ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • km 9/05 ojú ìwé 7
  • Àwọn Ìfilọ̀

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Àwọn Ìfilọ̀
  • Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2005
Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2005
km 9/05 ojú ìwé 7

Àwọn Ìfilọ̀

◼ Ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ tá a ó lò lóṣù September: Ìwé Sún Mọ́ Jèhófà la ó lò. Ẹ sì lè lo ìwé Àsọtẹ́lẹ̀ Dáníẹ́lì tàbí ìwé pẹlẹbẹ Ẹ Máa Ṣọ́nà bí àfirọ́pò. October: Ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́ àti Jí! ni kẹ́ ẹ lò jálẹ̀ oṣù náà. Báwọn èèyàn bá fìfẹ́ hàn, ẹ jọ̀wọ́ ẹ fún onílé ní ìwé pẹlẹbẹ Béèrè. Bẹ́ ẹ bá sì ń padà lọ, kẹ́ ẹ ní in lọ́kàn láti bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì inú ilé. November: Ẹ lo ìwé Kẹ́kọ̀ọ́ Lọ́dọ̀ Olùkọ́ Ńlá Náà. Báwọn kan bá sọ pé àwọn kì í ṣe òbí, ẹ fún wọn ní ìwé Ìmọ̀ tàbí ìwé àṣàrò kúkúrú náà Ṣé Wàá Fẹ́ Mọ Púpọ̀ Sí I Nípa Bíbélì? December: Ọkunrin Titobilọla Julọ Ti O Tii Gbé Ayé Rí. Àwọn ìwé tẹ́ ẹ lè lò bí àfirọ́pò ni Iwe Itan Bibeli Mi, tàbí Iwọ Le Walaaye Titilae ninu Paradise lori Ilẹ Aye.

◼ Ẹ̀ka ọ́fíìsì wa níbí kì í fi ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ ránṣẹ́ sí akéde kọ̀ọ̀kan. Kí alábòójútó olùṣalága ṣètò kí a máa ṣèfilọ̀ lóṣooṣù kí a tó fi fọ́ọ̀mù tí a fi ń béèrè fún ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ tí ìjọ nílò fún oṣù kọ̀ọ̀kan ránṣẹ́ sí ẹ̀ka ọ́fíìsì, kí olúkúlùkù ẹni tó bá fẹ́ gba ìwé tirẹ̀ lè sọ fún arákùnrin tó ń bójú tó ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́. Ẹ jọ̀wọ́, ẹ rántí pé àwọn ìtẹ̀jáde kan wà tá a máa ń kọ̀wé béèrè fún lákànṣe.

◼ À ń rán àwọn alàgbà létí láti ṣiṣẹ́ lórí àwọn ìtọ́ni tó wà nínú Ilé-ìṣọ́nà ti April 15, 1991, ojú ìwé 21 sí 23, tó sọ̀rọ̀ nípa àwọn tí a yọ lẹ́gbẹ́ tàbí tí wọ́n yọ ara wọn lẹ́gbẹ́, tí wọ́n lè fẹ́ kí a gba àwọn padà.

◼ A óò sọ àkànṣe àsọyé fún gbogbo èèyàn fún sáà Ìṣe Ìrántí ti ọdún 2006 ní ọjọ́ Sunday, April 30. A óò ṣèfilọ̀ àkòrí àsọyé náà nígbà tó bá yá. Kí àwọn ìjọ tí wọ́n bá ní ìbẹ̀wò alábòójútó àyíká, àpéjọ àyíká, tàbí àpéjọ àkànṣe lópin ọ̀sẹ̀ yẹn sọ àkànṣe àsọyé yìí ní ọ̀sẹ̀ tó tẹ̀ lé e. Kí ìjọ kankan má ṣe sọ àkànṣe àsọyé yìí ṣáájú Sunday, April 30, 2006.

◼ Lọ́dún iṣẹ́ ìsìn 2006, gbogbo àwọn tó bá ń ṣe aṣáájú ọ̀nà olùrànlọ́wọ́ lóṣù tí alábòójútó àyíká bá ń bẹ ìjọ wò la óò yọ̀ọ̀da fún láti bá àwọn aṣáájú ọ̀nà ṣe apá àkọ́kọ́ nínú ìpàdé tí alábòójútó àyíká máa ń bá wọn ṣe lọ́sẹ̀ ìbẹ̀wò. À ń fi àkókò yìí ké sí gbogbo àwọn tó bá lè jàǹfààní látinú ètò àkànṣe yìí láti ṣe bẹ́ẹ̀.

◼ Ike Pẹlẹbẹ Àtẹ́tísí Tuntun Tó Wà:

Àwọn Ohun Àríkọ́gbọ́n fún Wa Lónìí—Gẹ̀ẹ́sì

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́