ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • km 3/06 ojú ìwé 2-7
  • Àwọn Ìfilọ̀

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Àwọn Ìfilọ̀
  • Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2006
Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2006
km 3/06 ojú ìwé 2-7

Àwọn Ìfilọ̀

◼ Ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ tá a ó lò lóṣù March: Ẹ lo ìwé tuntun náà Kí Ni Bíbélì Fi Kọ́ni Gan-an? Ẹ sapá gidigidi láti bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì inú ilé. April àti May: Ká lo ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́ àti Jí! Nígbà tá a bá padà lọ bẹ àwọn tó fìfẹ́ hàn wò, bóyá tá a lọ sọ́dọ̀ àwọn tó wá síbi Ìrántí Ikú Kristi tàbí àwọn ìpàdé mìíràn tí ìjọ ṣètò àmọ́ tí wọn kò dara pọ̀ ní kíkún pẹ̀lú ìjọ, kí a fún wọn ní ìwé Ki Ni Bíbélì Fi Kọ́ni Gan-an? Ohun tó gbọ́dọ̀ jẹ wá lógún ni bá a ṣe máa fi ìwé yẹn bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì inú ilé. June: Ẹ lo ìwé Kẹ́kọ̀ọ́ Lọ́dọ̀ Olùkọ́ Ńlá Náà. Báwọn kan bá sì sọ pé àwọn kì í ṣe òbí, ẹ fún wọn ní ìwé Àṣírí Ayọ̀ Ìdílé.

◼ Níwọ̀n bó ti jẹ́ pé òpin ọ̀sẹ̀ márùn-ún ló máa wà nínú oṣù April, oṣù yìí á dára gan-an láti fi ṣe aṣáájú-ọ̀nà olùrànlọ́wọ́.

◼ Ọjọ́ Wednesday, April 12, 2006 la ó ṣe Ìrántí Ikú Kristi. Bó bá jẹ́ pé ọjọ́ Wednesday lẹ máa ń ṣe ìpàdé yín, ṣe ni kẹ́ ẹ wá ọjọ́ mìíràn nínú ọ̀sẹ̀ náà bí àyè bá máa wà ní Gbọ̀ngàn Ìjọba. Bí kò bá ṣeé ṣe, táwọn ohun kan sì wà nínú Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn tó kan ìjọ yín gbọ̀ngbọ̀n, ẹ lè fi apá yẹn kún ìtòlẹ́sẹẹsẹ Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn míì.

◼ A óò jíròrò fídíò náà, Noah—He Walked With God nínú ọ̀kan lára àwọn ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn wa lóṣù May. Nítorí náà, bẹ́ ẹ bá ń fẹ́ ẹ̀dà fídíò náà, ẹ tètè béèrè fún un nípasẹ̀ ìjọ yín.

◼ Nígbàkigbà tó o bá ń ṣètò fúnra rẹ láti rìnrìn àjò lọ sí orílẹ̀-èdè mìíràn, tó o sì fẹ́ lọ sí ìpàdé ìjọ, àpéjọ àyíká, tàbí àpéjọ àgbègbè níbẹ̀, ọ̀dọ̀ ẹ̀ka ọ́fíìsì tó ń bójú tó iṣẹ́ wa lórílẹ̀-èdè náà ni kó o ti béèrè déètì, àkókò àti ibi tí wọ́n á ti ṣe ìpàdé ọ̀hún. Àdírẹ́sì àwọn ẹ̀ka ọ́fíìsì wà ní ojú ìwé tó kẹ́yìn nínú ìwé ọdọọdún wa, ìyẹn Yearbook ti lọ́ọ́lọ́ọ́.

◼ Àkànṣe àsọyé fún gbogbo ènìyàn ti àkókò Ìrántí Ikú Kristi tọdún 2006, yóò wáyé ní Sunday, April 30. Àkòrí àsọyé náà yóò jẹ́, “Ṣé Ọwọ́ Ọlọ́run Làṣẹ Ṣì Wà?”

◼ Ní àwọn àpéjọ àyíká àti àpéjọ àkànṣe tí yóò wáyé lọ́dún 2006, a ó ya ibì kan sọ́tọ̀ fún àwọn adití ní àwọn àyíká tá a tò sísàlẹ̀ yìí. Ibi tá a bá sì yà sọ́tọ̀ fún wọn yìí la ó ti túmọ̀ gbogbo ìtòlẹ́sẹẹsẹ náà sí Èdè Àwọn Adití ní Ìlànà Ti Amẹ́ríkà:

Akábọ (EE-08) April 15 sí 16 àti July 16

Àkúrẹ́ (WE-12) March 4 àti August 5 sí 6

Bàdágìrì (WE-04) April 1 sí 2 àti August 5

Bàdágìrì (WE-23) May 20 sí 21 àti August 6

Kàlàba (EE-21) May 27 sí 28 àti September 10

Dálùwọ́n (WE-01) March 19 àti July 15 sí 16

Dálùwọ́n (WE-03) March 18 àti August 5 sí 6

Dálùwọ́n (WE-13) April 9 àti September 2 sí 3

Dálùwọ́n (WE-22) May 20 àti September 9 sí 10

Ẹnúgu (EE-17) May 6 àti September 2 sí 3

Ẹnúgu (EE-19) May 7 àti September 9 sí 10

Ìbàdàn (WE-10) May 27 sí 28 àti August 20

Igurúta Àlì (EE-22) May 13 àti August 12 sí 13

Iléṣà (WE-15) March 18 sí 19 ní Àkúrẹ́; June 25 ní Iléṣà

Kàdúná (NE-01b) May 20 sí 21 àti August 26

Ọ̀tà (WE-06) April 15 sí 16 àti July 15

Ọ̀tà (WE-07) March 18 sí 19 àti June 25

Ùlì (EE-24) March 5 àti June 17 sí 18

Uyó (EE-20) May 6 àti September 23 sí 24

◼ Àwọn Ìtẹ̀jáde Tuntun Tó Wà Lọ́wọ́ Báyìí:

Ilé Ìṣọ́ (ìdìpọ̀ ti ọdún 2004)—Gẹ̀ẹ́sì

Jí! (ìdìpọ̀ ti ọdún 2004)—Gẹ̀ẹ́sì

Kíyè sí Àsọtẹ́lẹ̀ Dáníẹ́lì!—Ìtẹ̀jáde Onílẹ́tà Gàdàgbà —Gẹ̀ẹ́sì

Sún Mọ́ Jèhófà—Tífí

◼ Àwọn Kásẹ́ẹ̀tì Àtẹ́tísí Tuntun Tó Wà Lọ́wọ́ Báyìí:

Sún Mọ́ Jèhófà (kásẹ́ẹ̀tì mẹ́jọ ló wà nínú ẹ̀)—Gẹ̀ẹ́sì

◼ Àwo CD Tó Wà Lọ́wọ́ Báyìí:

Watchtower Library—2004 Edition—Gẹ̀ẹ́sì

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́