Àwọn Ìfilọ̀
◼ Ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ tí a ó fi lọni ní oṣù February àti March: Ìmọ̀ Tí Ń Sinni Lọ sí Ìyè Àìnípẹ̀kun. A óò sapá gidigidi láti bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. April àti May: Kí a fi àwọn ẹ̀dà ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́ àti Jí! lọni. Nígbà tá a bá ń ṣe ìpadàbẹ̀wò sọ́dọ̀ àwọn tó fìfẹ́ hàn, bóyá tá a lọ sí ọ̀dọ̀ àwọn tó wá sí Ìṣe Ìrántí tàbí àwọn àpéjọ mìíràn tí a ṣètò rẹ̀ àmọ́ tí wọn kì í dara pọ̀ pẹ̀lú ìjọ déédéé, kí a sapá gan-an láti bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì inú ilé, pàápàá bó bá jẹ́ pé àwọn kan ti ní ìwé Ìmọ̀ àti ìwé pẹlẹbẹ Béèrè lọ́wọ́ tẹ́lẹ̀.
◼ Kí alábòójútó olùṣalága tàbí ẹnì kan tí ó yàn ṣàyẹ̀wò àkáǹtì ìjọ ní March 1, tàbí bó bá ti ṣe lè yá tó lẹ́yìn náà. Bí ẹ bá ti ṣe èyí, ẹ ṣe ìfilọ̀ fún ìjọ lẹ́yìn tí ẹ bá ti ka ìròyìn ìnáwó tó tẹ̀ lé e. Ẹ ka ọ̀rọ̀ ìdúpẹ́ èyíkéyìí látọ̀dọ̀ Society nípa ọrẹ tí ìjọ fi ránṣẹ́ fún iṣẹ́ kárí ayé àti àwọn owó àkànlò èyíkéyìí mìíràn fún ìtìlẹ́yìn ètò àjọ yìí.
◼ Kí akọ̀wé àti alábòójútó iṣẹ́ ìsìn ṣàyẹ̀wò ìgbòkègbodò gbogbo àwọn aṣáájú ọ̀nà déédéé. Bó bá ṣòro fún ẹnikẹ́ni lára wọn láti ní iye wákàtí tí à ń béèrè, kí àwọn alàgbà ṣètò láti ràn án lọ́wọ́. Fún ìdámọ̀ràn, ẹ ṣàtúnyẹ̀wò àwọn lẹ́tà tó ní nọ́ńbà náà, S-201, èyí tí Society máa ń kọ lọ́dọọdún. Ẹ tún wo ìpínrọ̀ 12 sí 20 nínú àkìbọnú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa ti September 1986.
◼ Ẹṣin ọ̀rọ̀ àkànṣe àsọyé fún gbogbo èèyàn fún sáà Ìṣe Ìrántí ti ọdún 2003 ni, “Ǹjẹ́ Wákàtí Ìdájọ́ Bábílónì Ti Dé?” Ẹ wo ìfilọ̀ tó fara jọ èyí nínú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa ti September 2002.