Àwọn Ìfilọ̀
◼ Ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ tá a ó lò lóṣù January: Ìwé olójú ewé 192 èyíkéyìí tá a tẹ̀ sórí bébà pípọ́n ràkọ̀ràkọ̀ tàbí èyí tó máa ń pàwọ̀ dà, tí ìjọ bá ní lọ́wọ́, ni kẹ́ ẹ lò. Ìwé míì tẹ́ ẹ lè lò bí àfirọ́pò ni ìwé Ìmọ̀. February: Ìwé Sún Mọ́ Jèhófà ni kẹ́ ẹ lò. Ìwé míì tẹ́ ẹ lè lò bí àfirọ́pò ni ìwé Ìmọ̀ tàbí ìwé ọlọ́jọ́ pípẹ́ míì tí èyí tá a ní lọ́wọ́ pọ̀ jù. March: Ẹ lo ìwé Kí Ni Bíbélì Fi Kọ́ni Gan-an? Sapá láti bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. April àti May: Ẹ lo àwọn ẹ̀dà Ilé Ìṣọ́ àti Jí! Nígbà tẹ́ ẹ bá ń ṣe ìpadàbẹ̀wò sọ́dọ̀ ẹni tó fìfẹ́ hàn tó fi mọ́ àwọn tó wá sí Ìṣe Ìrántí tàbí àwọn àpéjọ mìíràn tá a ṣètò rẹ̀ ṣùgbọ́n tí wọn kì í dara pọ̀ mọ́ ìjọ déédéé, ẹ pọkàn pọ̀ sórí lílo ìwé tuntun, Kí Ni Bíbélì Fi Kọ́ni Gan-an? Ohun tẹ́ ẹ gbọ́dọ̀ fi sọ́kàn ni láti bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì.
◼ Níwọ̀n bó ti jẹ́ pé òpin ọ̀sẹ̀ márùn-ún ló máa wà nínú oṣù April, oṣù yìí á dára gan-an láti fi ṣe aṣáájú-ọ̀nà olùrànlọ́wọ́.
◼ Bẹ̀rẹ̀ láti oṣù February, tàbí ó pẹ́ tán ní March 5, àsọyé tuntun fún gbogbo ènìyàn tí àwọn alábòójútó àyíká yóò máa sọ ni “Ìgbésí Ayé Alálàáfíà Lè Jẹ́ Tìẹ Nísinsìnyí—Àti Títí Láé!”
◼ Ní báyìí, ẹ̀ẹ̀mẹrin lọ́dún ni ìwé ìròyìn Jí! yóò máa jáde lédè Ìgbò àti Yorùbá látorí ìtẹ̀jáde ti January-March 2006.
◼ Kí àwọn ìjọ ṣètò tó rọrùn láti ṣe Ìṣe Ìrántí lọ́dún yìí ní ọjọ́ Wednesday, April 12, lẹ́yìn tí oòrùn bá wọ̀. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àsọyé náà lè bẹ̀rẹ̀ ṣáájú ìgbà yẹn, gbígbé àwọn ohun ìṣàpẹẹrẹ Ìṣe Ìrántí kiri kò gbọ́dọ̀ bẹ̀rẹ̀ àyàfi lẹ́yìn tí oòrùn bá wọ̀. Ẹ wádìí ládùúgbò yín láti mọ ìgbà tí oòrùn máa ń wọ̀. Ṣe ló yẹ kí ìjọ kọ̀ọ̀kan gbìyànjú láti dá ṣe Ìṣe Ìrántí tiwọn. Àmọ́ ó lè má ṣeé ṣe bẹ́ẹ̀. Tó bá jẹ́ pé àwọn ìjọ mélòó kan ni wọ́n ń lo Gbọ̀ngàn Ìjọba kan náà, ìjọ kan tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ lè lọ gba ibòmíràn tí wọn yóò lò lálẹ́ ọjọ́ yẹn. A dábàá pé níbi tó bá ti ṣeé ṣe, kí ó tó ogójì ìṣẹ́jú ó kéré tán, lẹ́yìn tí ìjọ kan bá parí Ìṣe Ìrántí tiẹ̀ kí ìjọ tó tẹ̀ lé e tó bẹ̀rẹ̀, kí olúkúlùkù lè jàǹfààní lẹ́kùn-únrẹ́rẹ́ látinú Ìṣe Ìrántí náà. Ó yẹ ká ronú nípa bí àwọn ọkọ̀ tá a óò gbé wá kò ṣe ní ṣèdíwọ́, ká sì tún ronú nípa ibi tí a óò gbé wọn sí, títí kan jíjá èrò sílẹ̀ àti gbígbé èrò. Kí ìgbìmọ̀ àwọn alàgbà pinnu ètò tí yóò dára jù lọ fún ìjọ wọn.
◼ Nígbàkigbà tó o bá ń ṣètò fúnra rẹ láti rìnrìn àjò lọ sí orílẹ̀-èdè mìíràn, tó o sì fẹ́ lọ sí ìpàdé ìjọ, àpéjọ, tàbí àpéjọ àgbègbè níbẹ̀, ọ̀dọ̀ ẹ̀ka ọ́fíìsì tó ń bójú tó iṣẹ́ wa lórílẹ̀-èdè náà ni kó o ti béèrè nípa déètì, àkókò àti ibi tí wọ́n á ti ṣe ìpàdé ọ̀hún. Àdírẹ́sì àwọn ẹ̀ka ọ́fíìsì wà ní ojú ìwé tó kẹ́yìn nínú ìwé ọdọọdún wa, ìyẹn Yearbook, ti lọ́ọ́lọ́ọ́.