Àwọn Ìfilọ̀
◼ Ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ tí a ó fi lọni ní oṣù February: Ìwé Sún Mọ́ Jèhófà la ó fi lọni. Bí kò bá sí, a lè lo ìwé Kíyè sí Àsọtẹ́lẹ̀ Dáníẹ́lì!, Ìṣípayá—Òtéńté Rẹ̀ Títóbi Lọ́lá Kù Sí Dẹ̀dẹ̀! àti Iwọ Le Walaaye Titilae ninu Paradise lori Ilẹ Aye. March: Ìmọ̀ Tí Ń Sinni Lọ sí Ìyè Àìnípẹ̀kun. April àti May: Kí a fi ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́ àti Jí! lọni. Nígbà tá a bá padà lọ bẹ àwọn tó fìfẹ́ hàn wò, bóyá tá a lọ sọ́dọ̀ àwọn tó wá síbi Ìṣe Ìrántí tàbí àwọn ìpàdé mìíràn tí ìjọ ṣètò àmọ́ tí wọn kò tíì di ọmọ ìjọ, kí a fún wọn ní ìwé Jọ́sìn Ọlọ́run Tòótọ́ Kan Ṣoṣo Náà. Kí a sapá láti bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì inú ilé, pàápàá bí a bá rí àwọn kan tó ti kẹ́kọ̀ọ́ ìwé Ìmọ̀ àti ìwé pẹlẹbẹ Béèrè tẹ́lẹ̀.
◼ Kí alábòójútó olùṣalága tàbí ẹnì kan tí ó yàn ṣàyẹ̀wò àkáǹtì ìjọ ní March 1, tàbí bó bá ṣe lè yá tó lẹ́yìn náà. Bí ẹ bá ní àkáǹtì mìíràn tẹ́ ẹ̀ ń tọ́jú owó àbójútó Gbọ̀ngàn Ìjọba tàbí owó kíkọ́ Gbọ̀ngàn Ìjọba tuntun sí, ẹ rí i pé ẹ ṣàyẹ̀wò èyí náà pẹ̀lú. Bí ẹ bá ti ṣàyẹ̀wò àkáǹtì tán, ẹ ṣèfilọ̀ rẹ̀ fún ìjọ nígbà tí ẹ bá fẹ́ ka ìròyìn ìnáwó.
◼ Kí akọ̀wé àti alábòójútó iṣẹ́ ìsìn ṣàyẹ̀wò ìgbòkègbodò gbogbo àwọn aṣáájú ọ̀nà déédéé. Bó bá ṣòro fún èyíkéyìí lára wọn láti ní iye wákàtí tí à ń béèrè, kí àwọn alàgbà ṣètò láti ràn án lọ́wọ́. Tẹ́ ẹ bá fẹ́ rí àwọn àbá nípa bẹ́ ẹ ṣe lè ṣèrànwọ́, ẹ wo àwọn lẹ́tà S-201-YR tí ètò àjọ Ọlọ́run máa ń kọ lọ́dọọdún.
◼ Ẹṣin ọ̀rọ̀ àkànṣe àsọyé fún gbogbo èèyàn tí a ó sọ ní àkókò Ìṣe Ìrántí ti ọdún 2005 ni “Kí Nìdí Tí Jésù Fi Jìyà Tó sì Kú?” Ìfilọ̀ tó jọ èyí wà nínú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa ti January 2005.
◼ Kí gbogbo àwọn ará rí i pé àwọn wà ní Ìpàdé fún Gbogbo Ènìyàn ní ọjọ́ Sunday, March 20 kí wọ́n lè gbọ́ ìfilọ̀ pàtàkì kan nípa ètò kan tá a máa ṣe fún àwọn akéde.
◼ Bẹ̀rẹ̀ ní ọ̀sẹ̀ May 23, 2005, a óò máa kẹ́kọ̀ọ́ ìwé pẹlẹbẹ Ẹ Máa Ṣọ́nà ní Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ìwé Ìjọ.