Lẹ́tà Látọ̀dọ̀ Ẹgbẹ́ Olùṣàkóso
Lásìkò yìí tá a ti wà ní bèbè ayé tuntun, ó túbọ̀ ṣe pàtàkì gan-an pé ká máa fojú sọ́nà fún dídé Jèhófà. (Sef. 3:8) Wòlíì Dáníẹ́lì sọ pé “Ọlọ́run . . . jẹ́ Olùṣí àwọn àṣírí payá, ó sì ti sọ ohun tí yóò ṣẹlẹ̀ ní apá ìgbẹ̀yìn ọjọ́ di mímọ̀.” (Dán. 2:28) Àǹfààní ńlá ló mà jẹ́ fún wa o pé à ń gbé ní òpin àsìkò tí ẹsẹ Bíbélì yìí sọ àsọtẹ́lẹ̀ rẹ̀, àti pé à ń lóye àwọn àṣírí tí Jèhófà ń ṣí payá!
Jèhófà ń tipasẹ̀ “ẹrú olóòótọ́ àti olóye” ṣí ohun tó fẹ́ ṣe payá ní ṣísẹ̀-n-tẹ̀lé, ìyẹn ni láti kó “ogunlọ́gọ̀ ńlá” àwọn olùjọsìn jọ kárí ayé “láwọn ọjọ́ ìkẹyìn” tó kún fún ìdààmú yìí. (Mát. 24:45; Ìṣí. 7:9; 2 Tím. 3:1) Aísáyà 2:2, 3 fi hàn pé “apá ìgbẹ̀yìn àwọn ọjọ́” ni kíkó tí Jèhófà máa kó àwọn olùjọsìn jọ nígun mẹ́rẹ̀ẹ̀rin ayé yìí yóò wáyé. Lọ́dọọdún ni ìkójọ yìí ń tẹ̀ síwájú láìka rògbòdìyàn àti ìwà ipá tó gbòde jákèjádò ayé sí.
Lọ́dún 2004, ètò àjọ Jèhófà ti jẹ́ ká rí i pé ó yẹ ká túbọ̀ fiyè sí ọ̀rọ̀ Jésù tó sọ pé: “Ẹ máa bá a nìṣó ní ṣíṣọ́nà . . . Ẹ wà ní ìmúratán.” (Mát. 24:42, 44) Àwọn Kristẹni tó mọ “àwọn àmì àkókò” tí wọ́n sì ń gbé ìgbésẹ̀ tó yẹ máa ń tètè róye ohun tí làásìgbò inú ayé túmọ̀ sí. (Mát. 16:1-3) Ọ̀rọ̀ tí Jèhófà sọ nínú Bíbélì ń ṣẹ lóòótọ́, pé òun ò ní padà lẹ́yìn àwọn èèyàn òun tí òun gbé iṣẹ́ ìwàásù lé lọ́wọ́, bó ti wù kí àtakò tó dojú kọ wọ́n pọ̀ tó.
Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn kan ń gbógun lọ́tùn-ún lósì láti dí iṣẹ́ ìwàásù Ìjọba Ọlọ́run lọ́wọ́ tàbí láti dá a dúró, síbẹ̀ àwọn ará wa ń polongo òtítọ́ nìṣó, wọ́n sì ń péjọ pọ̀ déédéé. (Ìṣe 5:19, 20; Héb. 10:24, 25) Ní Rọ́ṣíà, lóṣù June 2004, ilé ẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn kan nílùú Moscow fara mọ́ ìpinnu tílé ẹjọ́ kan ṣe pé kí wọ́n fòfin de iṣẹ́ àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà àti àwọn àjọ tó ń ṣojú wa lábẹ́ òfin ní ìlú yẹn. Síbẹ̀ àwọn ará ò jẹ́ kí ìyẹn kó wọn láyà jẹ; wọ́n mọ ohun tí Ọlọ́run ń fẹ́ kí wọ́n ṣe, wọ́n sì ń ṣègbọràn sí i gẹ́gẹ́ bí Olùṣàkóso dípò àwọn ènìyàn. (Ìṣe 5:29) Ó dá wa lójú pé Jèhófà yóò kọ́ àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ mọ̀ọ́ṣe kódà bí ilé ẹjọ́ bá tiẹ̀ ń dá wọn lẹ́bi.
Ní orílẹ̀-èdè Georgia, láti bí ọdún díẹ̀ sẹ́yìn làwọn èèyànkéèyàn ti ń fi dúkìá àwọn ará ṣòfò, tí àwọn jàǹdùkú ń ṣe wọ́n níṣe ìkà, tí wọ́n sì ń jó àwọn ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ wọn níná lójú wọn. Àmọ́ o, kò sí ohun ìjà èyíkéyìí tí wọ́n gbé sókè sí wọn tó ṣe àṣeyọrí sí rere. (Aísá. 54:17) Lọ́dún iṣẹ́ ìsìn 2004, ìjọba ilẹ̀ Georgia tún fọwọ́ sí ẹ̀sìn àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà padà pé ó jẹ́ ẹ̀sìn tó bófin mu. Àwọn ará wa ti ń ṣe àwọn àpéjọ wọn láìsí ìdààmú èyíkéyìí, ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ sì ń wọlé sí orílẹ̀-èdè náà láìsọsẹ̀. Àwọn akéde ti pọ̀ sí i ju ti ìgbàkígbà rí lọ, bákan náà niye àwọn tó wá sí Iṣe Ìrántí pọ̀ sí i.
Láwọn orílẹ̀-èdè bí Àméníà, Eritrea, Kòríà, Rwanda àti Turkmenistan, wọ́n fi àwọn arákùnrin wa sẹ́wọ̀n nítorí ìgbàgbọ́ wọn. Òótọ́ ni pé àwọn ará wọ̀nyí jìyà láìtọ́, ṣùgbọ́n wọ́n mọ̀ pé Ìwé Mímọ́ ti sọ bẹ́ẹ̀ tẹ́lẹ̀, ìyẹn ló jẹ́ kí wọ́n lè dúró ṣinṣin bí wọ́n ti ń retí ìdáǹdè látọ̀dọ̀ Jèhófà.—1 Pét. 1:6; 2 Pét. 2:9.
Bó o ṣe ń ka “Highlights of the Past Year” (Àwọn Ìṣẹ̀lẹ̀ Mánigbàgbé Ọdún Tó Kọjá), tó o sì ń gbé “Worldwide Report” (Ìròyìn Iṣẹ́ Ìsìn Kárí Ayé) ọdún 2004 yẹ̀ wò nínú ìwé ọdọọdún wa, 2005 Yearbook of Jehovah’s Witnesses, inú rẹ yóò dùn bó o ṣe ń rí i pé oore Jèhófà pọ̀ lórí wa. (Sm. 31:19; 65:11) A nírètí pé ìwé ọdọọdún wa yìí yóò fún ọ níṣìírí kó o lè máa ṣe ohun tí Ọlọ́run fẹ́ nìṣó.—1 Tẹs. 4:1.
A ò dẹwọ́ nínú bá a ṣe ń sapá láti mú kí ọ̀rọ̀ òtítọ́ détígbọ̀ọ́ gbogbo èèyàn. Bí àpẹẹrẹ, a ti ṣe ọ̀pọ̀ fídíò, àwo pẹlẹbẹ DVD, àtàwọn ohun ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́ mìíràn lédè àwọn adití, a sì ti tẹ àwọn ìwé jáde lédè àwọn afọ́jú pẹ̀lú láti fi ran àwọn adití àtàwọn afọ́jú lọ́wọ́ nípa tẹ̀mí. Ọ̀pọ̀ àwọn akéde Ìjọba Ọlọ́run ló ti kọ́ èdè táwọn àjèjì tó wà ní ìpínlẹ̀ ìjọ wọn ń sọ.
Síwájú sí i, ọgọ́rọ̀ọ̀rún àwọn àwùjọ ni a ti dá sílẹ̀ láwọn ibi tó wà ní àdádó tó ṣòro láti dé. Ohun tó lé ní ọgọ́rùn-ún mẹ́ta àwùjọ tó wà ní àdádó ni ẹ̀ka ọ́fíìsì kan ń bójú tó, àwọn akéde tó lé ní ẹgbẹ̀rún méje ló sì wà níbẹ̀. Ẹ ò rí i pé ìrètí wà pé a máa dá ọ̀pọ̀ ìjọ tuntun sílẹ̀ láwọn àgbègbè wọ̀nyí! Yàtọ̀ síyẹn, nínú mílíọ̀nù mẹ́rìndínlógún ó lé ọ̀kẹ́ méjìdínlógójì àti ẹgbẹ̀ta ó lé méje (16,760,607) èèyàn tó wá sí ibi ayẹyẹ Ìṣe Ìrántí lọ́dún iṣẹ́ ìsìn yìí, èyí tó lé ní mílíọ̀nù mẹ́wàá lára wọn ni kì í ṣe Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Ohun tí èyí túmọ̀ sí ni pé ọ̀pọ̀ jaburata iṣẹ́ ìkórè ló ṣì wà láti ṣe.
A dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà ní tìtorí ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ ìbùkún rẹ̀ àti bó ṣe ń fìfẹ́ bójú tó wa lójoojúmọ́. (Òwe 10:22; Mál. 3:10; 1 Pét. 5:7) Bá a ṣe ń fi ẹ̀mí ìṣọ̀kan tẹ̀ síwájú ní “apá ìgbẹ̀yìn ọjọ́” yìí, Jèhófà la gbójú lé, òun la sì fẹ̀yìn tì. Bí iná ń jó tíjì ń jà, ẹṣin ọ̀rọ̀ ọdún 2005 yìí ni kẹ́ ẹ jẹ́ ká fi sọ́kàn, ìyẹn ni: “Ọ̀dọ̀ Jèhófà ni ìrànlọ́wọ́ mi ti wá.” (Sm. 121:2) A fẹ́ kẹ́ ẹ mọ̀ pé a nífẹ̀ẹ́ yín gidigidi, a sì ń rántí yín nínú àdúrà wa.
Àwa arákùnrin yín,
Ẹgbẹ́ Olùṣàkóso ti Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà