Àwọn Ìfilọ̀
◼ Ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ tí a ó fi lọni ní July àti August: A lè fi èyíkéyìí nínú àwọn ìwé pẹlẹbẹ olójú ewé 32 tó tẹ̀ lé e yìí lọni: Akoso Naa Ti Yoo Mu Paradise Wá, Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà—Ta Ni Wọ́n? Kí Ni Wọ́n Gbà Gbọ́?, Ẹmi Awọn Oku—Wọn Ha Le Ran Ọ Lọwọ Tabi Pa Ọ Lara Bi? Wọn Ha Wa Niti Gidi Bi?, Gbádùn Iwalaaye Lori Ilẹ Ayé Titilae!, Ìwé Kan Tí Ó Wà fún Gbogbo Ènìyàn, Iwọ Ha Nilati Gbàgbọ́ Ninu Mẹtalọkan Bí?, Ki Ni Ète Igbesi-Aye? Bawo Ni Iwọ Ṣe Le Rí I?, Kí Ní Ń Ṣẹlẹ̀ sí Wa Nígbà Tí A Bá Kú?, Nígbà Tí Ẹnìkan Tí Ìwọ Fẹ́ràn Bá Kú?, Orukọ Atọrunwa naa Tí Yoo Wà Titilae, Ọlọrun Ha Bikita Nipa Wa Niti Gidi Bi?, Ọ̀nà Tó Lọ sí Ìyè Àìnípẹ̀kun—Ṣé O Ti Rí I?, àti “Sawo O! Emi Nsọ Ohun Gbogbo Di Ọtun.” September: Sún Mọ́ Jèhófà. Bí kò bá sí, a lè lo ìwé Kíyè sí Àsọtẹ́lẹ̀ Dáníẹ́lì! tàbí ìwé Iwọ Le Walaaye Titilae ninu Paradise lori Ilẹ Aye.
◼ Bẹ̀rẹ̀ láti oṣù September, ẹṣin ọ̀rọ̀ àsọyé táwọn alábòójútó àyíká yóò máa sọ ni “Bí A Ṣe Lè Fi Ìgbàgbọ́ àti Ìgboyà Kojú Àwọn Ìṣẹ̀lẹ̀ Ọjọ́ Iwájú.”
◼ A ti fi ẹ̀dà fọ́ọ̀mù Literacy Report (Ìròyìn Nípa Ètò Mọ̀ọ́kọ-Mọ̀ọ́kà) ránṣẹ́ sí ìjọ kọ̀ọ̀kan. Lẹ́yìn tẹ́ ẹ bá ti kọ̀wé sínú wọn, ẹ jọ̀wọ́ ẹ dá ẹ̀dà kan padà sí ẹ̀ka ọ́fíìsì ní August 1. Kí ẹ tọ́jú ẹ̀dà kejì sínú fáìlì ìjọ.
◼ Nígbà táwọn akéde bá ń ṣiṣẹ́ ní ìpínlẹ̀ tí a kò pín fúnni, wọ́n lè fi ìwé pẹlẹbẹ Béèrè tàbí ìwé Ìmọ̀ lọni. Wọ́n lè fi ìwé èyíkéyìí mìíràn lọni bí onílé bá ti ní àwọn ìwé méjì wọ̀nyí tẹ́lẹ̀. Kí gbogbo wọn kó onírúurú ìwé àṣàrò kúkúrú dání nítorí àwọn kò-sí-nílé tàbí àwọn mìíràn tí kò bá gba ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́. Kí a sapá láti padà lọ síbi tí wọ́n bá ti fi ìfẹ́ hàn, pàápàá níbi táwọn ìjọ tó wà nítòsí bá ti lè lọ sáwọn ìpínlẹ̀ tí a kò pín fúnni.
◼ Kí àwọn akọ̀wé ìjọ máa rí i pé Ìwé Ìwọṣẹ́ Ìsìn Aṣáájú Ọ̀nà Déédéé (S-205-YR) àti Ìwé Ìwọṣẹ́ Ìsìn Aṣáájú Ọ̀nà Olùrànlọ́wọ́ (S-205b-YR) tí ó pọ̀ tó wà lọ́wọ́. Ẹ lè béèrè fún àwọn fọ́ọ̀mù wọ̀nyí nípa lílo fọ́ọ̀mù Literature Request Form (S-14) [Fọ́ọ̀mù Tí A Fi Ń Béèrè fún Ìwé Ìkẹ́kọ̀ọ́]. Kí ẹ rí i pé èyí tí ìjọ ní lọ́wọ́ yóò tó lò fún ọdún kan, ó kéré tán.
◼ Ṣáájú káwọn akọ̀wé ìjọ tó fi fọ́ọ̀mù ìforúkọsílẹ̀ fún iṣẹ́ aṣáájú ọ̀nà déédéé ránṣẹ́ sí wa, kí wọ́n máa ṣàyẹ̀wò àwọn fọ́ọ̀mù náà láti rí i dájú pé ìsọfúnni inú wọn pé pérépéré. Báwọn tó fẹ́ di aṣáájú ọ̀nà kò bá lè rántí déètì náà gan-an tí wọ́n ṣe ìrìbọmi, kí wọ́n fojú díwọ̀n déètì kan kí wọ́n sì kọ ọ́ pa mọ́ síbì kan. Kí akọ̀wé kọ déètì tí wọ́n fojú díwọ̀n yìí sínú káàdì Congregation’s Publisher Record [Àkọsílẹ̀ Ìròyìn Akéde Ìjọ].
◼ Nígbàkigbà tó o bá ń ṣètò fúnra rẹ láti rìnrìn àjò lọ sí orílẹ̀-èdè mìíràn, tó o sì fẹ́ lọ sí ìpàdé ìjọ, àpéjọ àyíká, tàbí àpéjọ àgbègbè níbẹ̀, ọ̀dọ̀ ẹ̀ka ọ́fíìsì tó ń bójú tó iṣẹ́ wa lórílẹ̀-èdè náà ni kó o ti béèrè nípa déètì, àkókò àti ibi tí wọ́n á ti ṣe ìpàdé ọ̀hún. Àdírẹ́sì àwọn ẹ̀ka ọ́fíìsì wà ní ojú ìwé tó kẹ́yìn nínú ìwé ọdọọdún wa, Yearbook ti lọ́ọ́lọ́ọ́.
◼ Ó ṣe pàtàkì pé kí ẹ̀ka ọ́fíìsì wa níbí ní àkọsílẹ̀ tó bágbà mu nípa àdírẹ́sì àti nọ́ńbà tẹlifóònù gbogbo alábòójútó olùṣalága àti akọ̀wé. Bí ìyípadà bá wà nígbàkigbà, kí Ìgbìmọ̀ Iṣẹ́ Ìsìn Ìjọ kọ ọ̀rọ̀ sínú fọ́ọ̀mù Presiding Overseer/Secretary Change of Address (S-29) [Ìyípadà Àdírẹ́sì Alábòójútó Olùṣalága Àti Akọ̀wé], kí wọ́n buwọ́ lù ú, kí wọ́n sì fi ránṣẹ́ sí ẹ̀ka ọ́fíìsì lọ́gán. Èyí kan ìyípadà tó bá wà nínú area code [àkànṣe nọ́ńbà tẹlifóònù àgbègbè kọ̀ọ̀kan].