẹ́ ọ̀daràn tó ń ṣagbátẹrù oògùn olóró àti iṣẹ́ aṣẹ́wó ló máa ń ṣonígbọ̀wọ́ àwọn àjèjì láti wọ̀lú onílùú láìbófinmu, wọ́n sì sábà máa ń fipá mú wọn ṣe ohun tí wọ́n bá sọ fún wọn. Ẹlẹ́rìí kan tó pàdé àwọn kan tó ń ṣí lọ sí orílẹ̀-èdè mìíràn láìbófinmu ṣáájú kí wọ́n tó fi orílẹ̀-èdè rẹ̀ sílẹ̀ kọ ohun tó wà nísàlẹ̀ yìí ránṣẹ́ sí ọ̀kan lára àwọn ẹ̀ka ọ́fíìsì Society:
6 “Wọn [kì í pẹ́] kan ìdin nínú iyọ̀, tí wọ́n á sì wá lóye irú ‘iṣẹ́’ tí wọ́n máa ṣe. Àwọn tó ń ṣonígbọ̀wọ́ wọn á gba ìwé àṣẹ ọwọ́ wọn, wọ́n á sì [máa] fipá mú wọn láti ‘ṣiṣẹ́’ [aṣẹ́wó] lọ́sàn-án àti lóru láti fi san ‘gbèsè’ tí wọ́n jẹ. Ó lè gbà wọ́n ní ọ̀pọ̀ ọdún kí wọ́n tó tu irú owó bẹ́ẹ̀ jọ.”
7 Ǹjẹ́ wọ́n lè ké gbàjarè sí àwọn aláṣẹ pé kí wọ́n dáàbò bò wọ́n? Ìròyìn náà ń bá a lọ pé: “Bí wọ́n bá kọ̀ [láti ṣe ohun táwọn ọ̀daràn náà sọ,] ńṣe ni wọ́n máa nà wọ́n játijàti tí wọ́n á sì fipá bá wọn lòpọ̀ títí wọ́n á fi juwọ́ sílẹ̀, tí wọ́n á sì ṣe ohun tí wọ́n ní kí wọ́n ṣe. Yàtọ̀ sí pé wọ́n máa ń fi ìyà pá wọn lórí, àwọn tó jẹ́ ọ̀gá nínú ẹgbẹ́ ọ̀daràn náà tún máa ń halẹ̀ mọ́ wọn pé tí wọ́n bá sọ fún àwọn ọlọ́pàá, tàbí tí wọ́n gbìyànjú láti wá ìrànwọ́ ẹnikẹ́ni tàbí tí wọ́n bá gbìyànjú láti sá lọ pẹ́nrẹ́n, àwọ́n á lọ pa àwọn òbí tàbí àwọn mọ̀lẹ́bí wọn nílé tàbí kí àwọ́n ṣe wọ́n bí ọṣẹ ṣe ń ṣojú. Lára ‘ọgbọ́n’ táwọn ẹgbẹ́ ọ̀daràn bẹ́ẹ̀ máa ń ta ni pé, wọ́n tún máa ń [rí i dájú] pé àwọ́n pààrọ̀ [ibùgbé] àwọn ọmọbìnrin náà kí ojú wọn tó mọlé dáadáa ní àyíká tí wọ́n kó wọn lọ, nítorí èyí kò ní fún wọn láyè láti ní ibùgbé gidi kan, wọn kò sì ní ní olùrànlọ́wọ́, nípa bẹ́ẹ̀ á wá túbọ̀ rọrùn láti máa darí wọn bí wọ́n bá ṣe fẹ́.”—Fi wé 1 Tímótì 6:9, 10.
8 Ṣé wàá jẹ́ kí ipò tẹ̀mí ọmọ rẹ tàbí ti mọ̀lẹ́bí rẹ dìdàkudà bẹ́ẹ̀ nítorí àtidi ọlọ́rọ̀? Lóòótọ́ o, àwọn kan lè tiraka láti dé ibi tí wọ́n ń lọ láìdojúkọ èyíkéyìí lára àwọn ìṣòro tá a ṣẹ̀ṣẹ̀ mẹ́nu kàn wọ̀nyí. Àmọ́, nítorí ìbẹ̀rù kí ọwọ́ àwọn agbófinró má bàa tẹ̀ wọ́n, ńṣe ni wọ́n sábà máa ń fara pa mọ́, nípa bẹ́ẹ̀ kì í ṣeé ṣe fún wọn láti máa lọ sí ìpàdé ìjọ déédéé tàbí láti máa kópa nínú iṣẹ́ ìsìn pápá, èyí á sì ṣèpalára fún ipò tẹ̀mí wọn.—Mát. 24:14; 28:19; Héb. 10:23-25.
9 Bí a ṣe túbọ̀ ń wọnú àwọn ọjọ́ ìkẹyìn ètò àwọn nǹkan burúkú yìí, kò sí àní-àní pé ńṣe ni ipò àwọn nǹkan á máa le koko sí i. (2 Tím. 3:1-5) Òótọ́ ni pé, ojúṣe gbogbo wa lẹ́nì kọ̀ọ̀kan àti tàwọn olórí ìdílé ni láti gbọ́ bùkátà ara wa àti ti ìdílé wa. (Éfé. 4:28; 1 Tím. 5:8) Ṣùgbọ́n, ǹjẹ́ a kò ní ẹrù iṣẹ́ tó túbọ̀ ṣe pàtàkì jùyẹn lọ, ìyẹn bíbójútó àwọn àìní wa nípa tẹ̀mí?—Mát. 16:26.
10 Nítorí náà, ó bọ́gbọ́n mu pé kí gbogbo wa lẹ́nì kọ̀ọ̀kan àtàwọn olórí ìdílé ronú jinlẹ̀ lórí àwọn ewu tẹ̀mí tó fara sin wọ̀nyí, ká tó pinnu yálà láti ṣí lọ sí orílẹ̀-èdè òkèèrè nítorí ọ̀ràn ìṣúnná owó tàbí láti má ṣe ṣí lọ. Bí ìwọ tàbí mọ̀lẹ́bí rẹ kan bá fẹ́ rìnrìn àjò lọ sókè òkun nítorí ọ̀ràn àtijẹ-àtimu, rí i pé o gba ìwé àṣẹ tó pé pérépéré, kì í ṣe èyí tó máa fún ọ láyè láti máa gbé orílẹ̀-èdè ọ̀hún nìkan, àmọ́ kó o tún gba èyí tó máa fún ọ láṣẹ láti ṣiṣẹ́ níbẹ̀. Nígbà náà, wàá lè ké gbàjarè sí àwọn aláṣẹ tí Késárì ti gbé kalẹ̀ fún ààbò tó o bá bá ara rẹ nínú ìṣòro tó lè jin ipò tẹ̀mí rẹ lẹ́sẹ̀. Á ṣeé ṣe fún ọ láti ní àjọṣe tó dán mọ́rán pẹ̀lú Jèhófà bó o ti ń làkàkà láti ‘di ìgbàgbọ́ àti ẹ̀rí-ọkàn rere mú, èyí tí àwọn kan ti sọ́gọ sẹ́gbẹ̀ẹ́ kan, tí wọ́n sì ti ní ìrírí rírì ọkọ̀ ìgbàgbọ́ wọn.’—1 Tím. 1:19.