ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • km 2/04 ojú ìwé 4
  • Lẹ́tà Látọ̀dọ̀ Egbẹ́ Olùṣàkóso

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Lẹ́tà Látọ̀dọ̀ Egbẹ́ Olùṣàkóso
  • Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2004
Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2004
km 2/04 ojú ìwé 4

Lẹ́tà Látọ̀dọ̀ Egbẹ́ Olùṣàkóso

Ẹ̀yin Ará Ọ̀wọ́n:

“KÍ Ẹ ní inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí àti àlàáfíà láti ọ̀dọ̀ Baba wa Ọlọ́run àti Jésù Kristi Olúwa.” (1 Kọ́r. 1:3) Ńṣe ló ń ṣe wá bíi pé kí àkókò náà ti dé tí gbogbo ohun eléèémí yóò máa yin Jèhófà ẹni tí ìyìn yẹ lógo! (Sm. 150:6) Bá a ṣe ń retí kí ọjọ́ ńlá náà dé, a ò dáwọ́ iṣẹ́ pípolongo ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run àti sísọ àwọn èèyàn di ọmọ ẹ̀yìn dúró.

Iṣẹ́ ìjíhìnrere niṣẹ́ tó gbapò iwájú lára àwọn iṣẹ́ Jèhófà lórí ilẹ̀ ayé ní lọ́wọ́lọ́wọ́. (Máàkù 13:10) Níwọ̀n bí a ti mọ̀ pé Jèhófà nífẹ̀ẹ́ sí iṣẹ́ yìí, à ń gbàdúrà pé kó ràn wá lọ́wọ́ lẹ́nu iṣẹ́ náà, torí a mọ̀ pé gbogbo èèyàn ló lè jàǹfààní nínú ìràpadà tó pèsè. (Ìṣí. 14:6, 7, 14, 15) Òótọ́ ni pé à ń bá ìṣòro pàdé, àmọ́ a mà dúpẹ́ o pé a ti “di ẹni tí a gbé agbára wọ̀ láti ibi gíga lókè” láti ṣe iṣẹ́ òjíṣẹ́ náà parí!—Lúùkù 24:49.

Ó dùn mọ́ wa bá a ṣe gbé àwọn ohun tó wáyé lọ́dún iṣẹ́ ìsìn tó kọjá yẹ̀ wò, tá a sì ronú lórí àwọn nǹkan tí Jèhófà tipa àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ adúróṣinṣin gbé ṣe. Agbára tí ẹ̀mí mímọ́ fún àwọn èèyàn Ọlọ́run mú kí wọ́n máa fi irú ìfẹ́ tí Kristi ní hàn, kí wọ́n sì ṣẹ́pá ẹ̀mí ìkórìíra jákèjádò ayé. Irú ìfẹ́ yìí hàn gbangba láwọn àpéjọ wa. Láàárín oṣù June sí December 2003, àwọn aṣojú láti àwọn orílẹ̀-èdè tó lé ní ọgọ́rùn-ún lọ sí àpéjọ àgbáyé méjìlélọ́gbọ̀n ní ibi mẹ́fà ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ lágbàáyé. Ní àwọn àpéjọ àgbègbè àti ti àgbáyé, a fi ọ̀rọ̀ wá ọ̀rọ̀ wò lẹ́nu àwọn míṣọ́nnárì, àwọn òṣìṣẹ́ káyé àtàwọn tó ń sìn ní Bẹ́tẹ́lì nílẹ̀ òkèèrè.

A gba ìwé Wo “Ilẹ̀ Dáradára” Náà àti ìwé Kẹ́kọ̀ọ́ Lọ́dọ̀ Olùkọ́ Ńlá Náà láwọn àpéjọ yìí. Kò tán síbẹ̀ o, wọ́n ṣe ìfilọ̀ pé a ó bẹ̀rẹ̀ sí lo àtúnṣe ìwé Ilé Ẹ̀kọ́ Àwọn Aṣáájú Ọ̀nà lápá ìparí ọdún iṣẹ́ ìsìn 2004. Bọ́jọ́ ti ń gorí ọjọ́, a ó máa pe àwọn aṣáájú ọ̀nà tí wọ́n ti pẹ́ lẹ́nu iṣẹ́ tí wọ́n sì ti lọ sí ilé ẹ̀kọ́ náà rí pé kí wọ́n tún bá àwọn tó ṣẹ̀sẹ̀ di aṣáájú ọ̀nà lọ lẹ́ẹ̀kan sí i.

Ìtìlẹyìn Ọlọ́run àti ẹ̀mí ọ̀làwọ́ àwọn èèyàn mú kó ṣeé ṣe láti kọ́ ọ̀pọ̀ Gbọ̀ngàn Ìjọba sí i, pàápàá láwọn orílẹ̀-èdè tí wọn ò ti fi bẹ́ẹ̀ rí towó ṣe. Nítorí àwọn èèyàn tó túbọ̀ ń fẹ́ oúnjẹ tẹ̀mí sí i jákèjádò ayé, iṣẹ́ mímú kí ẹ̀ka iléeṣẹ́ ní ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè tóbi ju ti tẹ́lẹ̀ lọ ti ń lọ lọ́wọ́. Ìwé pẹlẹbẹ Gbádùn Iwalaaye lori Ilẹ Ayé Titilae! ti wà ní èdè mọ́kàndínlọ́ọ̀ọ́dúnrún [299] báyìí, tí àpapọ̀ iye ẹ̀dà tá a ti tẹ̀ jáde sì jẹ́ mílíọ̀nù mọ́kàndínlógóje [139,000,000]; iye ẹ̀dà ìwé Ìmọ̀ Tí Ń Sinni Lọ sí Ìyè Àìnípẹ̀kun tá a ti tẹ̀ jáde jẹ́ mílíọ̀nù mẹ́tàléláàádọ́rùn-ún [93,000,000] ní èdè mọ́kànlélọ́gọ́jọ [161]; a sì ti tẹ igba [200] mílíọ̀nù ìwé pẹlẹbẹ Kí Ni Ọlọrun Ń Béèrè Lọ́wọ́ Wa? sí èdè igba ó lé mẹ́tàdínláàádọ́rin [267].

A kí ẹgbàá mọ́kàndínláàádóje ó lé ẹgbẹ̀rin àti márùn-ún lélógójì [258,845] èèyàn tí wọ́n fi ìyàsímímọ́ wọn hàn nípa ṣíṣe ìrìbọmi ní ọdún iṣẹ́ ìsìn tó kọjá tọ̀yàyàtọ̀yàyà káàbọ̀ o! Bó tilẹ̀ jẹ́ pé títì tẹ́ ẹ̀ ń ti Ìjọba Ọlọ́run lẹ́yìn ti sọ yín dẹni tí Sátánì dìídì kórìíra, èyí pẹ̀lú ti mú kẹ́ ẹ dẹni tó ń rí ìbùkún gbà lọ́dọ̀ Jèhófà àti ẹni tó ní ààbò tẹ̀mí bẹ́ ẹ ṣe ń sá eré tá a gbé ka iwájú yín. (Héb. 12:1, 2; Ìṣí. 12:17) Bẹ́ẹ̀ ni o, kí ó dá yín lójú pé “kò ṣeé ṣe kí Ẹni tí ń ṣọ́ [yín] tòògbé.”—Sm. 121:3.

Ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tó bọ́ sákòókò gan-an ni ẹṣin ọdún 2004, ó sọ pé, “Ẹ máa bá a nìṣó ní ṣíṣọ́nà . . . Ẹ wà ní ìmúratán.” (Mát. 24:42, 44) Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sọ pé olùgbé fún ìgbà díẹ̀ làwọn Kristẹni jẹ́ nínú ètò àwọn nǹkan tó ń kú lọ yìí. (1 Pét. 2:11; 4:7) Ìdí nìyí tó fi yẹ ká máa pọkàn pọ̀ sórí àwọn nǹkan tẹ̀mí, ká má máa fi àwọn nǹkan tí kò pọn dandan dí ara wa lọ́wọ́, ká sì máa ṣe àyẹ̀wò ọkàn wa dáadáa. Ńṣe ni “dírágónì ńlá náà” fẹ́ pa wá jẹ, ó fẹ́ sọ wá dara ètò àwọn nǹkan tirẹ̀.—Ìṣí. 12:9.

Ohun pàtàkì kan tó máa ràn wá lọ́wọ́ láti lè wà lójúfò ni Bíbélì kíkà ojoojúmọ́. Ó lè ràn wá lọ́wọ́ láti jẹ́ ‘kí Bẹ́ẹ̀ ni wa túmọ̀ sí Bẹ́ẹ̀ ni’ ní ti ìyàsímímọ́ wa, ká sì “di ìgbọ́kànlé tí a ní ní ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀ mú ṣinṣin . . . títí dé òpin.” (Ják. 5:12; Héb. 3:14) Bíbélì kíkà ojoojúmọ́ lè ràn wá lọ́wọ́ láti má ṣe gbàgbé pé àwọn èèyàn nínú ayé kì í tẹ̀ lé àwọn ìlànà Ọlọ́run tí kì í yí padà. (Mál. 3:6; 2 Tím. 3:1, 13) Ìmọ̀ Bíbélì lè ràn wá lọ́wọ́ láti kọ “àwọn ìtàn èké àdọ́gbọ́nhùmọ̀” sílẹ̀ àti láti máa jẹ́ olóòótọ́ sí Jèhófà nìṣó.—2 Pét. 1:16; 3:11.

Bí ẹ̀yin òbí ṣe ń tọ́ àwọn ọmọ yín nínú ìbáwí àti ìlànà èrò orí Jèhófà, ǹjẹ́ ẹ̀ ń ràn wọ́n lọ́wọ́ kí wọ́n lè ní góńgó tẹ̀mí tí wọ́n ń lépa, kí wọ́n sì “máa bá a nìṣó ní ṣíṣọ́nà”? (Éfé. 6:4) Ṣé ẹ̀ ń kọ́ wọn ní bí wọ́n á ṣe máa wo ọjọ́ ọ̀la wọn bí ẹni tó jẹ́ ọlọ́gbọ́n jù lọ nínú gbogbo ẹni tó ti ń gbé láyé ti ṣe? Kì bá sí ẹlẹgbẹ́ Jésù nídìí iṣẹ́ káfíńtà, nídìí ìhùmọ̀ nǹkan tàbí ti ìmọ̀ ìṣègùn ká ní àwọn iṣẹ́ tó yàn láàyò nìyẹn, kàkà bẹ́ẹ̀ iṣẹ́ ìsìn alákòókò kíkún ló yàn láàyò. Ǹjẹ́ kí àpẹẹrẹ rẹ̀ mú kẹ́ ẹ lè máa ran àwọn ọmọ yín lọ́wọ́ láti fi ire Ìjọba Ọlọ́run sípò àkọ́kọ́ nínú ìgbésí ayé wọn.

Ẹgbẹ́ ẹrú olóòótọ́, tí Ẹgbẹ́ Olùṣàkóso ń ṣojú fún, ń dúpẹ́ gidigidi lọ́wọ́ “ogunlọ́gọ̀ ńlá” náà fún ríràn tí wọ́n ń ràn wá lọ́wọ́ láti ṣe ojúṣe wa, ìyẹn rírí i pé à ń ‘wàásù ìhìn rere ìjọba yìí ní gbogbo ilẹ̀ ayé tí a ń gbé, láti ṣe ẹ̀rí.’ (Ìṣí. 7:9; Mát. 24:14, 45) Kí ó dá ẹ̀yin ará ọ̀wọ́n lójú pé Jèhófà ò gbàgbé “iṣẹ́ yín àti ìfẹ́ tí ẹ fi hàn fún orúkọ rẹ̀, ní ti pé ẹ ti ṣe ìránṣẹ́ fún àwọn ẹni mímọ́, ẹ sì ń bá a lọ ní ṣíṣe ìránṣẹ́.” (Héb. 6:10) Bẹ́ ẹ ṣe ń ka àwọn ìrírí alárinrin tó wà nínú ìwé ọdọọdún náà 2004 Yearbook of Jehovah’s Witnesses, tẹ́ ẹ sì kíyè sí ohun tó jẹ́ àbájáde ipa tẹ́ ẹ jíjọ sà, kẹ́ ẹ mọ̀ pé ipa pàtàkì lẹ kó nínú iṣẹ́ ìwàásù tá à ń ṣe kárí ayé yìí.

Ǹjẹ́ kí ẹ ní ìbàlẹ̀ ọkàn nípa ọjọ́ ọ̀la bẹ́ ẹ ṣe ń bá a nìṣó láti máa “tẹjú mọ́ sísan ẹ̀san náà,” kẹ́ ẹ má sì jẹ́ kí ẹnikẹ́ni tàbí ẹ̀mí èṣù èyíkéyìí gbà á kúrò lọ́wọ́ yín. (Héb. 11:26; Kól. 2:18) Bẹ́ẹ̀ ni o, ẹ gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà, kẹ́ ẹ ní ìdánilójú pé yóò ran gbogbo àwọn tó nífẹ̀ẹ́ rẹ̀ lọ́wọ́ kí ọwọ́ wọn lè tẹ ìgbé ayé tó dùn dé ẹ̀kún rẹ́rẹ́.—Jòh. 6:48-54.

Kí ó dá yín lójú pé à ń láyọ̀ láti máa bá a yín sìn pa pọ̀ fún ògo Jèhófà.

Àwa arákùnrin yín.

Ẹgbẹ́ Olùṣàkóso ti Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́