ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • km 4/03 ojú ìwé 6
  • Àtúnyẹ̀wò Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Àtúnyẹ̀wò Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run
  • Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2003
Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2003
km 4/03 ojú ìwé 6

Àtúnyẹ̀wò Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run

Àwọn ìbéèrè tó wà nísàlẹ̀ wọ̀nyí la óò gbé yẹ̀ wò nínú àtúnyẹ̀wò aláfẹnusọ ní Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run ní ọ̀sẹ̀ tó bẹ̀rẹ̀ ní April 28, 2003. Alábòójútó ilé ẹ̀kọ́ yóò darí àtúnyẹ̀wò yìí fún ọgbọ̀n ìṣẹ́jú, èyí tá a gbé ka àwọn iṣẹ́ ilé ẹ̀kọ́ tá a ṣe ní ọ̀sẹ̀ March 3 sí ọ̀sẹ̀ April 28, 2003. [Àkíyèsí: Níbi tí a kò bá ti tọ́ka sí ibi tí a ti mú ìdáhùn jáde lẹ́yìn ìbéèrè kan, o ní láti ṣe ìwádìí fúnra rẹ láti wá ìdáhùn sí àwọn ìbéèrè náà.—Wo ìwé Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run, ojú ìwé 36 àti 37.]

ÀNÍMỌ́ Ọ̀RỌ̀ SÍSỌ

1. Kí làwọn ohun tó lè fa kí ọ̀rọ̀ máà yọ̀ mọ́ni lẹ́nu? [be-YR ojú ìwé 93]

2. Bẹ́ẹ̀ ni tàbí Bẹ́ẹ̀ kọ́: Ó yẹ ká yẹra fún dídánudúró, nítorí pé ó lè mú káwọn èèyàn mọ́kàn kúrò lórí ọ̀rọ̀ tí à ń sọ, ó sì lè mú kí wọ́n já lu ọ̀rọ̀ wa. Ṣàlàyé.

3. Báwo ni títẹnumọ́ ọ̀rọ̀ bó ṣe yẹ ṣe ṣe pàtàkì tó fún olùbánisọ̀rọ̀ tàbí ẹnì kan tí ń kàwé sétígbọ̀ọ́ àwùjọ? (Neh. 8:8) [be-YR ojú ìwé 101]

4. Báwo ni a ṣe lè máa tẹnu mọ́ ọ̀rọ̀ bó ṣe yẹ? [be-YR ojú ìwé 102 àti 103]

5. Kí làwọn kókó pàtàkì tó yẹ kó o tẹnu mọ́ nígbà tó o bá ń ka ìwé sókè níbi ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tàbí ní ìpàdé ìjọ? [be-YR ojú ìwé 105]

IṢẸ́ AKẸ́KỌ̀Ọ́ KÌÍNÍ

6. Kí làwọn òbí lè ṣe láti dá àwọn ọmọ wọn lẹ́kọ̀ọ́ “kí wọ́n bàa lè fetí sílẹ̀ àti kí wọ́n bàa lè kẹ́kọ̀ọ́” ní ìpàdé Kristẹni? (Diu. 31:12) [be-YR ojú ìwé 16]

7. Kí ni párádísè tẹ̀mí? [w01-YR 3/1 ojú ìwé 8 sí 10]

8. Báwo ni Òwe 8:1-3 ṣe fi hàn pé ọgbọ́n Ọlọ́run wà lárọ̀ọ́wọ́tó gbogbo èèyàn, àti pé, níbàámu pẹ̀lú Kólósè 2:3, ibo la ti lè rí i? [w01-YR 3/15 ojú ìwé 25 àti 28]

9. Báwo la ṣe lè sọ orúkọ Ọlọ́run di mímọ̀? (Jòh. 17:6) [be-YR ojú ìwé 273 sí 275]

10. Kí làwọn ìsọfúnni pàtàkì tó yẹ káwọn èèyàn mọ̀ nípa “ìhìn rere ìjọba” náà? (Mát. 24:14) [be-YR ojú ìwé 279 àti 280]

BÍBÉLÌ KÍKÀ Ọ̀SỌ̀Ọ̀SẸ̀

11. (a) Ní ọ̀rúndún kìíní, kí ni “ohun ìríra” tí a mẹ́nu kàn nínú Máàkù 13:14? (b) Kí ni dídúró tí ohun náà “dúró níbi tí kò yẹ” ń tọ́ka sí?

12. Báwo ni àkọsílẹ̀ Ìhìn Rere Lúùkù ṣe fẹ̀rí hàn pé Jésù ni ajogún tó lẹ́tọ̀ọ́ sí ìtẹ́ Dáfídì? (Lúùkù 3:23-38) [w92-YR 10/1 ojú ìwé 9 àti 10, ìpínrọ̀ 3]

13. Kí ni ìtumọ̀ ọ̀rọ̀ Jésù tó wà nínú Lúùkù 12:2?

14. Nínú àpèjúwe Jésù nípa ẹyọ owó dírákímà tó sọ nù, kí nìdí tí ìdùnnú àwọn áńgẹ́lì fi gba àfiyèsí? (Lúùkù 15:10) Báwo ló ṣe yẹ kí àpẹẹrẹ wọn nípa lórí wa?

15. Àwọn májẹ̀mú méjì wo ni Lúùkù 22:29 ń tọ́ka sí?

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́