Ọ̀nà Tó Lọ sí Ìyè Àìnípẹ̀kun—Ṣé O Ti Rí I?
1 Èyí ní àkọlé ìwé pẹlẹbẹ tuntun tí a mú jáde ní Àpéjọ Àgbègbè wa ti “Àwọn Olùfi Ìtara Pòkìkí Ìjọba Ọlọ́run” tá a ṣe lẹ́nu àìpẹ́ yìí. Ẹ jẹ́ ká dojúlùmọ̀ irinṣẹ́ tuntun tó dára gan-an tó sì gbéṣẹ́ yìí, tí a dìídì ṣe fáwọn ará ilẹ̀ Áfíríkà. O lè lò ó fún ìkẹ́kọ̀ọ́ ìdílé rẹ tàbí kó o fi ṣèkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì pẹ̀lú àwọn ẹlòmíràn. Láìsí àní-àní, ìwé yìí yóò wà lára àwọn irinṣẹ́ tí a óò máa lò láti bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì pẹ̀lú àwọn èèyàn! Ǹjẹ́ o ti fara balẹ̀ kà á? Jọ̀wọ́ ṣe bẹ́ẹ̀.
2 Kíyè sí ohun tí gbólóhùn méjì tó ṣáájú nínú Ẹ̀kọ́ 1 sọ, ó ní: “Ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ pé gbogbo èèyàn tó wà nílẹ̀ Áfíríkà ló gbà pé ó ṣe pàtàkì láti sin Ọlọ́run. Ṣùgbọ́n, ẹnu àwọn èèyàn ò fi bẹ́ẹ̀ kò lórí bó ṣe yẹ ká máa sìn ín.” Kedere ló ṣàlàyé àwọn ẹ̀sìn àbáláyé tó wà nílẹ̀ Áfíríkà àti ẹ̀rù àwọn ẹlẹ́mìí òkùnkùn tó sábà máa ń ba àwọn èèyàn. Á ran olúkúlùkù àwọn èèyàn lọ́wọ́ láti mọ bí wọ́n á ṣe yan ìsìn tòótọ́ níwọ̀n bó ti jẹ́ pé oríṣiríṣi ẹ̀sìn tó wà ò jẹ́ kí wọ́n mọ èyí táwọn ì bá yàn, àgàgà lójú àwọn ẹ̀sìn tí wọ́n ń dá sílẹ̀ lójoojúmọ́. Ìwé náà ní ọ̀pọ̀ àwòrán mèremère àtàwọn àpèjúwe tó rọrùn láti lóye. Ó ní ìsọfúnni tó ń wọni lọ́kàn gan-an fáwọn ará ilẹ̀ Áfíríkà! Gbé díẹ̀ lára àwọn kókó ẹ̀kọ́ inú ìwé pẹlẹbẹ tuntun náà yẹ̀ wò:
● Ẹ̀kọ́ 3 sọ ní kedere irú ẹni tí Jèhófà, Jésù àtàwọn áńgẹ́lì jẹ́, ó fi ibi tí Sátánì àtàwọn ẹ̀mí èṣù rẹ̀ ti wá hàn, ó sì tún sọ bí wọ́n ṣe “ń ṣi gbogbo ilẹ̀ ayé tí a ń gbé pátá lọ́nà.”—Ìṣí. 12:9.
● Ẹ̀kọ́ 4 sọ̀rọ̀ nípa ìjọsìn àwọn baba ńlá àtàwọn àṣà tó so mọ́ ọn, ó tún sọ ìdí táwọn ará ilẹ̀ Áfíríkà fi nígbàgbọ́ nínú ẹ̀sìn yìí àti ìdí tí ìjọsìn yìí kò fi lérè kankan nínú bí kò ṣe ewu ńláńlá. Lọ́nà tó rọrùn, ó ṣàlàyé ìdí tí ọkàn tàbí ẹ̀mí kì í fi í wà láàyè nìṣó lẹ́yìn tí ara bá kú.
● Ẹ̀kọ́ 5 tó ní àkòrí náà “Àṣírí Iṣẹ́ Òkùnkùn” jẹ́ ká mọ̀ bí irú àwọn ìgbàgbọ́ wọ̀nyí ṣe fìdí múlẹ̀ tó nínú àṣà àwọn ará ilẹ̀ Áfíríkà. Ìpínrọ̀ 4 sọ pé: “Àwọn èèyàn gbà gbọ́ pé àwọn àjẹ́ máa ń bọ́ agọ̀ ara wọn sílẹ̀ ní òru, tí wọ́n á sì fò lọ bóyá láti lọ bá àwọn àjẹ́ mìíràn ṣèpàdé tàbí láti lọ pín ẹran ara èèyàn tó ṣì wà láàyè jẹ kí onítọ̀hún tó wá kú níkẹyìn.” Báwo lá ṣe lè jẹ́ káwọn èèyàn mọ̀ pé irọ́ ńlá gbáà lèyí? Ìpínrọ̀ 10 sí 12 dáhùn ìbéèrè yìí. Ìpínrọ̀ 7 fi hàn bí Sátánì ṣe ń tan àwọn èèyàn kí wọn lè rò pé agbára òun pọ̀ ju ibi tí agbára òun mọ. Ìpínrọ̀ 15 sí 17 fi hàn pé Jèhófà lágbára ju àwọn ẹ̀mí èṣù lọ fíìfíì, torí pé òun ní Olódùmarè. Ìpínrọ̀ 7 àti 8 jádìí irọ́ ohun táwọn èèyàn gbà gbọ́ pé láburú kì í ṣàdédé ṣẹlẹ̀ tàbí pé kò sẹ́ni tó máa dédé kú láìjẹ́ pé agbára ẹ̀mí àìrí kan ló fà á.
● Ẹ̀kọ́ 6 sí 9 ran àwọn èèyàn lọ́wọ́ láti rí i ní kedere bí wọ́n ṣe lè dá ìsìn tòótọ́ mọ̀ láàárín gbogbo ìsìn èké. Ẹ̀kọ́ 7 ní ìpínrọ̀ 9 sí 11 fi hàn pé agbára táwọn oníṣẹ́ òkùnkùn ń lò làwọn ẹlẹ́sìn ilẹ̀ Áfíríkà ń lò tí wọ́n wá ń sọ pé àwọn lè ṣe àwọn iṣẹ́ ìyanu, èyí táwọn èèyàn sì nífẹ̀ẹ́ láti gbà gbọ́. Ẹ̀kọ́ 8 fún àwọn èèyàn níṣìírí pé kí wọn dára pọ̀ mọ́ ìsìn tòótọ́.
3 Ṣé o ò gbà pé ìwé pẹlẹbẹ tuntun yìí yóò jẹ́ irin iṣẹ́ alágbára láti lò nínú iṣẹ́ ìwàásù ilé-dé-ilé, ìpadàbẹ̀wò àti ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì? O lè ronú pé á dára ká fi ìwé yìí ṣèkẹ́kọ̀ọ́ pẹ̀lú àwọn tó fẹ́ ṣe ìrìbọmi. Èyí lè ṣàǹfààní àmọ́ kò pọn dandan. Á tún wúlò láwọn ọ̀nà mìíràn pẹ̀lú. Nítorí àwọn ẹgbẹ́ òkùnkùn tó gba ilé ẹ̀kọ́ kan lórílẹ̀ èdè yìí, á bọ́gbọ́n mu pé káwọn òbí fara balẹ̀ ṣèkẹ́kọ̀ọ́ pẹ̀lú àwọn ọmọ wọn látinú ìwé yìí. Á dáàbò bò wọ́n kúrò lọ́wọ́ àwọn tó fẹ́ kí wọn lọ́wọ́ nínú iṣẹ́ òkùnkùn nípa gbígbé e lárugẹ bí nǹkan tó lè dáàbò bò wọ́n tó sì lè jẹ́ kí wọn gbégbá orókè nínú ìdánwò ilé ẹ̀kọ́. A lè lò ó láti ṣèkẹ́kọ̀ọ́ pẹ̀lú àwọn tó ń bẹ̀rù àwọn ẹlẹ́mìí òkùnkùn tàbí àwọn tó ń bẹ̀rù pé ẹnì kan ló “fa” àìsàn tó ń ṣe wọ́n. Ìwé yìí wà lára ìwé tí a ó fi lọni ní oṣù June. Ẹ máa bá a nìṣó láti lò ó ní kíkún!