Àwọn Ìfilọ̀
◼ Ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ tí a ó fi lọni ní oṣù December: Ọkunrin Titobilọla Julọ Ti O Tii Gbé Ayé Rí. Bí kò bá sí, a lè lo Iwe Itan Bibeli Mi tàbí ìwé Iwọ Le Walaaye Titilae ninu Paradise lori Ilẹ Aye gẹ́gẹ́ bí àfidípò. January: Ìwé èyíkéyìí tí a ti tẹ̀ jáde ṣáájú ọdún 1988 tí ìjọ bá ní lọ́wọ́. Bí ìjọ yín ò bá ní èyíkéyìí lára ìwọ̀nyí lọ́wọ́, ẹ béèrè lọ́wọ́ àwọn ìjọ tó wà nítòsí yín bí wọ́n bá ní ọ̀pọ̀ àwọn ìwé ọlọ́jọ́ pípẹ́ tẹ́ ẹ lè lò. Àwọn ìjọ tí kò bá ní àwọn ìwé ọlọ́jọ́ pípẹ́ lè fi ìwé Mankind’s Search for God lọni. February: Ìwé Sún Mọ́ Jèhófà. Bí kò bá sí lọ́wọ́, a lè lo ìwé Ìṣípayá—Òtéńté Rẹ̀ Títóbi Lọ́lá Kù Sí Dẹ̀dẹ̀! gẹ́gẹ́ bí àfidípò. March: Ìmọ̀ Tí Ń Sinni Lọ sí Ìyè Àìnípẹ̀kun. A ó sapá lákànṣe láti bẹ̀rẹ̀ àwọn ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì inú ilé. Bí àwọn onílé bá ti ní ìwé yìí, a lè fi ìwé Kíyè sí Àsọtẹ́lẹ̀ Dáníẹ́lì! lọ̀ wọ́n.
◼ Gẹ́gẹ́ bí ìránnilétí fún àwọn arákùnrin tí ń bójú tó ọ̀ràn ìnáwó ìjọ, kí a máa fi àwọn ọrẹ tí a bá fi sínú àwọn àpótí tó wà fún Iṣẹ́ Kárí Ayé àti fún Owó Àkànlò fún Gbọ̀ngàn Ìjọba ránṣẹ́ lóṣooṣù, kí a má ṣe lò wọ́n fún sísan owó tí a yá láti kọ́ Gbọ̀ngàn Ìjọba tàbí fún àwọn ìnáwó mìíràn tó jẹ́ ti ìjọ.
◼ Bẹ̀rẹ̀ láti ọ̀sẹ̀ March 15, 2004 títí di ọ̀sẹ̀ May 16, 2005, a óò kẹ́kọ̀ọ́ ìwé náà, Sún Mọ́ Jèhófà, ní Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ìwé Ìjọ.