Lo Ìwé Jọ́sìn Ọlọ́run Láti Darí Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì
A ṣètò ìwé Jọ́sìn Ọlọ́run Tòótọ́ Kan Ṣoṣo Náà láti ran àwọn ẹni tuntun lọ́wọ́ kí wọ́n lè tẹ̀ síwájú nínú òtítọ́, kí ìmọrírì tí wọ́n ní fún Jèhófà àti ètò àjọ rẹ̀ sì lè jinlẹ̀ sí i. A lè lò ó gẹ́gẹ́ bí ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ kejì fún àwọn akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa ti June 2000 ṣàlàyé ní ojú ìwé 4 pé: “Bó bá hàn kedere pé ẹnì kan ń tẹ̀ síwájú nípa tẹ̀mí, ṣùgbọ́n tó jẹ́ pé díẹ̀díẹ̀ ni, tí ẹni náà sì ń fi ìmọrírì hàn fún ohun tó ń kẹ́kọ̀ọ́, nígbà náà, ẹ máa bá ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì náà nìṣó nínú ìwé mìíràn lẹ́yìn tí ẹ bá ti parí ìwé pẹlẹbẹ Béèrè àti ìwé Ìmọ̀. . . . Nínú gbogbo ọ̀ràn, ìwé pẹlẹbẹ Béèrè àti ìwé Ìmọ̀ ni a óò kọ́kọ́ kẹ́kọ̀ọ́. Kí o ka iye ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì àti iye ìpadàbẹ̀wò tí o bá ṣe àti àkókò tí o lò, kí o sì ròyìn wọn, kódà bí akẹ́kọ̀ọ́ náà bá ṣe batisí kí ẹ tó parí ìwé kejì.”
Àwọn wo ló tún lè jàǹfààní látinú lílo ìwé Jọ́sìn Ọlọ́run fún ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì? Àpilẹ̀kọ náà ń bá a lọ pé: “Bí o bá mọ àwọn kan tó ti kẹ́kọ̀ọ́ [ìwé pẹlẹbẹ Béèrè àti] ìwé Ìmọ̀ sẹ́yìn, ṣùgbọ́n tí wọn kò tẹ̀ síwájú dórí ìyàsímímọ́ àti batisí, o lè lo ìdánúṣe láti wádìí bóyá wọ́n á fẹ́ láti tún bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì.” Ẹ jẹ́ ká ṣe ìsapá àkànṣe láti lo ìwé Jọ́sìn Ọlọ́run láti fi bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ pẹ̀lú irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ nínú oṣù April àti May.