ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • km 4/05 ojú ìwé 7
  • Àtúnyẹ̀wò Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Àtúnyẹ̀wò Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run
  • Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2005
Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2005
km 4/05 ojú ìwé 7

Àtúnyẹ̀wò Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run

Àwọn ìbéèrè tó wà nísàlẹ̀ wọ̀nyí la óò gbé yẹ̀ wò nínú àtúnyẹ̀wò aláfẹnusọ ní Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run, ní ọ̀sẹ̀ tó bẹ̀rẹ̀ ní April 25, 2005. Alábòójútó Ilé Ẹ̀kọ́ yóò darí àtúnyẹ̀wò yìí fún ọgbọ̀n ìṣẹ́jú, èyí tá a gbé ka àwọn iṣẹ́ ilé ẹ̀kọ́ tá a ṣe ní ọ̀sẹ̀ March 7 sí April 25, 2005. [Àkíyèsí: Níbi tí a kò bá ti tọ́ka sí ibi tí a ti mú ìdáhùn jáde lẹ́yìn ìbéèrè kan, o ní láti ṣe ìwádìí fúnra rẹ láti wá ìdáhùn sí àwọn ìbéèrè náà.—Wo ìwé Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run, ojú ìwé 36 àti 37.]

ÀNÍMỌ́ Ọ̀RỌ̀ SÍSỌ

1. Nígbà tá a bá ń múra iṣẹ́ wa sílẹ̀, báwo la ṣe lè jẹ́ kí ọ̀rọ̀ wa dá lórí ibi tí wọ́n ti yanṣẹ́ fún wa, kí nìdí tí èyí sì fi ṣe pàtàkì? [be-YR ojú ìwé 234 ìpínrọ̀ 1 sí 3 àtàwọn àpótí]

2. Báwo ló ṣe yẹ kí kókó tá a máa sọ̀rọ̀ lé lórí níbi tí wọ́n ti yanṣẹ́ fún wa pọ̀ tó? [be-YR ojú ìwé 234 ìpínrọ̀ 4 sí ojú ìwé 235 ìpínrọ̀ 1]

3. Báwo la ṣe lè lo ìbéèrè láti jẹ́ kí àwọn tí à ń bá sọ̀rọ̀ lóde ẹ̀rí lóhùn sí ọ̀rọ̀ tá à ń bá wọn sọ? (Ìṣe 8:30) [be-YR ojú ìwé 236 ìpínrọ̀ 2 sí 5]

4. Báwo la ṣe lè lo ìbéèrè láti ran àwọn tá à ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lọ́wọ́ kí wọ́n lè lo “agbára ìmọnúúrò” wọn? (Róòmù 12:1) [be-YR ojú ìwé 238 ìpínrọ̀ 1]

5. Kí ni ìwúlò ìbéèrè tó wà nínú Róòmù 8:31, 32 àtèyí tó wà nínú Aísáyà 14:27? [be-YR ojú ìwé 238 ìpínrọ̀ 6 sí ojú ìwé 239 ìpínrọ̀ 1]

IṢẸ́ AKẸ́KỌ̀Ọ́ KÌÍNÍ

6. Báwo la ṣe ń fi ‘Kristi ṣe ìpìlẹ̀’ nínú iṣẹ́ sísọ àwọn èèyàn di ọmọ ẹ̀yìn tá à ń ṣe? (1 Kọ́r. 3:11) [be-YR ojú ìwé 278 ìpínrọ̀ 1 àti 2]

7. Níwọ̀n bí Jèhófà ti fún Ọmọ rẹ̀ láṣẹ láti máa ṣàkóso láti ọdún 1914, kí la ní lọ́kàn nígbà tá a bá ń gbàdúrà pé: “Kí ìjọba rẹ dé”? (Mát. 6:9, 10) [be-YR ojú ìwé 279 ìpínrọ̀ 4]

8. Kí nìdí tó fi yẹ kí gbogbo Kristẹni pátá nífẹ̀ẹ́ láti mọ̀wéé kà, ọ̀nà wo sì ni Jésù gbà fi àpẹẹrẹ èyí lélẹ̀? [w-YR 03 3/15 ojú ìwé 10 ìpínrọ̀ 5 àti ojú ìwé 12 ìpínrọ̀ 2]

9. Báwo ni àpẹẹrẹ Jòsáyà àti àpẹẹrẹ Jésù ṣe lè ran àwọn ọ̀dọ́ lọ́wọ́ láti tẹ̀ síwájú nípa tẹ̀mí? [w-YR 03 4/1 ojú ìwé 8 ìpínrọ̀ 3 àti 4 àti ojú ìwé 10 ìpínrọ̀ 3]

10. Kí nìdí tó fi yẹ ká gbẹ́kẹ̀ lé Ọlọ́run? (Òwe 3:5, 6) [w-YR 03 11/1 ojú ìwé 4 ìpínrọ̀ 6 àti 7]

BÍBÉLÌ KÍKÀ Ọ̀SỌ̀Ọ̀SẸ̀

11. Kí nìdí tí Hánà fi gbàdúrà sí Jèhófà pé kó “fi okun fún ọba rẹ̀” nígbà tó jẹ́ pé kò sí ọba kankan tó jẹ́ ẹ̀dá èèyàn ní Ísírẹ́lì? (1 Sám. 2:10)

12. Kí la lè rí kọ́ nínú báwọn ọ̀tá ṣe ṣẹ́gun Ísírẹ́lì bó tilẹ̀ jẹ́ pé àpótí májẹ̀mú wà pẹ̀lú wọn? (1 Sám. 4:3, 4, 10)

13. Kí nìdí tí 1 Kíróníkà 2:13-15 fi pe Dáfídì ní ọmọ keje tí Jésè bí àmọ́ tí 1 Sámúẹ́lì 16:10, 11 pè é ní ọmọ kẹjọ?

14. “Ẹ̀mí búburú” wo ló ń yọ Sọ́ọ̀lù lẹ́nu? (1 Sám. 16:14)

15. Abẹ́mìílò tó wà ní Ẹ́ń-dórì pe ẹnì kan jáde tó pè ní “Sámúẹ́lì.” Ǹjẹ́ àsọtẹ́lẹ̀ tí ẹni tó pè ní Sámúẹ́lì yìí sọ ṣẹ gẹ́lẹ́ bó ṣe sọ ọ́? (1 Sám. 28:16-19)

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́