Àwọn Ìfilọ̀
◼ Ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ tá a ó lò lóṣù October: Ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́ àti Jí! ni kẹ́ ẹ lò jálẹ̀ oṣù náà. Báwọn èèyàn bá fìfẹ́ hàn, ẹ jọ̀wọ́ ẹ fún onílé ní ìwé pẹlẹbẹ Béèrè. Bẹ́ ẹ bá sì ń padà lọ, kẹ́ ẹ ní in lọ́kàn láti bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì inú ilé. November: Ẹ lo ìwé Kẹ́kọ̀ọ́ Lọ́dọ̀ Olùkọ́ Ńlá Náà. Báwọn kan bá sọ pé àwọn kì í ṣe òbí, ẹ fún wọn ní ìwé Ìmọ̀ tàbí ìwé àṣàrò kúkúrú náà Ṣé Wàá Fẹ́ Mọ Púpọ̀ Sí I Nípa Bíbélì? December: Ọkunrin Titobilọla Julọ Ti O Tii Gbé Ayé Rí. Àwọn ìwé tẹ́ ẹ lè lò bí àfirọ́pò ni Iwe Itan Bibeli Mi, tàbí Iwọ Le Walaaye Titilae ninu Paradise lori Ilẹ Aye. January: Ìwé olójú ewé 192 èyíkéyìí tá a tẹ̀ sórí bébà pípọ́n ràkọ̀ràkọ̀ tàbí èyí tó máa ń pàwọ̀ dà, tí ìjọ bá ní lọ́wọ́, ni kẹ́ ẹ lò. Ìwé míì tẹ́ ẹ lè lò: Mankind’s Search for God, tàbí ìwé pélébé Ẹ Máa Ṣọ́nà!
◼ Níwọ̀n bí oṣù October ti ní òpin ọ̀sẹ̀ márùn-ún. Ó máa dáa gan-an láti ṣiṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà olùrànlọ́wọ́.
◼ “Ìtòlẹ́sẹẹsẹ Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run ti Ọdún 2006” wà nínú àkìbọnú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa yìí. Ẹ tọ́jú rẹ̀ kí ẹ lè rí i lò jálẹ̀ ọdún náà.