Ìṣe Ìrántí—Àkókò Tó Gba Ìrònújinlẹ̀
Kété lẹ́yìn tí Jésù fi Oúnjẹ Alẹ́ Oluwa lọ́lẹ̀, àwọn ọ̀tá fi àṣẹ ọba mú un wọ́n sì pa á lẹ́yìn náà. Èyí kì í ṣe àkókò àsè rárá, kàkà bẹ́ẹ̀, àkókò tó gba ìrònújinlẹ̀ gidi ló jẹ́. Kò sí ibì kankan tá a lè rí tọ́ka sí nínú Bíbélì tí wọ́n ti jẹ àsè lẹ́yìn Oúnjẹ Alẹ́ Oluwa tí Jésù Kristi fi lọ́lẹ̀. Àwọn Kristẹni àkọ́kọ́bẹ̀rẹ̀ kò ṣètò irú àsè bẹ́ẹ̀ ṣáájú tàbí lẹ́yìn ayẹyẹ Ìṣe Ìrántí.
Ìṣe Ìrántí kì í ṣe àkókò àpèjẹ. Nípa bẹ́ẹ̀, kò ní bójú mu kí àwọn ìjọ wá máa ṣètò fún síse oúnjẹ tàbí kí àwọn akéde máa ké sí ara wọn láti ṣe fàájì tàbí láti gbọ́ orin. Èyí lè mú kí àwọn ará ìta máa sọ pé “Kérésìmesì àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà” nìyẹn. Èyí lè jẹ́ ohun ìkọ̀sẹ̀. (1 Kọ́r. 8:12, 13; 10:23, 24) Ìṣe Ìrántí kì í ṣe àkókò tí ẹnì kan yóò máa lò láti jẹ “oúnjẹ àkànṣe.” Bí ẹnì kan bá rin kinkin mọ́ pípe àpèjẹ lọ́jọ́ Ìṣe Ìrántí láìbìkítà fún ẹ̀rí ọkàn àwọn ẹlòmíràn, èyí kò ní fi hàn pé irú ẹni bẹ́ẹ̀ ń tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Kristi, ẹni tí “kò ṣe bí ó ti wu ara rẹ̀.” (Róòmù 15:2, 3) Ìṣe Ìrántí tó ń bọlá fún Jèhófà kò gbọ́dọ̀ ní irú àwọn àṣà bẹ́ẹ̀ nínú.
Báwo la ṣe lè lo àkókò Ìṣe Ìrántí láti ronú jinlẹ̀ nípa ìgbésí ayé wa gẹ́gẹ́ bí Kristẹni kan? A lè ṣàṣàrò lórí ohun tá a ti ń fi ìgbésí ayé wa ṣe bọ̀ látẹ̀yìnwá àti ohun tá a fẹ́ fi ṣe lọ́jọ́ iwájú. A lè mú kí ìpinnu wa láti ṣe ìfẹ́ Jèhófà lágbára sí i láìka ohunkóhun tó lè ṣẹlẹ̀ sí. Ní paríparí rẹ̀, a lè ronú jinlẹ̀ lórí ìfẹ́ tí Jèhófà fi hàn sí wa nípa pípèsè ìràpadà náà, bákan náà, a lè ronú jinlẹ̀ lórí ìfẹ́ Jésù, ẹni tó fi tinútinú san owó ìràpadà náà kó lè ṣeé ṣe fún wa láti ní ìrètí. (Jòh. 15:13; Fílí. 2:7, 8) Ẹ ò rí i pé ohun tó ń gbéni ró tó sì ń fúnni níṣìírí ló jẹ́ láti ṣàṣàrò lórí ìpèsè àgbàyanu yìí!—1 Jòhánù 4:11.