Àtúnyẹ̀wò Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run
Àwọn ìbéèrè tó wà nísàlẹ̀ wọ̀nyí ni a óò dáhùn ní Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run ní ọ̀sẹ̀ tó bẹ̀rẹ̀ ní April 26, 2004. Alábòójútó ilé ẹ̀kọ́ yóò darí àtúnyẹ̀wò yìí fún ọgbọ̀n ìṣẹ́jú, èyí tá a gbé ka àwọn iṣẹ́ ilé ẹ̀kọ́ tá a ṣe ní ọ̀sẹ̀ March 1 sí April 26, 2004. [Àkíyèsí: Níbi tí a kò bá ti tọ́ka sí ibi tí a ti mú ìdáhùn jáde lẹ́yìn ìbéèrè kan, kí o fúnra rẹ ṣe ìwádìí láti wá ìdáhùn sí àwọn ìbéèrè náà.—Wo ìwé Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run, ojú ìwé 36 àti 37.]
ÀNÍMỌ́ Ọ̀RỌ̀ SÍSỌ
1. Nígbà tá a bá ń sọ àsọyé, kí nìdí tó fi dára pé ká máa lo ìlapa èrò dípò tá a ó fi kọ gbogbo ọ̀rọ̀ wa síwèé ká máa wá kà á jáde ní tààràtà? [be-YR ojú ìwé 166 ìpínrọ̀ 3]
2. Nígbà tá a bá ń múra òde ẹ̀rí sílẹ̀, báwo la ṣe lè ṣe ìlapa èrò kan sórí? [be-YR ojú ìwé 167 ìpínrọ̀ 3]
3. Lo Ìṣe 13:16-41 àti Ìṣe 17:2, 3 láti fi ṣàlàyé bí Pọ́ọ̀lù ṣe ‘fi ẹ̀rí ìdánilójú hàn lọ́nà tó bọ́gbọ́n mu pé Jésù ni Kristi náà.’ (Ìṣe 9:22) [be-YR ojú ìwé 170 ìpínrọ̀ 2]
4. Kí ni díẹ̀ lára àwọn àǹfààní tó wà nínú sísọ̀rọ̀ láìgbáralé àkọsílẹ̀? [be-YR ojú ìwé 175 ìpínrọ̀ 1 sí 4]
5. Àwọn ọ̀fìn wo ló wà nínú sísọ̀rọ̀ láìgbáralé àkọsílẹ̀, kí ló sì lè ràn wá lọ́wọ́ láti yẹra fún wọn? [be-YR ojú ìwé 175 ìpínrọ̀ 5 sí ojú ìwé 176 ìpínrọ̀ 3]
IṢẸ́ AKẸ́KỌ̀Ọ́ KÌÍNÍ
6. Gẹ́gẹ́ bí ìtàn tó wà nínú Jẹ́nẹ́sísì 32:24-32 ṣe fi hàn, kí ni Jákọ́bù tó jẹ́ ẹni ọdún mẹ́tàdínlọ́gọ́rùn-ún ṣe láti rí ìbùkún Jèhófà gbà, ẹ̀kọ́ wo sì ni èyí kọ́ wa? [w02-YR 8/1 ojú ìwé 29 sí 31]
7. Kí ni “agbára láti ronú,” báwo sì ni kò ṣe ní jẹ́ ká ṣìwà hù, kí ọ̀rọ̀ sì máa dùn wá ju bó ṣe yẹ lọ? (Òwe 1:4) [w02-YR 8/15 ojú ìwé 21 àti 22]
8. Báwo ni àwọn tó ń sọ àsọyé fún gbogbo ènìyàn ṣe lè gbé ọ̀rọ̀ wọn karí Ìwé Mímọ́? [be-YR ojú ìwé 52 ìpínrọ̀ 6 sí ojú ìwé 53 ìpínrọ̀ 5]
9. Bí alásọyé kan bá fẹ́ sọ èrò tó wà nínú ìwé àsọyé kan di àlàyé tó kún rẹ́rẹ́ látinú Ìwé Mímọ́, àwọn ìpinnu wo ló yẹ kí ó ṣe? [be-YR ojú ìwé 54 ìpínrọ̀ 2 sí 4]
10. Kí nìdí tí Jèhófà fi ń fi mánà bọ́ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀ àti lóṣooṣù nínú aginjù, kí sì la lè rí kọ́ látinú èyí? (Diu. 8:16) [w02-YR 9/1 ojú ìwé 30 ìpínrọ̀ 3 àti 4]
BÍBÉLÌ KÍKÀ Ọ̀SỌ̀Ọ̀SẸ̀
11. Gẹ́gẹ́ bí Jẹ́nẹ́sísì 37:12-17 ṣe fi hàn, ìjọra wo la lè rí láàárín ìwà Jósẹ́fù àti ti Jésù? [w87-YR 5/1 ojú ìwé 12 ìpínrọ̀ 12]
12. Gẹ́gẹ́ bó ṣe wà nínú àkọsílẹ̀ inú Jẹ́nẹ́sísì 42:25-35, báwo ni ìyọ́nú tí Jósẹ́fù lò àti ti Jésù ṣe jọra? [w87-YR 5/1 ojú ìwé 18 ìpínrọ̀ 10; ojú ìwé 19 ìpínrọ̀ 17]
13. Ọ̀nà wo ni àwọn ohun tí ẹgbẹ́ ẹrú náà ń pèsè lónìí fi bá ètò pínpín ọkà nígbà ayé Jósẹ́fù mu? (Jẹ́n. 47:21-25)
14. Nígbà tí Jèhófà sọ pé, “Èmi yóò jẹ́ ohun tí èmi yóò jẹ́,” kí ni Jèhófà ń jẹ́ ká mọ̀ nípa orúkọ rẹ̀? (Ẹ́kís. 3:14, 15)
15. Ewu méjì tó ń bá ẹ̀mí ṣíṣàròyé rìn wo la kíyè sí nínú Ẹ́kísódù 16:2, 3? [w93-YR 3/15 ojú ìwé 20 àti 21]