ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • km 2/03 ojú ìwé 6
  • Àtúnyẹ̀wò Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Àtúnyẹ̀wò Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run
  • Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2003
Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2003
km 2/03 ojú ìwé 6

Àtúnyẹ̀wò Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run

Àwọn ìbéèrè tó wà nísàlẹ̀ wọ̀nyí la óò gbé yẹ̀ wò nínú àtúnyẹ̀wò aláfẹnusọ ní Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run ní ọ̀sẹ̀ tó bẹ̀rẹ̀ ní February 24, 2003. Alábòójútó ilé ẹ̀kọ́ yóò darí àtúnyẹ̀wò yìí fún ọgbọ̀n ìṣẹ́jú, èyí tá a gbé ka àwọn iṣẹ́ ilé ẹ̀kọ́ tá a ṣe ní ọ̀sẹ̀ January 6 sí ọ̀sẹ̀ February 24, 2003. [Àkíyèsí: Níbi tí a kò bá ti tọ́ka sí ibi tí a ti mú ìdáhùn jáde lẹ́yìn ìbéèrè kan, ṣe ìwádìí tìrẹ fúnra rẹ láti wá ìdáhùn sí àwọn ìbéèrè náà.—Wo ìwé Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run, ojú ìwé 36 àti 37.]

ÀNÍMỌ́ Ọ̀RỌ̀ SÍSỌ

1. Bẹ́ẹ̀ Ni Tàbí Bẹ́ẹ̀ Kọ́: Ohun tó lè ran ẹnì kan lọ́wọ́ láti kàwé lọ́nà tó tọ́ ni pé, kó ṣáà ti máa rí i dájú pé ohun tí òun ń kà jọ pé ó ń dún dáadáa, kódà bí ohun tí ó ń kà bá yàtọ̀ díẹ̀ sí ohun tí wọ́n kọ sílẹ̀. Ṣàlàyé. [be-YR ojú ìwé 83]

2. Fi Ọ̀rọ̀ Tó Yẹ Sínú Àwọn Àlàfo Yìí: Láti kàwé lọ́nà tó tọ́, ẹnì kan ní láti ․․․․․․․․, ․․․․․․․․, ․․․․․․․․, kó sì rí i pé òún ń kà á sókè. [be-YR ojú ìwé 85]

3. Kí nìdí tó fi ṣe pàtàkì láti máa sọ̀rọ̀ ketekete? (1 Kọ́r. 14:8, 9) [be-YR ojú ìwé 86]

4. Kí làwọn ohun díẹ̀ tó lè máà jẹ́ kí ọ̀rọ̀ ẹni dún jáde ketekete, kí la sì lè ṣe láti túbọ̀ máa sọ̀rọ̀ ketekete? [be-YR ojú ìwé 87 àti 88]

5. Àwọn ọ̀rọ̀ díẹ̀ wo ni a lò nínú Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run láàárín oṣù méjì tó kọjá tó o rò pé ó yẹ kó o kọ́ bí a ṣe ń pè wọ́n lọ́nà tó tọ́? [be-YR ojú ìwé 92]

IṢẸ́ AKẸ́KỌ̀Ọ́ KÌÍNÍ

6. Bẹ́ẹ̀ Ni Tàbí Bẹ́ẹ̀ Kọ́: Ojú wa lè ràn wá lọ́wọ́ láti fetí sílẹ̀. Ṣàlàyé. [be-YR ojú ìwé 14]

7. Fi Ọ̀rọ̀ Tó Yẹ Sínú Àwọn Àlàfo Yìí: Ohun tí Pọ́ọ̀lù rí lọ́nà nígbà tó ń lọ sí Damásíkù mú kí ó dá a lójú gbangba pé ․․․․․․․․ ni ․․․․․․․․, tàbí ․․․․․․․․ tá a ṣèlérí, ẹni tí yóò di alákòóso Ìjọba tá a ṣèlérí náà lọ́jọ́ iwájú. [w01-YR 4/1 ojú ìwé 5 ìpínrọ̀ 5]

8. Fi Ọ̀rọ̀ Tó Yẹ Sínú Àwọn Àlàfo Yìí: Ìhìn rere náà ṣe Pọ́ọ̀lù láǹfààní nítorí pé ó fi ․․․․․․․․ yọwọ́ kúrò nínú ohun tó yà á nípa sí Ọlọ́run, ó sì fi ․․․․․․․․ lépa àwọn ohun tó bá ète Ọlọ́run mu. [w01-YR 4/1 ojú ìwé 6 ìpínrọ̀ 3]

9. Báwo ni àpẹẹrẹ Hánà, Máàkù àti Èlíjà ṣe lè ràn wá lọ́wọ́ láti borí ìrẹ̀wẹ̀sì? Báwo la ṣe lè lo àwọn àpẹẹrẹ wọ̀nyí láti ran àwọn ẹlòmíràn lọ́wọ́? [w01-YR 2/1 ojú ìwé 20 sí 23]

10. Báwo ni mímọ̀ nípa àwọn eré ìdárayá ayé ọjọ́un ṣe mú kí àwọn ẹsẹ Bíbélì kan túbọ̀ ṣe kedere sí wa? Báwo ló ṣe yẹ kí ìsọfúnni yìí nípa lórí ìgbésí ayé wa? [w01-YR 1/1 ojú ìwé 28 sí 31]

BÍBÉLÌ KÍKÀ Ọ̀SỌ̀Ọ̀SẸ̀

11. Bẹ́ẹ̀ Ni Tàbí Bẹ́ẹ̀ Kọ́: Níwọ̀n bí a ti gbé Ìjọba Ọlọ́run kalẹ̀ ní ọ̀run lọ́dún 1914, kò yẹ ká tún ṣì máa gbàdúrà pé, “Kí ìjọba rẹ dé.” (Mát. 6:10) Ṣàlàyé. [be-YR ojú ìwé 279; w96-YR 6/1 ojú ìwé 31]

12. Bẹ́ẹ̀ Ni Tàbí Bẹ́ẹ̀ Kọ́: Ọ̀rọ̀ tí Jésù sọ nínú àkọsílẹ̀ Mátíù 11:24 túmọ̀ sí pé àwọn tí Jèhófà fi iná pa run ní Sódómù àti Gòmórà yóò ní àjíǹde. Ṣàlàyé.

13. Èwo Nìdáhùn: Ẹrú olóòótọ́ àti olóye tí Jésù mẹ́nu kàn nínú Mátíù 24:45-47 jẹ́ (a) Ẹgbẹ́ Olùṣàkóso ti Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà; (b) gbogbo àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró tó wà lórí ilẹ̀ ayé lápapọ̀ ní ìgbà èyíkéyìí; (d) Jésù Kristi fúnra rẹ̀. Ẹrú yìí ló ń pèsè oúnjẹ tẹ̀mí ní àkókò tí ó bẹ́tọ̀ọ́ mu fún “àwọn ará ilé” náà, èyí tó dúró fún (a) àwọn ẹni àmì òróró lẹ́nì kọ̀ọ̀kan; (b) àwọn àgùntàn mìíràn; (d) gbogbo àwọn tó ń ka àwọn ìtẹ̀jáde Kristẹni. Ọ̀gá náà yan ẹrú náà sípò lórí gbogbo àwọn nǹkan ìní rẹ̀ lọ́dún (a) 1914; (b) 33 Sànmánì Tiwa; (d) 1919.

14. Èwo Nìdáhùn: Ohun tó wà nínú àwọ̀n ìpẹja tí Jésù sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀ nínú àkàwé tó ṣe ní Mátíù 13:47-50 ni ìjọ àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró àti (a) Ìjọba Ọlọ́run ti Mèsáyà náà; (b) àwọn àgùntàn mìíràn alábàákẹ́gbẹ́ wọn; (d) Kirisẹ́ńdọ̀mù.

15. Gẹ́gẹ́ bí ohun tí Jésù sọ nínú àkọsílẹ̀ Mátíù 5:24, kí ló yẹ kó o ṣe bó o bá ṣàkíyèsí pé o ti ṣẹ olùjọsìn ẹlẹgbẹ́ rẹ kan? [g96-YR 2/8 ojú ìwé 26 àti 27]

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́