ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • km 3/03 ojú ìwé 7
  • Àwọn Ìfilọ̀

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Àwọn Ìfilọ̀
  • Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2003
Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2003
km 3/03 ojú ìwé 7

Àwọn Ìfilọ̀

◼ Ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ tí a ó fi lọni ní oṣù March: Ìmọ̀ Tí Ń Sinni Lọ sí Ìyè Àìnípẹ̀kun. A óò sapá gidigidi láti bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. April àti May: Kí a fi àwọn ẹ̀dà ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́ àti Jí! lọni. Nígbà tá a bá ń ṣe ìpadàbẹ̀wò sọ́dọ̀ àwọn tó fìfẹ́ hàn, bóyá tá a lọ sọ́dọ̀ àwọn tó wá sí Ìṣe Ìrántí tàbí àwọn àpéjọ mìíràn tí a ṣètò rẹ̀ àmọ́ tí wọn kì í dara pọ̀ pẹ̀lú ìjọ déédéé, kí a ṣe gbogbo ohun tá a bá lè ṣe láti bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì inú ilé, pàápàá bó bá jẹ́ pé àwọn kan ti ní ìwé Ìmọ̀ àti ìwé pẹlẹbẹ Béèrè lọ́wọ́. June: Kí a fi ìwé Ìmọ̀ àti ìwé pẹlẹbẹ Béèrè lọni. Bí àwọn onílé bá ti ní àwọn ìwé wọ̀nyí lọ́wọ́, lo ìwé pẹlẹbẹ mìíràn tó bá ipò onílé mu tí ìjọ ní lọ́wọ́.

◼ Kí àwọn akéde tí wọ́n fẹ́ láti ṣe iṣẹ́ aṣáájú ọ̀nà olùrànlọ́wọ́ lóṣù April múra sílẹ̀ nísinsìnyí, kí wọ́n sì tètè forúkọ sílẹ̀. Èyí yóò ran àwọn alàgbà lọ́wọ́ láti ṣe àwọn ètò tó yẹ fún iṣẹ́ ìsìn pápá, wọ́n á sì lè ṣètò kí ìjọ ní àwọn ìwé ìròyìn àti ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ mìíràn tí ó pọ̀ tó lọ́wọ́. Lóṣooṣù, kí a máa kéde orúkọ gbogbo àwọn tá a fọwọ́ sí láti ṣe aṣáájú ọ̀nà olùrànlọ́wọ́ fún ìjọ gbọ́.

◼ Àkọlé àkànṣe àsọyé fún gbogbo èèyàn fún sáà Ìṣe Ìrántí ti ọdún 2003 ni “Ǹjẹ́ Wákàtí Ìdájọ́ Bábílónì Ti Dé?” Wo Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa ti oṣù September 2002 fún irú ìfilọ̀ kan náà.

◼ Àwọn Ìtẹ̀jáde Tuntun Tó Wà: Ọ̀nà Tó Lọ sí Ìyè Àìnípẹ̀kun—Ṣé O Ti Rí I?—Ẹ́fíìkì, Faransé, Gẹ̀ẹ́sì, Haúsá, Ìgbò, Ísókó, Tífí, Yorùbá

Sún Mọ́ Jèhófà—Faransé, Gẹ̀ẹ́sì, Haúsá, Ísókó, Yorùbá

Jọ́sìn Ọlọ́run Tòótọ́ Kan Ṣoṣo Náà—Ẹ́fíìkì, Faransé, Gẹ̀ẹ́sì, Haúsá, Ìgbò, Ísókó, Tífí, Yorùbá

Watch Tower Publications Index, 2001—Gẹ̀ẹ́sì

Jọ́sìn Ọlọ́run Tòótọ́ Kan Ṣoṣo Náà—Ìtẹ̀jáde Onílẹ́tà Gàdàgbà—Gẹ̀ẹ́sì

Jehovah’s Witnesses—A Christian Community (Ìwé àṣàrò kúkúrú No. 7072)—Èdè Lárúbáwá

◼ Àwọn Ìtẹ̀jáde Tó Wà Báyìí: Kọrin Ìyìn sí Jehofah—Àwọn Ọ̀rọ̀ Orin Nìkan (Ọgọ́rùn-ún Orin Ló Wà Nínú Rẹ̀)—Ègùn

◼ Kásẹ́ẹ̀tì Àfetígbọ́ Tuntun Tó Wà: A Satisfying Life—How to Attain It—Gẹ̀ẹ́sì

◼ Fídíò Tuntun Tó Wà: Iwe Itan Bibeli Mi—Kásẹ́ẹ̀tì Fídíò, Ìdìpọ̀ 1—Èdè Àwọn Adití ní Ìlànà ti Amẹ́ríkà

Ọkunrin Titobilọla Julọ Ti O Tii Gbé Ayé Rí—Kásẹ́ẹ̀tì Fídíò, Ìdìpọ̀ 8—Èdè Àwọn Adití ní Ìlànà ti Amẹ́ríkà

◼ Àwo Compact Disc Àfetígbọ́ Tuntun Tó Wà: Máa Bọ̀wọ̀ fún Ọlá Àṣẹ Jèhófà—Gẹ̀ẹ́sì

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́