ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • km 11/02 ojú ìwé 7
  • Àwọn Ìfilọ̀

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Àwọn Ìfilọ̀
  • Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2002
Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2002
km 11/02 ojú ìwé 7

Àwọn Ìfilọ̀

◼ Ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ tí a ó fi lọni ní oṣù November: Kí Ni Ọlọrun Ń Béèrè Lọ́wọ́ Wa? tàbí Ìmọ̀ Tí Ń Sinni Lọ sí Ìyè Àìnípẹ̀kun. Bí onílé bá ti ní àwọn ìwé wọ̀nyí, o lè fi ìwé kan tí ọjọ́ rẹ̀ ti pẹ́ lọ̀ ọ́. December: Ọkunrin Titobilọla Julọ Ti O Tii Gbé Ayé Rí. Bí kò bá sí, a lè fi Iwe Itan Bibeli Mi, tàbí ìwé Iwọ Le Walaaye Titilae ninu Paradise lori Ilẹ Aye lọni. Bí ìjọ kò bá ní èyíkéyìí lára àwọn ìwé tá a lè fi lọni ní àfidípò yìí, ẹ béèrè bóyá àwọn ìjọ tó wà nítòsí yín ní púpọ̀ lọ́wọ́ tẹ́ ẹ lè rí lò. January: Ìwé èyíkéyìí tí a ti tẹ̀ jáde ṣáájú ọdún 1988 tí ìjọ bá ní lọ́wọ́. Bí ẹ kò bá ní èyíkéyìí lára ìwọ̀nyí, ẹ béèrè bóyá àwọn ìjọ tó wà nítòsí yín ní ọ̀pọ̀ àwọn ìwé tí ọjọ́ wọn ti pẹ́ lọ́wọ́ tẹ́ ẹ lè rí lò. Àwọn ìjọ tí kò bá ní àwọn ìwé tí ọjọ́ wọn ti pẹ́ lè fi ìwé Mankind’s Search for God lọni.

◼ Kí alábòójútó olùṣalága tàbí ẹnì kan tí ó bá yàn ṣàyẹ̀wò àkáǹtì ìjọ ní December 1 tàbí bí ó bá ti lè yá tó lẹ́yìn náà. Bí ẹ bá ti ṣe èyí, ẹ ṣèfilọ̀ rẹ̀ fún ìjọ lẹ́yìn tí ẹ bá ti ka ìròyìn ìnáwó ti oṣù tó ń bọ̀.

◼ Kí àwọn ìjọ bẹ̀rẹ̀ sí í kọ̀wé béèrè fún ìdìpọ̀ Ilé Ìṣọ́ àti ìdìpọ̀ Jí! ti ọdún 2002 nígbà tí wọ́n bá tún fẹ́ kọ̀wé béèrè fún àwọn ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ tí wọ́n nílò. Èdè Gẹ̀ẹ́sì ni àwọn ìdìpọ̀ náà máa jẹ́. Títí di ìgbà tí àwọn ìdìpọ̀ náà máa tó wà nílẹ̀ tí a ó sì kó o ránṣẹ́, ọ̀rọ̀ náà “Pending” ni yóò máa fara hàn lórí fọ́ọ̀mù tá a fi ń kó ẹrù ránṣẹ́ sí ìjọ. Àwọn ìwé ìdìpọ̀ wà lára àwọn ìtẹ̀jáde tí ẹ ní láti kọ̀wé béèrè fún lákànṣe.

◼ Ọ̀rọ̀ náà, “Watch Tower Bible and Tract Society” ni kí a máa kọ sórí ìwé sọ̀wédowó tí a fi ṣe ọrẹ fún iṣẹ́ kárí ayé àti Owó Àkànlò fún Kíkọ́ Gbọ̀ngàn Ìjọba.

◼ Ní báyìí, ó yẹ kí àwọn akéde ti ní ẹ̀dà ìwé Jàǹfààní Nínú Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run tiwọn lọ́wọ́. Kí gbogbo àwọn ará sapá láti ka àwọn ìsọfúnni inú rẹ̀ dáadáa ní ìmúrasílẹ̀ fún lílò ó ní Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run bẹ̀rẹ̀ láti January 2003.

◼ Àwọn Ìtẹ̀jáde Tuntun Tó Wà:

Jehovah’s Witnesses—Who Are They? What Do They Believe?—Tiv

Jàǹfààní Nínú Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run—Faransé

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́