Àwọn Ìfilọ̀
◼ Ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ tá a ó lò lóṣù November: Ẹ lo ìwé Kẹ́kọ̀ọ́ Lọ́dọ̀ Olùkọ́ Ńlá Náà. Báwọn kan bá sọ pé àwọn kì í ṣe òbí, ẹ fún wọn ní ìwé Ìmọ̀ tàbí ìwé àṣàrò kúkúrú náà Ṣé Wàá Fẹ́ Mọ Púpọ̀ Sí I Nípa Bíbélì? December: Ọkunrin Titobilọla Julọ Ti O Tii Gbé Ayé Rí. Àwọn ìwé tẹ́ ẹ lè lò bí àfirọ́pò ni Iwe Itan Bibeli Mi, tàbí Iwọ Le Walaaye Titilae ninu Paradise lori Ilẹ Aye. January: Ìwé olójú ewé 192 èyíkéyìí tá a tẹ̀ sórí bébà pípọ́n ràkọ̀ràkọ̀ tàbí èyí tó máa ń pàwọ̀ dà, tí ìjọ bá ní lọ́wọ́, ni kẹ́ ẹ lò. Ìwé míì tẹ́ ẹ lè lò bí àfirọ́pò ni Mankind’s Search for God, tàbí ìwé pélébé Ẹ Máa Ṣọ́nà! February: Ìwé Sún Mọ́ Jèhófà ni kẹ́ ẹ lò. Ìwé míì tẹ́ ẹ lè lò bí àfirọ́pò ni Ìṣípayá—Òtéńté Rẹ̀ Títóbi Lọ́lá Kù Sí Dẹ̀dẹ̀! tàbí ìwé ọlọ́jọ́ pípẹ́ míì tí èyí tá a ní lọ́wọ́ pọ̀ jù.
◼ Kí alábòójútó olùṣalága tàbí ẹnì kan tí ó bá yàn ṣàyẹ̀wò àkáǹtì ìjọ ní December 1 tàbí bó bá ti lè yá tó lẹ́yìn náà. Bí ẹ bá ní àkáǹtì mìíràn tẹ́ ẹ̀ ń lò fún títọ́jú owó àbójútó Gbọ̀ngàn Ìjọba tàbí owó kíkọ́ Gbọ̀ngàn Ìjọba tuntun, kó ṣàyẹ̀wò èyí náà pẹ̀lú. Bó bá ti ṣàyẹ̀wò àkáǹtì tán, ẹ ṣèfilọ̀ rẹ̀ fún ìjọ nígbà tí ẹ bá fẹ́ ka ìròyìn ìnáwó.
◼ “Watch Tower” ni kẹ́ ẹ kọ sórí sọ̀wédowó tẹ́ ẹ bá fi tọrẹ, tẹ́ ẹ sì jù sínú àwọn àpótí ọ̀rẹ́ fún ìtìlẹ́yìn iṣẹ́ kárí ayé àti Owó Àkànlò fún Kíkọ́ Gbọ̀ngàn Ìjọba. Bákan náà, “Watch Tower” ni kẹ́ ẹ kọ sórí sọ̀wédowó tẹ́ ẹ bá fi tọrẹ ní àpéjọ àgbègbè àtèyí tẹ́ ẹ bá fi ránṣẹ́ sí ẹ̀ka ọ́fíìsì. Àdírẹ́sì tẹ́ ẹ lè lò láti fi fowó ránṣẹ́ sí ẹ̀ka ọ́fíìsì ni Watch Tower Bible and Tract Society (Ltd/Gte), P.M.B. 1090, Benin City 300001, Edo State.