Àwọn Ìfilọ̀
◼ Ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ tá ó lò ní March 21 sí April 17: A ó lo ìwé pẹlẹbẹ Ẹ Máa Ṣọ́nà! fún ìgbòkègbodò àkànṣe. April 18 sí 30, àti May: Ẹ lo ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́ àti Jí! Bẹ́ ẹ bá padà lọ sọ́dọ̀ àwọn tó fìfẹ́ hàn, tó fi mọ́ àwọn tó wá síbi Ìrántí Ikú Kristi tàbí àwọn ìpàdé ìjọ mìíràn, ṣùgbọ́n tí wọn ò tíì máa wá sáwọn ìpàdé ìjọ déédéé, ìwé Jọ́sìn Ọlọ́run Tòótọ́ Kan Ṣoṣo Náà ni kí ẹ fún wọn. Ẹ sapá ní gbogbo ọ̀nà kẹ́ ẹ lè bẹ̀rẹ̀ sí kọ́ wọn lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, pàápàá báwọn kan bá ti kẹ́kọ̀ọ́ ìwé Ìmọ̀ àti ìwé pẹlẹbẹ Béèrè tẹ́lẹ̀. June: Ìwé Kẹ́kọ̀ọ́ Lọ́dọ̀ Olùkọ́ Ńlá Náà ni kẹ́ ẹ lò. Báwọn kan bá sì sọ pé àwọn kì í ṣe òbí, ẹ lè fún wọn ní ìwé pẹlẹbẹ Béèrè. Ẹ gbìyànjú láti bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì.
◼ Ní May 28, 2005, kò ní sí àyè fún wa láti gbàlejò ní Bẹ́tẹ́lì. Ẹ jọ̀wọ́, ẹ má ṣe wá ṣèbẹ̀wò, bẹ́ẹ̀ ni kí ẹ má ṣe wá gba ìwé lọ́jọ́ náà.
◼ Ó ṣe pàtàkì pé kí ẹ̀ka ọ́fíìsì wa níbí ní àkọsílẹ̀ àdírẹ́sì àti nọ́ńbà tẹlifóònù tí gbogbo alábòójútó olùṣalága àti akọ̀wé ń lò lọ́wọ́lọ́wọ́. Bí ìyípadà bá wà nígbàkigbà, kí Ìgbìmọ̀ Iṣẹ́ Ìsìn Ìjọ kọ àdírẹ́sì àti nọ́ńbà tẹlifóònù tí wọ́n ń lò lọ́wọ́lọ́wọ́ sínú fọ́ọ̀mù Presiding Overseer/Secretary Change of Address (S-29) [Ìyípadà Àdírẹ́sì Alábòójútó Olùṣalága àti Akọ̀wé], kí wọ́n buwọ́ lù ú, kí wọ́n sì fi ránṣẹ́ sí ẹ̀ka ọ́fíìsì lọ́gán. Èyí kan ìyípadà tó bá wà nínú area code, ìyẹn nọ́ńbà tẹlifóònù àgbègbè kọ̀ọ̀kan.
◼ Kí àwọn akọ̀wé ìjọ máa rí i pé Ìwé Ìwọṣẹ́ Ìsìn Aṣáájú Ọ̀nà Déédéé (S-205-YR) àti Ìwé Ìwọṣẹ́ Ìsìn Aṣáájú Ọ̀nà Olùrànlọ́wọ́ (S-205b-YR) tí ó pọ̀ tó wà lọ́wọ́. Ẹ lè béèrè fún àwọn fọ́ọ̀mù wọ̀nyí nípa lílo fọ́ọ̀mù tá a fi ń béèrè ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́, Literature Request Form (S-14). Kí ẹ rí i pé èyí tí ìjọ ní lọ́wọ́ yóò tó lò fún ọdún kan, ó kéré tán. Ẹ máa ṣàyẹ̀wò gbogbo fọ́ọ̀mù ìwọṣẹ́ aṣáájú ọ̀nà déédéé láti rí i dájú pé ìsọfúnni inú wọn pé pérépéré.