Ètò Kíkọ́ Gbọ̀ngàn Ìjọba Ń Tẹ̀ Síwájú ní Nàìjíríà
1. Iṣẹ́ wo lóde òní la lè fi wé ohun tí wọ́n ṣe nígbà ayé Hágáì?
1 “‘Ẹ . . . jẹ́ alágbára, gbogbo ẹ̀yin ènìyàn ilẹ̀ náà,’ ni àsọjáde Jèhófà, ‘kí ẹ sì ṣiṣẹ́. Nítorí mo wà pẹ̀lú yín,’ ni àsọjáde Jèhófà àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun.” (Hág. 2:4) Ọ̀rọ̀ afúnnilókun yìí fún orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì níṣìírí nígbà tí wọ́n ń kọ́ tẹ́ńpìlì wọn lẹ́yìn tí wọ́n dé láti ìgbèkùn nílẹ̀ Bábílónì. Wọ́n ní iṣẹ́ ìkọ́lé ńlá kan láti ṣe, èyí tí ì bá má ṣeé ṣe fún wọn láti ṣe yọrí ká ní Jèhófà ò tì wọ́n lẹ́yìn. Bákan náà lónìí, a ní iṣẹ́ ńlá kan láti ṣe, ìyẹn ni kíkọ́ ọ̀pọ̀ Gbọ̀ngàn Ìjọba lábẹ́ ìtọ́sọ́nà Jèhófà.
2. Kí ló fi hàn pé ètò kíkọ́ Gbọ̀ngàn Ìjọba ń tẹ̀ síwájú ní Nàìjíríà?
2 Ó ti pé ọdún mẹ́rin báyìí tá a ti bẹ̀rẹ̀ ètò tuntun kan, ìyẹn ni lílo Ẹgbẹ́ Àwọn Tí Ń Kọ́ Gbọ̀ngàn Ìjọba láti máa kọ́ Gbọ̀ngàn Ìjọba. Ǹjẹ́ ìtẹ̀síwájú tiẹ̀ ti bá ètò yìí látìgbà tá a ti bẹ̀rẹ̀? A lè fi tọkàntọkàn dáhùn pé BẸ́Ẹ̀ NI! Látìgbà tí àkọ́kọ́ nínú Ẹgbẹ́ Àwọn Tí Ń Kọ́ Gbọ̀ngàn Ìjọba ti bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ ní ìbẹ̀rẹ̀ ọdún iṣẹ́ ìsìn 2000, Gbọ̀ngàn Ìjọba tó lé ní ẹgbẹ̀ta la ti kọ́ parí. Ìyìn ńláǹlà lèyí mà jẹ́ o sí Jèhófà!—Wo àtẹ ìsọfúnni tó wà lójú ewé yìí.
3. Báwo ni ètò ìkọ́lé yìí ṣe nípa lórí àwọn kan? (Fi àlàyé kún un látinú àpótí náà, “Ọ̀rọ̀ Ìmọrírì Tí Àwọn Ará Sọ Nípa Ètò Kíkọ́ Gbọ̀ngàn Ìjọba ní Nàìjíríà.”)
3 Àwọn èèyàn ń kíyè sí iṣẹ́ bàǹtà-banta yìí. Ẹnì kan tí kì í ṣe Ẹlẹ́rìí ní Ìpínlẹ̀ Ebonyi kọ̀wé pé: “Mo kan sáárá sí ìjọ yín jákèjádò orílẹ̀-èdè yìí àti jákèjádò ayé fún kíkọ́ tẹ́ ẹ kọ́ irú ilé tó jojú ní gbèsè bẹ́ẹ̀ sí abúlé wa. [Èyí] fi hàn pé ìsìn yín kì í ṣe ojúsàájú sí ẹ̀yà èyíkéyìí tàbí kí wọ́n torí ipò tí àwọn èèyàn wà láwùjọ ṣojúsàájú.” Ẹnì kan tó jẹ́ alábòójútó ilé kíkọ́ nílùú Èkó sọ pé: “A mọyì àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà gan-an nítorí pé wọ́n máa ń gbìyànjú láti rí i pé ìjọba fọwọ́ sí àwọn ilé tí wọ́n ń kọ́ nípa gbígba ìwé àṣẹ ìkọ́lé . . . Ó fi hàn pé wọ́n máa ń ṣe nǹkan tọkàntọkàn, wọ́n sì máa ń pa òfin mọ́.” Ní Ìpínlẹ̀ Delta, ẹ̀mí tó dára tí àwọn arákùnrin tó ń kọ́ Gbọ̀ngàn Ìjọba kan ní wú ọmọbìnrin kan lórí débi pé ó ní kí àwọn Ẹlẹ́rìí máa bá òun ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Ṣáájú kí wọ́n tó parí iṣẹ́ olóṣù kan ààbọ̀ náà, ó ti di akéde tí kò tíì ṣèrìbọmi.
4. Báwo ni ẹ̀ka ọ́fíìsì ṣe ń mọ àwọn ibi tí wọ́n ti nílò Gbọ̀ngàn Ìjọba ní kánjúkánjú?
4 Àwọn Ohun Tí A Ṣe Kí Ètò Yìí Lè Kẹ́sẹ Járí: Kò sí àní-àní pé inú wa dùn lórí àwọn ohun tá a ti gbé ṣe, àmọ́ ó dájú pé a ṣì ní ọ̀pọ̀ iṣẹ́ láti ṣe ní Nàìjíríà. A fojú díwọ̀n rẹ̀ pé a ṣì ní tó nǹkan bí èédégbèje [1,300] Gbọ̀ngàn Ìjọba tá ò tíì kọ́. Láfikún sí i, bí ìjọ ṣe ń pọ̀ sí i lọ́dọọdún fi hàn pé a óò ní láti máa kọ́ nǹkan bí ọgọ́rin Gbọ̀ngàn Ìjọba tuntun lọ́dọọdún. Kó bàa lè ṣeé ṣe fún wa láti mọ àwọn ibi tí wọ́n ti nílò Gbọ̀ngàn Ìjọba ní kánjúkánjú, a máa ń ṣètò pé kí àwọn alábòójútó arìnrìn-àjò ṣe àwọn ìwádìí kan. Lẹ́yìn èyí, ẹ̀ka ọ́fíìsì á wá ṣe ìtòlẹ́sẹẹsẹ bí àwọn ará ṣe nílò Gbọ̀ngàn Ìjọba sí, èyí tí yóò tọ́ àwọn arákùnrin tó ń ṣojú fún Ẹ̀ka Tí Ń Bójú Tó Kíkọ́ Gbọ̀ngàn Ìjọba ní ẹ̀ka ọ́fíìsì sọ́nà láti ṣe àwọn ètò tó yẹ kí iṣẹ́ ilé kíkọ́ tó bẹ̀rẹ̀. Àwọn arákùnrin wọ̀nyí máa ń ran àwọn ìjọ lọ́wọ́ nínú ọ̀ràn wíwá ilẹ̀, nínú ṣíṣàyẹ̀wò ilẹ̀ náà bóyá ó dára fún Gbọ̀ngàn Ìjọba, nínú gbígba gbogbo àwọn ìwé àṣẹ tó yẹ àti nínú pípinnu bóyá àwọn ìjọ ń fẹ́ ìrànwọ́ síwájú sí i láti lè kọ́ Gbọ̀ngàn Ìjọba.
5. Àwọn ohun wo la ṣe kí a lè ṣèrànwọ́ fáwọn tó ń fẹ́ Gbọ̀ngàn Ìjọba?
5 Kó bàa lè ṣeé ṣe fún wa láti kọ́ ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ Gbọ̀ngàn Ìjọba tá a nílò wọ̀nyí, a máa ń tẹ̀ lé àwọn ìlànà ìkọ́lé tá a ti ṣe sílẹ̀, níbàámu pẹ̀lú Ìlànà fún Kíkọ́ Gbọ̀ngàn Ìjọba tí Ẹgbẹ́ Olùṣàkóso pèsè. Ìlànà wọ̀nyí ń jẹ́ ká lè lo àwọn ohun èlò ìkọ́lé tó wà ní àgbègbè kọ̀ọ̀kan, tí yóò mú kó rọrùn fún àwọn ará láti lè máa bójú tó gbọ̀ngàn náà. Nítorí pé owó tó wà lọ́wọ́ ò pọ̀ tó, ó tún ti pọn dandan láti fi ààlà sí irú àwọn tó lè rí ìrànwọ́ gbà àti irú ìrànwọ́ tá a lè ṣe fún wọn. Nítorí ìdí yìí, àwọn ìjọ tí akéde wọn kò bá pé ọgbọ̀n kò ní lè rí ìrànwọ́ gbà láti kọ́ Gbọ̀ngàn Ìjọba wọn lákòókò yìí. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ó wù wá ní ẹ̀ka ọ́fíìsì láti fi owó ṣètìlẹyìn fún àwọn ìjọ tí wọ́n nílò ìrànwọ́ gidigidi, àwọn tó bá gba irú ìrànwọ́ bẹ́ẹ̀ ní láti bójú tó àwọn ìnáwó kan fúnra wọn. Lára irú ìnáwó bẹ́ẹ̀ ni ríra ilẹ̀, gbígba ìwé àṣẹ àtàwọn ìnáwó mìíràn tó dá lórí iṣẹ́ ilé kíkọ́ náà.
6. Àwọn ojúṣe wo làwọn ìjọ ń ṣe nígbà tí iṣẹ́ kíkọ́ Gbọ̀ngàn Ìjọba wọn bá ń lọ lọ́wọ́?
6 Ní báyìí, àwọn ohun tó jẹ́ ojúṣe ìjọ ṣáájú kí iṣẹ́ ìkọ́lé tó bẹ̀rẹ̀ àti nígbà tí iṣẹ́ bá ń lọ lọ́wọ́ ti pọ̀ sí i, inú wa sì dùn láti rí bí àwọn ará ṣe ń kọ́wọ́ tì í lẹ́yìn. (Neh. 4:6) Ẹrù iṣẹ́ ìjọ ni láti ṣe gbogbo ohun tí wọ́n bá lè ṣe láti kópa nínú iṣẹ́ kíkọ́ Gbọ̀ngàn Ìjọba wọn. Ẹgbẹ́ Àwọn Tí Ń Kọ́ Gbọ̀ngàn Ìjọba máa ń sọ fún àwọn alàgbà nípa irú àwọn oníṣẹ́ ọwọ́ tí wọ́n ń fẹ́ àti iye àwọn olùyọ̀ǹda-ara-ẹni tí wọ́n nílò. Àwọn alàgbà tún lè sọ fún àwọn ìjọ tó wà nítòsí pé kí wọ́n wá ràn wọ́n lọ́wọ́. (Gál. 6:2) Bó bá jẹ́ pé kò ṣeé ṣe fún ọ láti kópa ní tààràtà nínú iṣẹ́ ìkọ́lé náà, ǹjẹ́ o lè ṣèrànwọ́ láwọn ọ̀nà míì? Bí àpẹẹrẹ, ǹjẹ́ o lè bá wọn se oúnjẹ, tàbí kó o bá wọn ṣe iṣẹ́ olùṣọ́, tàbí kó o bá wọn gba ìwé àṣẹ lọ́dọ̀ ìjọba tàbí kẹ̀, kó o gbà lára Ẹgbẹ́ Àwọn Tí Ń Kọ́ Gbọ̀ngàn Ìjọba sílé? Níwọ̀n bí gbogbo wa ti “ní àwọn ẹ̀bùn tí ó yàtọ̀ síra ní ìbámu pẹ̀lú inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí tí a fi fún wa,” ẹ jẹ́ ká máa bá a nìṣó láti lò wọ́n dé ẹ̀kúnrẹ́rẹ́.—Róòmù 12:4, 6.
7. (a) Ọ̀nà pàtàkì wo la lè gbà ṣètìlẹyìn fún iṣẹ́ ìkọ́lé tó fa kíki yìí? (b) Ibo ni àwọn ìtọ́ni àti ìlànà tí à ń tẹ̀ lé ti ń wá?
7 Fífi Ìṣòtítọ́ Ṣètìlẹyìn fún Ètò Yìí: Onírúurú ọ̀nà ni gbogbo akéde lè gbà ṣètìlẹyìn fún ètò kíkọ́ Gbọ̀ngàn Ìjọba yìí, tí í ṣe iṣẹ́ pàtàkì tó fa kíki. Ọ̀nà kan tá a fi lè ṣe èyí ni nípa fífọwọ́ sowọ́ pọ̀ pẹ̀lú àwọn arákùnrin tó ń ṣojú fún Ẹ̀ka Tí Ń Bójú Tó Kíkọ́ Gbọ̀ngàn Ìjọba ní ẹ̀ka ọ́fíìsì, bóyá nígbà tí wọ́n ń ṣe àwọn ètò tó yẹ ṣáájú iṣẹ́ kíkọ́ Gbọ̀ngàn Ìjọba ni o tàbí nígbà tí iṣẹ́ ń lọ lọ́wọ́. Bí àpẹẹrẹ, ó lè jẹ́ pé irú àwọn àga kan la fẹ́, tàbí pé irú àwọn ohun ọ̀ṣọ́ kan la fẹ́ ṣe sí gbọ̀ngàn náà, tàbí kó tiẹ̀ jẹ́ pé gbọ̀ngàn tó tóbi gan-an ló wù wá. Àmọ́, bá a bá ń rántí pé ìlànà ètò àjọ Ọlọ́run làwọn arákùnrin wọ̀nyí ń tẹ̀ lé, á ràn wá lọ́wọ́ láti fọwọ́ sowọ́ pọ̀ ká má bàa ṣe ohun tó lòdì sí ìlànà wọ̀nyẹn. (1 Kọ́r. 14:40) Síwájú sí i, àwọn arákùnrin wọ̀nyí, tí ń bá Ẹ̀ka Tí Ń Bójú Tó Kíkọ́ Gbọ̀ngàn Ìjọba ní ẹ̀ka ọ́fíìsì wa ṣiṣẹ́ pọ̀, ti gba ìdánilẹ́kọ̀ọ́ àti ìtọ́ni nípa bí wọ́n á ṣe náwó àti bí wọ́n á ṣe ṣe àkọsílẹ̀ ìnáwó. Yàtọ̀ síyẹn, ẹ̀ka ọ́fíìsì ni wọ́n á jíhìn fún ní tààràtà lórí àwọn nǹkan wọ̀nyí. A fẹ́ fi ìṣòtítọ́ kọ́wọ́ ti àwọn ìtọ́ni àti ìlànà tí àwọn arákùnrin tá a yàn wọ̀nyí ń tẹ̀ lé, bí wọ́n ti ń ṣiṣẹ́ lábẹ́ ìdarí Ẹgbẹ́ Olùṣàkóso.—Mát. 24:45-47; 2 Tím. 2:2.
8. (a) Kí làwọn ìjọ lè ṣe láti múra sílẹ̀ fún iṣẹ́ ìkọ́lé? (b) Ẹ̀mí wo ló yẹ káwọn ìjọ ní sí ìpinnu tí wọ́n ṣe, kí nìdí tí èyí sì fi jẹ́ àmì pé wọ́n jẹ́ onífẹ̀ẹ́?
8 Ní báyìí, owó tó wà lọ́wọ́ fún iṣẹ́ kíkọ́ Gbọ̀ngàn Ìjọba ti mú kó di dandan fún wa láti dín iye gbọ̀ngàn tá a ó lè máa kọ́ kù. Látàrí èyí, àwọn ìjọ tí wọ́n bá lè fúnra wọn kówó tí wọn yóò fi ra ilẹ̀ jọ ni ẹ̀ka ọ́fíìsì ń kọ́kọ́ ṣèrànwọ́ fún. Nítorí náà, ó yẹ kí àwọn ìjọ ṣe ìtìlẹyìn ọrẹ tó máa pọ̀ tó láti fi ra ilẹ̀ fúnra wọn. (Lúùkù 14:28-30) Ọ̀pọ̀ ìjọ ti pinnu láti máa fi owó ránṣẹ́ sí ẹ̀ka ọ́fíìsì lóṣooṣù, bóyá láti fi ṣètìlẹyìn fún iṣẹ́ ìkọ́lé ọjọ́ iwájú tàbí láti kàn fi ṣètìlẹyìn fún Owó Àkànlò fún Gbọ̀ngàn Ìjọba kárí ayé. Fífi ìṣòtítọ́ tẹ̀ lé ìpinnu tá a ṣe, gẹ́gẹ́ bá a ṣe ṣèlérí láti máa fi iye kan ránṣẹ́, jẹ́ ọ̀nà pàtàkì kan láti ṣètìlẹyìn fún ètò kíkọ́ Gbọ̀ngàn Ìjọba. (Mát. 5:37) Ó tún ń fi hàn pé a ní irú ìfẹ́ tó yẹ Kristẹni, àti pé a fẹ́ kí àwọn ìjọ mìíràn rí irú ìrànwọ́ kan náà gbà láti kọ́ Gbọ̀ngàn Ìjọba tiwọn.—Fílí. 2:4.
9. Kí nìdí tó fi yẹ kí ẹ̀ka ọ́fíìsì fọwọ́ sí iṣẹ́ ìkọ́lé wa ká tó bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ kódà bó bá jẹ́ pé fúnra wa la kówó jọ?
9 Àwọn ìjọ tó bá ṣeé ṣe fún láti fi owó tí wọ́n kó jọ fúnra wọn máa báṣẹ́ ìkọ́lé wọn lọ lè ṣe bẹ́ẹ̀, àmọ́ kí èyí jẹ́ lẹ́yìn tí ẹ̀ka ọ́fíìsì bá ti fọwọ́ sí i pé kí wọ́n ṣe bẹ́ẹ̀. A ti fún àwọn alàgbà nítọ̀ọ́ni nípa bí wọ́n ṣe lè kàn sí ẹ̀ka ọ́fíìsì ká lè fọwọ́ sí iṣẹ́ ìkọ́lé náà, kí wọ́n sì gba ìtọ́sọ́nà ṣáájú kí wọ́n tó dáwọ́ lé irú iṣẹ́ ìkọ́lé bẹ́ẹ̀, tàbí kí wọ́n tó ra ilẹ̀ tí wọ́n bá fẹ́ rà. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé à ń rọ àwọn ará lẹ́nì kọ̀ọ̀kan láti fi ẹ̀mí ọ̀làwọ́ ṣètìlẹyìn fún kíkọ́ Gbọ̀ngàn Ìjọba wọn, kò yẹ kí ẹnikẹ́ni ronú pé nítorí pé àwọn làwọn kówó jọ, ìyẹn fún àwọn láǹfààní láti ṣe ohun tó yàtọ̀ sóhun tí ìlànà sọ nípa ọ̀nà tí wọ́n á gbà kọ́lé tàbí irú ohun ọ̀ṣọ́ tí wọ́n lè ṣe sí gbọ̀ngàn náà. Ó ṣe pàtàkì láti máa rántí bí ètò yìí ṣe gbòòrò tó, ká sì jẹ́ kí ìlànà tí ètò àjọ fi lélẹ̀ tẹ́ wa lọ́rùn.—2 Kọ́r. 8:14.
10. (a) Báwo la ṣe lè fi hàn pé a ní ìtẹ́lọ́rùn? (b) Kí ni ojúṣe wa sí Gbọ̀ngàn Ìjọba wa?
10 Ẹ̀mí ìtẹ́lọ́rùn yóò jẹ́ ká mọrírì Gbọ̀ngàn Ìjọba alábọ́ọ́dé. (1 Tím. 6:8) Nítorí náà, kí àwọn ìjọ tí wọ́n ti kọ́ Gbọ̀ngàn Ìjọba wọn parí má ṣe dáwọ́ lé àwọn iṣẹ́ tuntun, irú bíi mímọ ọgbà yí i ká, kíkọ́ ilé fún ẹni tí yóò máa mójú tó Gbọ̀ngàn Ìjọba tàbí ṣíṣe ìyípadà sáwọn ibì kan lára gbọ̀ngàn wọn. Àmọ́ o, wọ́n lè ṣe èyí bí àwọn ipò tó ṣàrà ọ̀tọ̀ bá jẹ yọ, tí ẹ̀ka ọ́fíìsì sì ti kọ́kọ́ fọwọ́ sí i. Ńṣe ló yẹ kí àwọn ìjọ wọ̀nyí gbájú mọ́ bíbójútó Gbọ̀ngàn Ìjọba wọn àti àyíká rẹ̀. Kódà bí ibi ìpàdé tẹ́ ẹ̀ ń lò báyìí kì í bá ṣe Gbọ̀ngàn Ìjọba tuntun, ẹ ní láti máa bójú tó o kẹ́ ẹ sì máa fowó ṣètìlẹyìn láti ṣe èyí. Kò sí àwíjàre kankan fún jíjẹ́ kí ibi ìpàdé èyíkéyìí di ibi tí kò bójú mu, ì báà tiẹ̀ jẹ́ ilé ìpàdé kékeré. (2 Kíró. 24:13; 29:3) A ti sọ fún àwọn alábòójútó arìnrìn-àjò pé kí wọ́n máa ṣèwádìí nípa èyí lọ́wọ́ àwọn alàgbà ìjọ nígbà tí wọ́n bá ń ṣèbẹ̀wò wọn ẹlẹ́ẹ̀mejì lọ́dún, kí wọ́n sì rí i dájú pé àwọn ará ń bójú tó Gbọ̀ngàn Ìjọba wọn bó ṣe tọ́ àti bó ṣe yẹ.
11. Báwo la ṣe lè fi Sáàmù 32:8 sílò nínú ètò kíkọ́ Gbọ̀ngàn Ìjọba wa?
11 Ìtọ́sọ́nà Ètò Àjọ Ọlọ́run Ń Mú Ìbùkún Wá: Jèhófà mú un dá wa lójú nínú Sáàmù 32:8 pé: “Èmi yóò mú kí o ní ìjìnlẹ̀ òye, èmi yóò sì fún ọ ní ìtọ́ni nípa ọ̀nà tí ìwọ yóò máa tọ̀. Dájúdájú, èmi yóò fún ọ ní ìmọ̀ràn pẹ̀lú ojú mi lára rẹ.” Báwo la ṣe lè fi ọ̀rọ̀ yìí sílò nínú ètò kíkọ́ Gbọ̀ngàn Ìjọba wa? Ìgbà gbogbo la máa ń fẹ́ láti tẹ̀ lé ìtọ́ni Jèhófà. Gẹ́gẹ́ bí Jèhófà ṣe fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ nítọ̀ọ́ni láti kọ́ tẹ́ńpìlì, ó ń fún wa nítọ̀ọ́ni nípasẹ̀ ètò àjọ rẹ̀ lónìí ká bàa lè ṣe iṣẹ́ ìkọ́lé wa láṣeyọrí. Nípa báyìí, a ò ní fẹ́ jẹ́ ẹlẹ́mìí tinú-mi-ni-màá-ṣe.—Héb. 13:17.
12. Báwo ni gbogbo wa ṣe lè kópa nínú iṣẹ́ ìkọ́lé pàtàkì yìí?
12 Ọ̀pọ̀ jù lọ wa ló jẹ́ pé ẹ̀ẹ̀kan ṣoṣo ní ìgbésí ayé la máa lè kópa nínú iṣẹ́ kíkọ́ Gbọ̀ngàn Ìjọba. Dájúdájú, a óò fẹ́ láti ṣe gbogbo ohun tá a lè ṣe, ká lè tipa bẹ́ẹ̀ fi ìfẹ́ àti ìmọrírì wa sí Jèhófà hàn. Gbogbo wa lè kópa nínú ètò yìí nípa fífi owó ṣètìlẹyìn, nípa títẹ̀lé àwọn ìlànà tí ètò àjọ ti gbé kalẹ̀, nípa yíyọ̀ǹda ara wa àti nípa fífọwọ́ sowọ́ pọ̀ pẹ̀lú àwọn ètò tí ètò àjọ ṣe. Bákan náà, a tún fẹ́ ṣe ojúṣe wa nínú iṣẹ́ kíkọ́ Gbọ̀ngàn Ìjọba wa, ká sì fọwọ́ sowọ́ pọ̀ ní kíkún pẹ̀lú Ẹgbẹ́ Àwọn Tí Ń Kọ́ Gbọ̀ngàn Ìjọba tá a yàn láti darí iṣẹ́ yìí. Nígbà náà, gẹ́gẹ́ bíi tẹ́ńpìlì ọjọ́ Hágáì, àwọn Gbọ̀ngàn Ìjọba wa yóò máa kún fún àwọn ohun fífani lọ́kàn mọ́ra látinú àwọn orílẹ̀-èdè bí àwọn olóòótọ́ ṣe ń wá kẹ́kọ̀ọ́ nípa Jèhófà. Ká sòótọ́, Jèhófà ‘ń mú kí gbogbo iṣẹ́ rẹ̀,’ títí kan kíkọ́ Gbọ̀ngàn Ìjọba, ‘wà ní ìfọwọ́sowọ́pọ̀ fún ire àwọn tí ó nífẹ̀ẹ́ rẹ̀.’—Róòmù 8:28.
[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 6]
Ọ̀rọ̀ Ìmọrírì Tí Àwọn Ará Sọ Nípa Ètò Kíkọ́ Gbọ̀ngàn Ìjọba ní Nàìjíríà
● “Gbogbo wa la mọrírì ètò kíkọ́ Gbọ̀ngàn Ìjọba gidigidi, ìpinnu wa sì ni pé a óò kọ́wọ́ ti gbogbo ètò náà látòkèdélẹ̀.”—Ìpínlẹ̀ Imo
● “Àní, ńṣe ló dà bí àlá, pé ohun tá a ti ń gbàdúrà fún láti ọ̀pọ̀ ọdún sẹ́yìn lè di ṣíṣe nípasẹ̀ ètò tí ‘ẹrú olóòótọ́ àti olóye’ gbé kalẹ̀.”—Ìpínlẹ̀ Èkó
● “Mo kọ̀wé yìí láti fi ìmọrírì àtọkànwá mi hàn fún [ètò ìkọ́lé] àgbàyanu yìí, tí ẹ̀ ń lò láti rí i dájú pé a gbé ibi ìjọsìn Jèhófà ga ju gbogbo àwọn ibi ìjọsìn mìíràn lọ.”—Ìpínlẹ̀ Ẹnúgu
● “A kọ̀wé yìí láti fi ìmọrírì wa hàn sí Ẹgbẹ́ Olùṣàkóso fún ètò dáradára tí wọ́n gbé kalẹ̀ láti kọ́ Gbọ̀ngàn Ìjọba púpọ̀ sí i jákèjádò ayé.”—Ìpínlẹ̀ Ọ̀ṣun
● “Tẹ́lẹ̀tẹ́lẹ̀, a wà lára àwọn ìjọ Nàìjíríà tí kò ní Gbọ̀ngàn Ìjọba; lónìí, a ní Gbọ̀ngàn Ìjọba ẹlẹ́wà kan, tó bójú mu, tá a sì kùn dáadáa.”—Ìpínlẹ̀ Ebonyi
[Àtẹ Ìsọfúnnni tó wà ní ojú ìwé 3]
Iye Gbọ̀ngàn Ìjọba tí a kọ́ ní Nàìjíríà láti ọdún iṣẹ́ ìsìn 2000 sí 2003
2000 2001 2002 2003
102 125 171 236