Àwọn Ìfilọ̀
◼ Ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ tí a óò fi lọni ní oṣù May: Kí a fi àwọn ẹ̀dà ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́ àti Jí! lọni. Nígbà tá a bá ń ṣe ìpadàbẹ̀wò sọ́dọ̀ àwọn tó fìfẹ́ hàn, tó lè kan lílọ sọ́dọ̀ àwọn tó wá sí Ìṣe Ìrántí tàbí àwọn àpéjọ mìíràn tí a ṣètò àmọ́ tí wọn kì í dara pọ̀ pẹ̀lú ìjọ déédéé, kí a darí àfiyèsí sórí fífi ìwé Jọ́sìn Ọlọ́run Tòótọ́ Kan Ṣoṣo Náà lọni. Kí a sapá gidigidi láti bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì inú ilé, pàápàá pẹ̀lú àwọn tó bá ti ka ìwé Ìmọ̀ àti ìwé pẹlẹbẹ Béèrè tán. June: Kí a fi ìwé Ìmọ̀ tàbí àwọn ìwé pẹlẹbẹ náà Béèrè tàbí Ọ̀nà Tó Lọ sí Ìyè Àìnípẹ̀kun—Ṣé O Ti Rí I? lọni. Bí àwọn onílé bá ti ní àwọn ìwé wọ̀nyí lọ́wọ́, lo ìwé pẹlẹbẹ mìíràn tó bá ipò onílé mu tí ìjọ ní lọ́wọ́. July àti August: A lè fi èyíkéyìí nínú àwọn ìwé pẹlẹbẹ olójú ewé 32 tó tẹ̀ lé e yìí lọni: Akoso Naa Ti Yoo Mu Paradise Wá, Gbádùn Iwalaaye Lori Ilẹ Ayé Titilae!, Iwọ Ha Nilati Gbàgbọ́ Ninu Mẹtalọkan Bí?, Ki Ni Ète Igbesi-Aye? Bawo Ni Iwọ Ṣe Le Rí I?, Kí Ní Ń Ṣẹlẹ̀ sí Wa Nígbà Tí A Bá Kú?, Nígbà Tí Ẹnìkan Tí Ìwọ Fẹ́ràn Bá Kú?, Orukọ Atọrunwa naa Tí Yoo Wà Titilae, Ọlọrun Ha Bikita Nipa Wa Niti Gidi Bi?, Ọ̀nà Tó Lọ sí Ìyè Àìnípẹ̀kun—Ṣé O Ti Rí I?, àti “Sawo O! Emi Nsọ Ohun Gbogbo Di Ọtun.”
◼ Àwọn déètì tó fara hàn nísàlẹ̀ yìí ni a ti yí padà nínú àwọn déètì fún àpéjọ àyíká àti àpéjọ àkànṣe tí a ó ṣe lọ́dún 2003. Àwọn àyíká mẹ́rin tí a ó ti túmọ̀ gbogbo ìtòlẹ́sẹẹsẹ sí Èdè Àwọn Adití Lọ́nà ti Amẹ́ríkà ni:
Àkúrẹ́ (WE-12) March 1 àti July 26-27, 2003
Badagry (WE-04) May 17 àti October 4-5, 2003
Badagry (WE-23) March 2 àti July 26-27, 2003
Ùbogò (ME-07) June 21 àti October 4-5, 2003
Déètì tí àwọn àyíká yòókù yóò ṣe tiwọn gẹ́gẹ́ bí a ṣe gbé e jáde nínú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa ti January 2003 kò yí padà.
◼ Kí alábòójútó olùṣalága tàbí ẹnì kan tí ó bá yàn ṣàyẹ̀wò àkáǹtì ìjọ ní June 1 tàbí bí ó bá ti lè yá tó lẹ́yìn náà. Bí ẹ bá ti ṣe èyí, ẹ ṣèfilọ̀ rẹ̀ fún ìjọ lẹ́yìn tí ẹ bá ti ka ìròyìn ìnáwó ti oṣù tó ń bọ̀.
◼ Kásẹ́ẹ̀tì Àtẹ́tísí Tuntun Tó Wà: A Satisfying Life—How to Attain It—Gẹ̀ẹ́sì
◼ Kásẹ́ẹ̀tì Fídíò Tuntun Tó Wà: Warning Examples for Our Day—Gẹ̀ẹ́sì
◼ Ìtẹ̀jáde Tuntun Tó Wà: Sún Mọ́ Jèhófà—Ẹ́fíìkì