Àwọn Ìfilọ̀
◼ Ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ tí a ó fi lọni ní oṣù April àti May: Kí a fi àwọn ẹ̀dà ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́ àti Jí! lọni. Nígbà tá a bá ń ṣe ìpadàbẹ̀wò sọ́dọ̀ àwọn tó fìfẹ́ hàn, bóyá tá a lọ sọ́dọ̀ àwọn tó wá sí Ìṣe Ìrántí tàbí àwọn àpéjọ mìíràn tí a ṣètò rẹ̀ àmọ́ tí wọn kì í dara pọ̀ pẹ̀lú ìjọ déédéé, kí a ṣe gbogbo ohun tá a bá lè ṣe láti fún wọn ní ìwé Jọ́sìn Ọlọ́run Tòótọ́ Kan Ṣoṣo Náà. Kí a sapá láti bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì inú ilé, pàápàá bó bá jẹ́ pé àwọn kan ti kẹ́kọ̀ọ́ ìwé Ìmọ̀ àti ìwé pẹlẹbẹ Béèrè tẹ́lẹ̀. June: Kí a fi ìwé Ìmọ̀ àti ìwé pẹlẹbẹ Béèrè lọni. Bí àwọn onílé bá ti ní àwọn ìwé wọ̀nyí lọ́wọ́, lo ìwé pẹlẹbẹ mìíràn tó bá ipò onílé mu tí ìjọ ní lọ́wọ́. July àti August: A lè fi èyíkéyìí nínú àwọn ìwé pẹlẹbẹ olójú ewé 32 tó tẹ̀ lé e yìí lọni: Akoso Naa Ti Yoo Mu Paradise Wá, Gbádùn Iwalaaye Lori Ilẹ Ayé Titilae!, Iwọ Ha Nilati Gbàgbọ́ Ninu Mẹtalọkan Bí?, Ki Ni Ète Igbesi-Aye? Bawo Ni Iwọ Ṣe Le Rí I?, Kí Ní Ń Ṣẹlẹ̀ sí Wa Nígbà Tí A Bá Kú?, Nígbà Tí Ẹnìkan Tí Ìwọ Fẹ́ràn Bá Kú?, Orukọ Atọrunwa naa Tí Yoo Wà Titilae, Ọlọrun Ha Bikita Nipa Wa Niti Gidi Bi?, Ọ̀nà Tó Lọ sí Ìyè Àìnípẹ̀kun—Ṣé O Ti Rí I?, àti “Sawo O! Emi Nsọ Ohun Gbogbo Di Ọtun.”
◼ Ó pọn dandan pé kí ẹ̀ka ilé iṣẹ́ wa níbí ní àkọsílẹ̀ tó bágbà mu nípa àdírẹ́sì àti nọ́ńbà tẹlifóònù gbogbo alábòójútó olùṣalága àti akọ̀wé. Bí ìyípadà èyíkéyìí bá wà nígbàkigbà, kí Ìgbìmọ̀ Iṣẹ́ Ìsìn Ìjọ kọ ọ̀rọ̀ sínú fọ́ọ̀mù Presiding Overseer/Secretary Change of Address (S-29), kí wọ́n buwọ́ lù ú, kí wọ́n sì fi ránṣẹ́ sí ẹ̀ka ilé iṣẹ́ lọ́gán. Èyí kan ìyípadà tó bá wà nínú area code (àkànṣe nọ́ńbà tẹlifóònù ti àgbègbè kọ̀ọ̀kan).
◼ Kí àwọn akọ̀wé ìjọ máa rí i pé Ìwé Ìwọṣẹ́ Ìsìn Aṣáájú Ọ̀nà Déédéé (S-205-YR) àti Ìwé Ìwọṣẹ́ Ìsìn Aṣáájú Ọ̀nà Olùrànlọ́wọ́ (S-205b-YR) tí ó pọ̀ tó wà lọ́wọ́. Ẹ lè béèrè fún àwọn fọ́ọ̀mù wọ̀nyí nípa lílo fọ́ọ̀mù Literature Request Form (S-14). Kí ẹ rí i pé èyí tí ìjọ ní lọ́wọ́ yóò tó láti lò fún, ó kéré tán, ọdún kan. Ẹ máa ṣàyẹ̀wò gbogbo fọ́ọ̀mù ìwọṣẹ́ aṣáájú ọ̀nà déédéé láti rí i dájú pé ìsọfúnni inú wọn pé pérépéré. Bí àwọn tó fẹ́ di aṣáájú ọ̀nà kò bá lè rántí déètì náà gan-an tí wọ́n ṣe ìrìbọmi, kí wọ́n fojú díwọ̀n déètì kan kí wọ́n sì ṣàkọsílẹ̀ rẹ̀ síbì kan.
◼ Nígbàkigbà tí o bá ń ṣètò fúnra rẹ láti rìnrìn àjò lọ sí orílẹ̀-èdè mìíràn, tí o sì fẹ́ láti lọ sí ìpàdé ìjọ, àpéjọ àyíká, tàbí àpéjọ àgbègbè níbẹ̀, láti ọ̀dọ̀ ẹ̀ka iléeṣẹ́ tó ń bójú tó iṣẹ́ wa lórílẹ̀-èdè náà ni kó o ti béèrè ìsọfúnni nípa déètì, àkókò àti ibi tí wọ́n á ti ṣe ìpàdé ọ̀hún. Àdírẹ́sì àwọn ẹ̀ka iléeṣẹ́ wà ní ojú ìwé tó kẹ́yìn nínú ìwé Yearbook wa ti lọ́ọ́lọ́ọ́.
◼ Ní May 31, 2003, kò ní sí àyè fún wa láti gbàlejò ní Bẹ́tẹ́lì. Ẹ jọ̀wọ́ ẹ má ṣe wá ṣèbẹ̀wò, bẹ́ẹ̀ ni kí ẹ má ṣe wá gba ìwé lọ́jọ́ náà.
◼ Fídíò Tuntun Tó Wà: Transfusion-Alternative Health Care—Meeting Patient Needs and Rights—Gẹ̀ẹ́sì
◼ Àwọn Ìtẹ̀jáde Tó Wà Báyìí fún Àwọn Afọ́jú: Àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà—Ìmọ́lẹ̀ fún Gbogbo Aráyé, Apá Kejì (ìdìpọ̀ mẹ́rin)—Èdè Gẹ̀ẹ́sì, ìpele kejì