Àwọn Ìfilọ̀
◼ Ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ tí a óò fi lọni ní oṣù September: Sún Mọ́ Jèhófà. Bí kò bá sí lọ́wọ́, ẹ lè lo ìwé Kíyè sí Àsọtẹ́lẹ̀ Dáníẹ́lì! tàbí Iwọ Le Walaaye Titilae ninu Paradise lori Ilẹ Aye, gẹ́gẹ́ bí àfidípò. October: Ilé Ìṣọ́ àti Jí! Níbi tí wọ́n bá ti fìfẹ́ hàn, kí a fi ìwé pẹlẹbẹ Béèrè lọni, kí a sì sapá gidigidi láti bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. November: Ọ̀nà Tó Lọ sí Ìyè Àìnípẹ̀kun—Ṣé O Ti Rí I? December: Ọkunrin Titobilọla Julọ Ti O Tii Gbé Ayé Rí. Gẹ́gẹ́ bí àfidípò, kí a lo Iwe Itan Bibeli Mi tàbí Iwọ Le Walaaye Titilae ninu Paradise lori Ilẹ Aye.
◼ Ẹ̀ka ọ́fíìsì wa níbí kì í fi ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ ránṣẹ́ sí akéde kọ̀ọ̀kan. Kí alábòójútó olùṣalága ṣètò kí a máa ṣèfilọ̀ lóṣooṣù kí a tó fi fọ́ọ̀mù tí a fi ń béèrè fún ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ tí ìjọ nílò fún oṣù kọ̀ọ̀kan ránṣẹ́ sí ẹ̀ka ọ́fíìsì, kí olúkúlùkù ẹni tó bá fẹ́ láti gba ìwé tirẹ̀ lè sọ fún arákùnrin tí ń bójú tó ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́. Ẹ jọ̀wọ́, ẹ rántí pé àwọn ìtẹ̀jáde kan wà tí kíkọ̀wé béèrè fún wọn jẹ́ àkànṣe.
◼ À ń rán àwọn alàgbà létí láti ṣiṣẹ́ lórí àwọn ìtọ́ni tó wà nínú Ilé-ìṣọ́nà ti April 15, 1991, ojú ìwé 21 sí 23, tó sọ̀rọ̀ nípa àwọn tí a yọ lẹ́gbẹ́ tàbí tí wọ́n yọ ara wọn lẹ́gbẹ́, tí wọ́n lè fẹ́ kí a gba àwọn padà.
◼ A óò sọ àkànṣe àsọyé fún gbogbo èèyàn fún sáà Ìṣe Ìrántí ti ọdún 2004 ní ọjọ́ Sunday, April 18. A óò ṣèfilọ̀ àkòrí àsọyé náà nígbà tó bá yá. Kí àwọn ìjọ tí wọ́n bá ní ìbẹ̀wò alábòójútó àyíká, àpéjọ àyíká, tàbí àpéjọ àkànṣe ní òpin ọ̀sẹ̀ yẹn sọ àkànṣe àsọyé yìí ní ọ̀sẹ̀ tó tẹ̀ lé e. Kí ìjọ kankan má ṣe sọ àkànṣe àsọyé yìí ṣáájú April 18, 2004.
[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 7]
Ẹ jọ̀wọ́, a fẹ́ kẹ́ ẹ mọ̀ pé agogo mẹ́sàn án kọjá ogún ìṣẹ́jú òwúrọ̀ lọ́jọ́ Friday ni Àpéjọ Àgbègbè “Ẹ Fi Ògo fún Ọlọ́run” yóò bẹ̀rẹ̀, nígbà tí ìtòlẹ́sẹẹsẹ ti àpéjọ àgbáyé yóò bẹ̀rẹ̀ lọ́jọ́ Thursday ní agogo kan kọjá ogún ìṣẹ́jú ọ̀sán.