Lẹ́tà Látọ̀dọ̀ Ẹgbẹ́ Olùṣàkóso
Ẹ̀yin Arákùnrin àti Arábìnrin Ọ̀wọ́n:
Inú wa dùn gan-an láti kọ̀wé sí yín! A gbóríyìn fún un yín fún ìfẹ́ àti ẹ̀mí ìfara-ẹni-rúbọ tí ẹ ti ń fi hàn. Ẹ óò rí i nínú ìwé Yearbook ọdún yìí pé ọ̀pọ̀ ohun rere la ṣe lọ́dún iṣẹ́ ìsìn tó kọjá lọ. Lẹ́ẹ̀kan sí i, a tún ti lo ohun tó ju bílíọ̀nù kan wákàtí lọ nínú iṣẹ́ ìwàásù àti ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́ tí à ń ṣe, bí a ti ń tọ àwọn èèyàn lọ ní tààràtà tí a sì ń rọ̀ wọ́n láti sún mọ́ Jèhófà. Ǹjẹ́ kì í ṣe àǹfààní ńlá ló jẹ́ láti jẹ́ alábàáṣiṣẹ́pọ̀ pẹ̀lú Ọlọ́run wa ológo àti Baba wa ọ̀run?—1 Kọ́r. 3:9.
Bá a ti ń wo iṣẹ́ tó ń bẹ níwájú wa, a ní ìdánilójú pé ẹ óò máa bá a lọ ní ṣíṣàfarawé ìtara àti ìgbàgbọ́ àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run tí a sọ nípa wọn nínú Bíbélì. Bí àpẹẹrẹ, àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù máa ń hára gàgà láti ṣe gbogbo ohun tó lè ṣe fún ìtẹ̀síwájú ire Ìjọba náà. Gẹ́gẹ́ bí ẹ̀rí ṣe fi hàn, àárín ọdún tó lò kẹ́yìn ní ìlú Éfésù ló kọ lẹ́tà rẹ̀ àkọ́kọ́ sí ìjọ Kristẹni tó wà ní Kọ́ríńtì. Nígbà tó ń sọ nípa àwọn ohun tó fẹ́ mú ṣe láìpẹ́ jọjọ, ó kọ̀wé pé: “Èmi yóò wà ní Éfésù títí di ìgbà àjọyọ̀ Pẹ́ńtíkọ́sì; nítorí ilẹ̀kùn ńlá tí ń ṣamọ̀nà sí ìgbòkègbodò ni a ti ṣí sílẹ̀ fún mi, ṣùgbọ́n ọ̀pọ̀ alátakò ní ń bẹ.”—1 Kọ́r. 16:8, 9.
Ohun tí Pọ́ọ̀lù wéwèé tẹ́lẹ̀ ni láti rìnrìn àjò lọ sí Makedóníà àti Kọ́ríńtì. Àmọ́, ó rí i pé àǹfààní kan yọjú, ìyẹn ni pé kó dúró díẹ̀ sí i ní ìlú Éfésù láti ṣe ohun tó máa ṣe àwọn èèyàn láǹfààní. Pọ́ọ̀lù jẹ́ ẹni tó mọwọ́ yí padà; ó rí ipò kan tó túbọ̀ máa ṣàǹfààní fún mímú ire Ìjọba náà tẹ̀ síwájú níbi tó wà lákòókò yẹn, ó sì yí ìtòlẹ́sẹẹsẹ rẹ̀ padà láti bá ipò yẹn mu. Ilẹ̀kùn ńlá tí ń ṣamọ̀nà sí ìgbòkègbodò ti ṣí sílẹ̀ fún un, Pọ́ọ̀lù sì ń hára gàgà láti lo àǹfààní tó ní láti gba ẹnu ilẹ̀kùn náà wọlé.
Ṣíṣe bẹ́ẹ̀ túmọ̀ sí pé yóò ṣe ọ̀pọ̀lọpọ̀ iṣẹ́—ìyẹn wíwàásù ìhìn rere náà àti gbígbé ìjọ tó wà ní Éfésù ró. Nígbà tí Pọ́ọ̀lù ń bá àwọn àgbà ọkùnrin tó wà ní ìlú náà sọ̀rọ̀ lẹ́yìn ìgbà yẹn, ó sọ pé: “Èmi kò . . . fà sẹ́yìn kúrò nínú sísọ èyíkéyìí lára àwọn ohun tí ó lérè nínú fún yín tàbí kúrò nínú kíkọ́ yín ní gbangba àti láti ilé dé ilé. Ṣùgbọ́n mo jẹ́rìí kúnnákúnná fún àwọn Júù àti àwọn Gíríìkì nípa ìrònúpìwàdà sí Ọlọ́run àti ìgbàgbọ́ nínú Olúwa wa Jésù.”—Ìṣe 20:20, 21.
Lọ́nà kan náà, ọ̀pọ̀ ẹ̀yin arákùnrin àti arábìnrin ọ̀wọ́n ti lo àwọn àǹfààní tó ṣí sílẹ̀ fún un yín. Nínú ọdún iṣẹ́ ìsìn tó kọjá, ní ìpíndọ́gba, ó ti ṣeé ṣe fún àwọn akéde tí iye wọn jẹ́ ọ̀kẹ́ mọ́kàndínlógójì ó lé ẹgbàásàn-án, ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀rún àti méjìdínlogoji [798, 938] láti ṣètò àwọn ìgbòkègbodò wọn láti lè kópa nínú ẹ̀ka iṣẹ́ aṣáájú ọ̀nà kan tàbí òmíràn. Díẹ̀ lára yín ti rìnrìn àjò lọ sí àwọn ibi tó jìnnà réré lórí ilẹ̀ ayé láti lè sìn gẹ́gẹ́ bíi míṣọ́nnárì. Ẹ̀ ń fi tìtaratìtara tan ìhìn rere náà kálẹ̀, ẹ sì ń gbé àwọn ìjọ ró. Àwọn mìíràn lára yín ti kọ́ èdè mìíràn kẹ́ ẹ bàa lè ran àwọn èèyàn tó ń sọ èdè òkèèrè tí wọ́n ń gbé nítòsí yín lọ́wọ́. Síbẹ̀, àwọn mìíràn lára yín ti tún ètò ṣe láti lè ṣiṣẹ́ ní àwọn ìpínlẹ̀ tí a kò pín fúnni tàbí láti sìn níbi tí àìní gbé pọ̀. Àwọn kan tiẹ̀ ti rí i pé ilẹ̀kùn ńlá tí ń ṣamọ̀nà sí ìgbòkègbodò ti ṣí sílẹ̀ fún wọn ní ilé ẹ̀kọ́, níbi iṣẹ́, tàbí láwọn ọ̀nà mìíràn tí wọ́n ti lè jẹ́rìí fún àwọn èèyàn lọ́nà gbígbéṣẹ́, irú bíi nípa lílo tẹlifóònù. Àwọn ìrírí yíká ayé ti jẹ́rìí sí i pé àwọn èèyàn Ọlọ́run, lọ́mọdé àti lágbà, ń fìtara wá àwọn àǹfààní láti ṣàjọpín ìmọ̀ òtítọ́ náà pẹ̀lú àwọn èèyàn níbi gbogbo, wọ́n sì ń rí àǹfààní wọ̀nyí.
Ẹ ní ìdánilójú pé Jèhófà ń rí àwọn ìsapá yín, èyí sì ń múnú rẹ̀ dùn gan-an. Bíbélì sọ pé: “Ọlọ́run kì í ṣe aláìṣòdodo tí yóò fi gbàgbé iṣẹ́ yín àti ìfẹ́ tí ẹ fi hàn fún orúkọ rẹ̀.” (Héb. 6:10) Ẹ máa bá a nìṣó láti máa wà lójúfò sí àwọn àǹfààní tí yóò jẹ́ kẹ́ ẹ lè gbé ìjọsìn mímọ́ lárugẹ. Àwọn kan lára yín lè mú iṣẹ́ òjíṣẹ́ wọn gbòòrò sí i. Gbogbo wa la sì lè sapá láti mú kí iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa gbéṣẹ́ sí i.
A ò lè ṣe iṣẹ́ ìwàásù tá a gbé lé wa lọ́wọ́ láìrí àtakò. Rántí pé lẹ́yìn tí Pọ́ọ̀lù sọ̀rọ̀ nípa ilẹ̀kùn ńlá tí ń ṣamọ̀nà sí ìgbòkègbodò tó ṣí sílẹ̀ fún un, ó kọ̀wé pé: “Ọ̀pọ̀ alátakò ní ń bẹ.” Lára àwọn tó jẹ́ alátakò Pọ́ọ̀lù làwọn Júù àtàwọn Kèfèrí, àwọn kan tí wọ́n dìídì wá kò ó lójú, àtàwọn mìíràn tí wọ́n ń fi ọgbọ́n ẹ̀wẹ́ gbìmọ̀ ọ̀tẹ̀ sí i lábẹ́lẹ̀.—Ìṣe 19:24-28; 20:18, 19.
Àwa náà dojú kọ irú ipò kan náà lónìí. Bá a ti ń sún mọ́ ìparun ètò àwọn nǹkan búburú yìí, a retí pé àtakò yóò máa pọ̀ sí i. Sátánì ní “ìbínú ńlá,” àwọn tó ń sin Ọlọ́run ló sì dìídì kọjú ìbínú náà sí. (Ìṣí. 12:12) Má ṣe gbàgbé pé Sátánì ni “olùṣàkóso ayé.” Jésù sọ fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ pé: “Bí ẹ̀yin bá jẹ́ apá kan ayé, ayé yóò máa ní ìfẹ́ni fún ohun tí í ṣe tirẹ̀. Wàyí o, nítorí pé ẹ kì í ṣe apá kan ayé, ṣùgbọ́n mo ti yàn yín kúrò nínú ayé, ní tìtorí èyí ni ayé fi kórìíra yín.”—Jòh. 14:30; 15:19.
A ti pinnu lọ́kàn wa láti má ṣe gba ẹnikẹ́ni láyè láti sọ ìgbàgbọ́ wa nínú Ọlọ́run dòkú tàbí sọ wá di aláìṣedéédéé nínú iṣẹ́ ìwàásù wa. A mọ̀ pé kò ní ṣaláì sí àwọn tí yóò máa ta kò wá, tí wọ́n á sì máa gbèrò ibi sí wa. Síbẹ̀, láìka àtakò sí, a óò máa bá a lọ láti máa wàásù ìhìn rere Ìjọba náà, pẹ̀lú ìgbọ́kànlé pé nígbà tí àkókò bá tó lójú Jèhófà, Jésù yóò pa Sátánì àti gbogbo àwọn tó ń tẹ̀ lé e run pátápátá. Kò ṣeé ṣe fún àwọn alátakò láti pa àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù lẹ́nu mọ́; bẹ́ẹ̀ náà ni wọn ò lè pa àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà lẹ́nu mọ́ lónìí. Láìka ìbínú Sátánì àti ìkórìíra ayé sí, ẹ̀mí Jèhófà ń báṣẹ́ lọ láìṣeé dá dúró láàárín àwọn èèyàn Rẹ̀. Ayọ̀ ńláǹlà ló jẹ́ láti mọ̀ pé iye àwa tá à ń polongo ìhìn rere náà tún ti pọ̀ sí i gan-an, a ti di mílíọnú mẹ́fà, ẹgbẹ̀rún mẹ́rìnlélọ́ọ̀ọ́dúnrún, òjìlélẹ́gbẹ̀ta àti márùn-ún [6,304,645]!
Àdúrà wa ni pé kí ẹ lè máa bá a lọ láti lo àwọn àǹfààní tó bá yọjú láti gbé ire Ìjọba ológo Jèhófà ga. Ẹ ní ìdánilójú pé à ń dàníyàn nípa yín lẹ́nì kọ̀ọ̀kan bá a ti ń bá a lọ ní “ìfẹ̀gbẹ́kẹ̀gbẹ́” nínú iṣẹ́ ìsìn Ọlọ́run Gíga Jù Lọ náà, Jèhófà.—Sef. 3:9.
Àwa arákùnrin yín,
Ẹgbẹ́ Olùṣàkóso ti Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà