ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • km 11/04 ojú ìwé 3
  • Àpótí Ìbéèrè

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Àpótí Ìbéèrè
  • Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2004
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ìdí Tó Fi Yẹ Ká Jẹ́ Ẹni Tó Mẹ̀tọ́mọ̀wà
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2017
  • O Lè Jẹ́ Amẹ̀tọ́mọ̀wà Bí Kò Bá Tiẹ̀ Rọrùn
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2017
  • Bó O Ṣe Lè Láyọ̀ Tí Iṣẹ́ Ìsìn Rẹ Bá Yí Pa Dà
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2019
  • “Ọgbọ́n Wà Pẹ̀lú Àwọn Amẹ̀tọ́mọ̀wà”
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2000
Àwọn Míì
Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2004
km 11/04 ojú ìwé 3

Àpótí Ìbéèrè

◼ Báwo ló ṣe yẹ ká bójú tó iṣẹ́ tó bá yẹ ní ṣíṣe nínú ìjọ?

Ìfọwọ́sowọ́pọ̀ gbogbo wa ló ń mú kí nǹkan lọ létòlétò nínú ìjọ àwa èèyàn Jèhófà. (1 Kọ́r. 14:33, 40) Wo àwọn ohun tá a ní láti bójú tó tá a bá fẹ́ ṣe ìpàdé ìjọ kan ṣoṣo. Yàtọ̀ sí ìtòlẹ́sẹẹsẹ ìpàdé ọ̀hún fúnra rẹ̀, ọ̀pọ̀ nǹkan làwọn arákùnrin àti arábìnrin ní láti bójú tó ṣáájú ìpàdé àti lẹ́yìn ìpàdé. Àwọn iṣẹ́ mìíràn táwọn ará ń bójú tó lábẹ́lẹ̀ náà ṣe pàtàkì. Báwo ni olúkúlùkù wa ṣe lè kọ́wọ́ ti gbogbo ètò yìí?

Yọ̀ǹda ara rẹ. Àwọn tó bá lẹ́mìí ìyọ̀ǹda ara ẹni á rí ọ̀pọ̀ nǹkan láti ṣe. (Sm. 110:3) Máa ṣaájò àwọn aláìsàn àtàwọn àgbàlagbà. Máa lọ́wọ́ nínú iṣẹ́ ìmọ́tótó Gbọ̀ngàn Ìjọba. Ọ̀pọ̀ ohun tó ṣàǹfààní la lè ṣe nínú ìjọ láìsí pé ẹnì kan ṣẹ̀ṣẹ̀ ń sọ fún wa. Ohun tó ṣe pàtàkì jù ni pé ká sáà ti fẹ́ láti ṣèrànwọ́.

Máa fi ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ sìn. Inú àwọn onírẹ̀lẹ̀ ẹ̀dá máa ń dùn láti ṣe ohun tó máa ṣe àwọn ẹlòmíràn láǹfààní. (Lúùkù 9:48) Ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ ò ní jẹ́ ká kó ohun tó pọ̀ jù máyà. Bákan náà, ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ ò ní jẹ́ ká kọjá àyè wa.—Òwe 11:2.

Jẹ́ ẹni tó ṣeé gbẹ́kẹ̀ lé. Jẹ́tírò fún Mósè nímọ̀ràn pé kó yan “àwọn ọkùnrin tí ó ṣeé gbẹ́kẹ̀ lé” kí wọ́n lè bójú tó ẹrù iṣẹ́ ní Ísírẹ́lì ìgbàanì. (Ẹ́kís. 18:21) Irú ẹ̀mí bẹ́ẹ̀ ṣe pàtàkì lónìí náà. Máa fi tọkàntọkàn ṣe gbogbo iṣẹ́ tí wọ́n bá yàn fún ọ. (Lúùkù 16:10) Bó ò bá ní ráyè bójú tó iṣẹ́ kan, rí i dájú pé o ṣètò pé kí ẹnì kan bá ọ bójú tó o.

Sa gbogbo ipá rẹ. Ìwé Mímọ́ rọ àwọn Kristẹni pé kí wọ́n máa ṣiṣẹ́ tọkàntọkàn, kódà nígbà tí wọ́n bá ń ṣe iṣẹ́ ayé pàápàá. (Kól. 3:22-24) Mélòómélòó wá ni nígbà tá a bá ń ṣe ohun tó máa mú kí ìjọsìn tòótọ́ tẹ̀ síwájú. Kódà bó bá dà bíi pé iṣẹ́ kan ò fi bẹ́ẹ̀ jọni lójú, yóò ṣe ìjọ láǹfààní bá a bá ṣe é dáadáa.

Iṣẹ́ kọ̀ọ̀kan tí à ń bójú tó ń jẹ́ ká lè fi hàn pé a nífẹ̀ẹ́ Jèhófà àtàwọn arákùnrin wa. (Mát. 22:37-39) Ẹ jẹ́ ká máa fi tọkàntọkàn bójú tó iṣẹ́ èyíkéyìí tí wọ́n bá yàn fún wa nínú ìjọ.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́