Àwọn Ìfilọ̀
◼ Ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ tá a ó lò lóṣù February: Ìwé Sún Mọ́ Jèhófà la ó lò. A lè lo ìwé Ìmọ̀ tàbí ìwé tí ọjọ́ rẹ̀ ti pẹ́ tó bá pọ̀ jù lọ́wọ́ gẹ́gẹ́ bí àfidípò. March: Ẹ lo ìwé tuntun náà Kí Ni Bíbélì Fi Kọ́ni Gan-an? Ẹ sapá gidigidi láti bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì inú ilé. April àti May: Ká lo ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́ àti Jí! Nígbà tá a bá padà lọ bẹ àwọn tó fìfẹ́ hàn wò, bóyá tá a lọ sọ́dọ̀ àwọn tó wá síbi Ìrántí Ikú Kristi tàbí àwọn ìpàdé mìíràn tí ìjọ ṣètò àmọ́ tí wọn kò dara pọ̀ ní kíkún pẹ̀lú ìjọ, kí a fún wọn ní ìwé Ki Ni Bíbélì Fi Kọ́ni Gan-an? Ohun tó gbọ́dọ̀ jẹ wá lógún ni bá a ṣe máa fi ìwé yẹn bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì inú ilé.
◼ Níwọ̀n bó ti jẹ́ pé òpin ọ̀sẹ̀ márùn-ún ló máa wà nínú oṣù April, oṣù yìí á dára gan-an láti fi ṣe aṣáájú-ọ̀nà olùrànlọ́wọ́.
◼ Ẹṣin ọ̀rọ̀ àkànṣe àsọyé fún gbogbo èèyàn ní àkókò Ìrántí Ikú Kristi ti ọdún 2006 ni, “Ṣé Ọwọ́ Ọlọ́run Làṣẹ Ṣì Wà.” Ẹ wo ìfilọ̀ tó jọ èyí nínú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa ti September 2005.
◼ Àpilẹ̀kọ tó wà lójú ìwé 6, “Bá A Ṣe Lè Kẹ́kọ̀ọ́ Ìwé Kí Ni Bíbélì Fi Kọ́ni Gan-an? Ka sí Gbádùn Rẹ̀” la óò jíròrò ní Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn tá a ó ṣe lọ́sẹ̀ April 3. Ẹ jọ̀wọ́, ẹ tọ́jú àpilẹ̀kọ náà àti ìtòlẹ́sẹẹsẹ ìkẹ́kọ̀ọ́ tó bá a wá.
◼ Kí akọ̀wé àti alábòójútó iṣẹ́ ìsìn ṣàyẹ̀wò ìgbòkègbodò gbogbo àwọn aṣáájú ọ̀nà déédéé. Bó bá ṣòro fún èyíkéyìí lára wọn láti ní iye wákàtí tó yẹ kí wọ́n ròyìn, kí àwọn alàgbà ṣètò láti ràn án lọ́wọ́. Àwọn àmọ̀ràn tẹ́ ẹ lè fún irú ẹni bẹ́ẹ̀ wà nínú lẹ́tà S-201-YR.
◼ A kò gba ẹnikẹ́ni tàbí àwùjọ èyíkéyìí láàyè láti ṣèbẹ̀wò sí ibi tá a ṣẹ̀ṣẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí í kọ́ Ọ́fíìsì wa tuntun sí nílùú Èkó. Ìdí ni pé ilé iṣẹ́ tó ń gba ilé kọ́ la gbé iṣẹ́ náà fún. Bí ẹnikẹ́ni bá sì lọ síbẹ̀, ó lè dí iṣẹ́ tí wọ́n ń ṣe níbẹ̀ lọ́wọ́.
◼ Ní àwọn àpéjọ àyíká àti àpéjọ àkànṣe tí yóò wáyé lọ́dún 2006, a óò ya ibì kan sọ́tọ̀ fún àwọn adití ní àwọn àyíká tá a tò sísàlẹ̀ yìí. Ibi tá a bá sì yà sọ́tọ̀ fún wọn yìí la ó ti túmọ̀ gbogbo ìtòlẹ́sẹẹsẹ náà sí Èdè Àwọn Adití ní Ìlànà Ti Amẹ́ríkà. A ó tẹ ìsọfúnni nípa àwọn àpéjọ míì tá a ó ti ya ibì kan sọ́tọ̀ fáwọn adití sínú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa ti March 2006:
Badagry (WE-02) January 21 sí 22 àti April 23
Badagry (WE-14) January 14 sí 15 àti April 22
Ibadan (WE-09) February 11 àti June 17 sí 18
Ota (WE-05) January 14 sí 15 àti April 8
Ota (WE-25) January 21 sí 22 àti April 9
Ubogo (ME-07) February 4 sí 5 àti May 21