ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • km 9/04 ojú ìwé 7
  • Àwọn Ìfilọ̀

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Àwọn Ìfilọ̀
  • Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2004
Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2004
km 9/04 ojú ìwé 7

Àwọn Ìfilọ̀

◼ Ìwé tí a ó fi lọni ní September: Sún Mọ́ Jèhófà. Bí kò bá sí, a lè lo ìwé Kíyè sí Àsọtẹ́lẹ̀ Dáníẹ́lì! tàbí Iwọ Le Walaaye Titilae ninu Paradise lori Ilẹ Aye. October: Ilé Ìṣọ́ àti Jí! la ó fi lọni jálẹ̀ gbogbo oṣù yìí. Níbi tí wọ́n bá ti fìfẹ́ hàn, kí a fi ìwé pẹlẹbẹ Béèrè lọni, kí a sì sapá gidigidi láti bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. November: Kẹ́kọ̀ọ́ Lọ́dọ̀ Olùkọ́ Ńlá Náà la ó fi lọni. Bí ẹni tó ò ń wàásù fún bá sọ pé òun ò lọ́mọ, fún un ní ìwé pẹlẹbẹ Béèrè. Gbìyànjú láti fi ìwé pẹlẹbẹ yìí bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. December: Ọkunrin Titobilọla Julọ Ti O Tii Gbé Ayé Rí. Bí kò bá sí, a lè lo Iwe Itan Bibeli Mi tàbí Iwọ Le Walaaye Titilae ninu Paradise lori Ilẹ Aye.

◼ À ń rán àwọn alàgbà létí pé kí wọ́n ṣiṣẹ́ lórí àwọn ìtọ́ni tó wà nínú Ilé-ìṣọ́nà ti April 15, 1991, ojú ìwé 21 sí 23, èyí tó sọ̀rọ̀ nípa àwọn tí a yọ lẹ́gbẹ́ tàbí tí wọ́n yọ ara wọn lẹ́gbẹ́, tó yẹ kí àwọn alàgbà bẹ̀ wò.

◼ Bí ìjọ bá ti gba ẹ̀dà Ilé Ìṣọ́ àti Jí! tuntun, kí a fún àwọn ará láìjáfara. Èyí á jẹ́ kí àwọn akéde lè mọ ohun tó wà nínú àwọn ìwé ìròyìn wọ̀nyí kí wọ́n tó fi lọni lóde ẹ̀rí.

◼ A óò sọ àkànṣe àsọyé fún gbogbo èèyàn fún sáà Ìṣe Ìrántí ti ọdún 2005 ní ọjọ́ Sunday, April 10. A óò ṣèfilọ̀ àkòrí àsọyé náà nígbà tó bá yá. Kí àwọn ìjọ tí wọ́n bá ní ìbẹ̀wò alábòójútó àyíká, àpéjọ àyíká, tàbí àpéjọ àkànṣe ní òpin ọ̀sẹ̀ yẹn sọ àkànṣe àsọyé yìí ní ọ̀sẹ̀ tó tẹ̀ lé e. Kí ìjọ kankan má ṣe sọ àkànṣe àsọyé yìí ṣáájú April 10, 2005.

◼ Níwọ̀n bó ti jẹ́ pé òpin ọ̀sẹ̀ márùn-ún ló máa wà nínú oṣù October, oṣù yìí á dára gan-an láti fi ṣe aṣáájú ọ̀nà olùrànlọ́wọ́.

◼ Ìtẹ̀jáde Tuntun Tó Wà:

Ìdìpọ̀ Jí! ọdún 2003—Gẹ̀ẹ́sì

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́